Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìdárò 4:1-22

א [Áléfì] 4  Wo bí wúrà tí ń dán ti di bàìbàì, wúrà dídára!+Wo bí a ti tú àwọn òkúta mímọ́+ dà sí ìkòríta gbogbo ojú pópó!+ ב [Bétì]   Ní ti àwọn ọmọ ọ̀wọ́n ti Síónì,+ àwọn tí a ń díwọ̀n ní ìfiwéra pẹ̀lú wúrà tí a yọ́ mọ́,Wo bí a ti kà wọ́n sí ìṣà amọ̀ títóbi, iṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!+ ג [Gímélì]   Àní àwọn akátá pàápàá ti gbé ọmú sílẹ̀. Wọ́n ti fún ọmọ lọ́mú.Ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi di ìkà,+ bí ògòǹgò ní aginjù.+ ד [Dálétì]   Ahọ́n ọmọ ẹnu ọmú ti lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu rẹ̀ nítorí òùngbẹ.+Àwọn ọmọ pàápàá ti béèrè fún oúnjẹ.+ Kò sí ẹni tí ń fi í fún wọn.+ ה [Híì]   Àní àwọn tí ń jẹ àdídùn ni ìyàlẹ́nu ti bá ní àwọn ojú pópó.+Àwọn tí a tọ́ dàgbà nínú aṣọ rírẹ̀dòdò+ ni ó ti di dandan fún láti gbá òkìtì eérú mọ́ra.+ ו [Wọ́ọ̀]   Ìyà ìṣìnà ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi wá pọ̀ ju ìyà ẹ̀ṣẹ̀ Sódómù lọ,+Èyí tí a bì ṣubú bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan, èyí tí ọwọ́ kankan kò sì wá ràn lọ́wọ́.+ ז [Sáyínì]   Àwọn Násírì+ rẹ̀ mọ́ gaara ju ìrì dídì lọ;+ wọ́n funfun ju wàrà lọ.Ní ti tòótọ́, wọ́n pọ́n+ ju iyùn lọ; dídán wọ́n jẹ́ bí ti sàfáyà.+ ח [Kétì]   Ìrí ojú wọn ti ṣú ju ìdúdú pàápàá. A kò dá wọn mọ̀ ní àwọn ojú pópó.+Awọ ara wọn ti kíweje lára egungun wọn.+ Ó ti gbẹ bí igi. ט [Tétì]   Ó sàn fún àwọn tí a fi idà+ pa jù fún àwọn tí a fi ìyàn pa,+Nítorí pé àwọn wọ̀nyí ń joro dànù, a gún wọn ní àgúnyọ nítorí àìsí àmújáde nínú pápá gbalasa. י [Yódì] 10  Àní ọwọ́ àwọn obìnrin oníyọ̀ọ́nú ti se àwọn ọmọ wọn.+Wọ́n ti dà bí oúnjẹ ìtùnú fúnni lákòókò ìwópalẹ̀ ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi.+ כ [Káfì] 11  Jèhófà ti ṣàṣeparí ìhónú rẹ̀.+ Ó ti da ìbínú rẹ̀ jíjófòfò jáde.+Ó sì mú kí iná jó ní Síónì, èyí tí ó jẹ ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.+ ל [Lámédì] 12  Àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti gbogbo olùgbé ilẹ̀ eléso kò gbà gbọ́+Pé elénìní àti ọ̀tá yóò wá sí àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.+ מ [Mémì] 13  Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀, ìṣìnà àwọn àlùfáà rẹ̀,+Nínú rẹ̀ ni àwọn tí ń ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo sílẹ̀ wà.+ נ [Núnì] 14  Wọ́n ti rìn gbéregbère bí afọ́jú+ ní àwọn ojú pópó.+ Ẹ̀jẹ̀ ti sọ wọ́n di eléèérí,+Tí kò fi sí ẹnì kankan tí ó lè fi ọwọ́ kan ẹ̀wù wọn.+ ס [Sámékì] 15  “Kúrò lọ́nà! Aláìmọ́!”+ ni wọ́n ké jáde sí wọn. “Kúrò lọ́nà! Kúrò lọ́nà! Má fọwọ́ kàn án!”+Nítorí wọ́n ti di aláìnílé.+ Wọ́n ti rìn gbéregbère pẹ̀lú.+ Àwọn ènìyàn ti sọ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé: “Wọn kì yóò tún ṣe àtìpó mọ́.+ פ [Péè] 16  Ojú Jèhófà ti pín wọn yẹ́lẹyẹ̀lẹ.+ Kì yóò tún bojú wò wọ́n mọ́.+Dájúdájú, àwọn ènìyàn kì yóò fi ìgbatẹnirò hàn àní fún àwọn àlùfáà.+ Dájúdájú, wọn kì yóò fi ojú rere hàn àní fún àwọn arúgbó.”+ ע [Áyínì] 17  Nígbà tí a ṣì wà, ojú wa ń joro lẹ́nu wíwọ̀nà lásán fún ìrànwọ́ wa.+Lákòókò tí a ń wò yí ká, a ti yíjú sí orílẹ̀-èdè kan tí kò lè mú ìgbàlà wá.+ צ [Sádì] 18  Wọ́n ti ṣọdẹ àwọn ìṣísẹ̀+ wa tí kò fi sí rírìn ní àwọn ojúde ìlú wa.Òpin wa ti sún mọ́lé. Ọjọ́ wa ti pé, nítorí òpin wa ti dé.+ ק [Kófì] 19  Àwọn olùlépa wa yára ju idì ojú ọ̀run lọ.+Wọ́n ti lépa+ wa kíkankíkan lórí àwọn òkè ńlá. Wọ́n ti lúgọ dè wá nínú aginjù.+ ר [Réṣì] 20  Èémí ihò imú wa gan-an,+ ẹni àmì òróró Jèhófà,+ ni a ti mú nínú kòtò ńlá wọn,+Ẹni tí a sọ nípa rẹ̀ pé: “Abẹ́ ibòji+ rẹ̀ ni àwa yóò máa gbé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.”+ ש [Sínì] 21  Máa yọ ayọ̀ ńláǹlà kí o sì máa yọ̀,+ ìwọ ọmọbìnrin Édómù,+ ìwọ tí ń gbé ní ilẹ̀ Úsì.+Ife náà yóò kọjá sọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú.+ Ìwọ yóò mu àmupara, ìwọ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní ìhòòhò.+ ת [Tọ́ọ̀] 22  Ìṣìnà rẹ, ìwọ ọmọbìnrin Síónì, ti wá sí òpin rẹ̀.+ Òun kì yóò tún mú ọ lọ sí ìgbèkùn mọ́.+Ó ti yí àfiyèsí rẹ̀ sí ìṣìnà rẹ, ìwọ ọmọbìnrin Édómù. Ó ti tú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ síta.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé