Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìdárò 3:1-66

א [Áléfì] 3  Èmi ni abarapá ọkùnrin tí ó ti rí ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́+ nítorí ọ̀gọ ìbínú kíkan rẹ̀.   Èmi ni ó ti ṣamọ̀nà tí ó sì mú kí ó rìn nínú òkùnkùn kì í sì í ṣe nínú ìmọ́lẹ̀.+   Ní tòótọ́, èmi ni ó yí ọwọ́ rẹ̀ padà sí léraléra láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+ ב [Bétì]   Ó ti mú kí ẹran ara mi àti awọ ara mi ṣá.+ Ó ti fọ́ egungun mi.+   Ó ti mọdi tì mí, kí ó lè fi ọ̀gbìn onímájèlé+ àti ìnira ká mi mọ́.+   Ibi tí ó ṣókùnkùn+ ni ó mú kí n jókòó sí bí àwọn ènìyàn tí ó ti kú tipẹ́tipẹ́.+ ג [Gímélì]   Ó ti dí mi pa bí ẹni pé pẹ̀lú ògiri òkúta, kí èmi má bàa jáde lọ.+ Ó ti mú kí ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀+ bàbà mi wúwo.   Pẹ̀lúpẹ̀lù, nígbà tí mo bá pè fún ìrànwọ́ tí mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ní ti tòótọ́, ó ń dínà àdúrà mi.+   Ó ti fi òkúta gbígbẹ́ dí àwọn ọ̀nà mi pa.+ Ó ti lọ́ àwọn òpópónà mi.+ ד [Dálétì] 10  Bí béárì tí ó lúgọ ni ó jẹ́ sí mi,+ bí kìnnìún ní ibi ìlùmọ́.+ 11  Àwọn ọ̀nà mi ni ó ti dà rú, ó sì sọ mí di aláìríkan-ṣèkan. Ó ti sọ mí di ahoro.+ 12  Ó ti fa ọrun rẹ̀,+ ó sì gbé mi kalẹ̀ bí àfojúsùn fún ọfà.+ ה [Híì] 13  Ó ti mú àwọn ọmọ apó rẹ̀ wá sínú àwọn kíndìnrín mi.+ 14  Mo ti di ohun ìfirẹ́rìn-ín+ fún gbogbo ènìyàn tí ó lòdì sí mi, ẹṣin ọ̀rọ̀ orin wọn láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+ 15  Ó ti fún mi ní ohun kíkorò tí ó pọ̀ tó.+ Ó ti fi iwọ rin mí gbingbin.+ ו [Wọ́ọ̀] 16  Ó sì fi taàrá ká eyín mi.+ Ó ti mú mi ṣojo nínú eérú.+ 17  Ìwọ pẹ̀lú ṣe ìtanù tí kò fi sí àlàáfíà fún ọkàn mi. Ohun rere ti rá kúrò nínú iyè mi.+ 18  Mo sì ń wí pé: “Ìtayọlọ́lá mi ti ṣègbé, àti ìfojúsọ́nà mi láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.”+ ז [Sáyínì] 19  Rántí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́ àti inú ipò àìnílé tí mo wà,+ iwọ àti ọ̀gbìn onímájèlé.+ 20  Láìkùnà, ọkàn rẹ yóò rántí, yóò sì tẹ̀ ba mọ́lẹ̀ lórí mi.+ 21  Èyí ni ohun tí èmi yóò mú padà wá sí ọkàn-àyà mi.+ Ìdí nìyẹn tí èmi yóò ṣe fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn.+ ח [Kétì] 22  Àwọn ìṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ ti Jèhófà ni kò jẹ́ kí a wá sí òpin wa,+ nítorí ó dájú pé àánú rẹ̀ kì yóò wá sí òpin.+ 23  Tuntun ni wọ́n ní òròòwúrọ̀.+ Ìṣòtítọ́ rẹ pọ̀ yanturu.+ 24  “Jèhófà ni ìpín mi,”+ ni ọkàn mi wí, “ìdí nìyẹn tí èmi yóò ṣe fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí i.”+ ט [Tétì] 25  Jèhófà jẹ́ ẹni rere sí ẹni tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀,+ sí ọkàn tí ń wá a.+ 26  Ó dára kí ènìyàn dúró,+ àní ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́,+ de ìgbàlà Jèhófà.+ 27  Ó dára kí abarapá ọkùnrin ru àjàgà ní ìgbà èwe rẹ̀.+ י [Yódì] 28  Kí ó jókòó ní òun nìkan kí ó sì dákẹ́ jẹ́ẹ́,+ nítorí ó ti gbé ohun kan kà á lórí.+ 29  Kí ó fi ẹnu rẹ̀ sínú ekuru.+ Bóyá ìrètí wà.+ 30  Kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ fún ẹni náà tí ń lù ú.+ Kí ó ní ànító ẹ̀gàn rẹ̀.+ כ [Káfì] 31  Nítorí Jèhófà kì yóò máa bá a nìṣó ní títaninù fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 32  Nítorí bí ó tilẹ̀ ti ṣokùnfà ẹ̀dùn-ọkàn,+ dájúdájú, òun yóò tún fi àánú hàn ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pọ̀ yanturu inú-rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́.+ 33  Nítorí kì í ṣe láti inú ọkàn-àyà òun fúnra rẹ̀ ni ó ti ṣẹ́ni níṣẹ̀ẹ́ tàbí ni ó ti kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ọmọ ènìyàn.+ ל [Lámédì] 34  Láti tẹ gbogbo ẹlẹ́wọ̀n ilẹ̀ ayé+ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ ẹni,+ 35  Láti yí ìdájọ́ abarapá ọkùnrin po níwájú Ẹni Gíga Jù Lọ,+ 36  Láti sọ ènìyàn di oníwà wíwọ́ nínú ẹjọ́ rẹ̀, ni Jèhófà tìkára rẹ̀ kò fi ojú rere wò.+ מ [Mémì] 37  Ta wá ni ó ti sọ pé kí ohun kan ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ kò pa á láṣẹ?+ 38  Ohun búburú àti ohun rere kì í ti ẹnu Ẹni Gíga Jù Lọ jáde.+ 39  Báwo ni alààyè ènìyàn ṣe lè fi ìráhùn kẹ́ra bàjẹ́,+ abarapá ọkùnrin ní tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?+ נ [Núnì] 40  Jẹ́ kí a wá ọ̀nà wa kàn,+ kí a sì yẹ̀ ẹ́ wò, kí a sì padà tààrà sọ́dọ̀ Jèhófà.+ 41  Jẹ́ kí a gbé ọkàn-àyà wa pẹ̀lú àtẹ́lẹwọ́ wa sókè sí Ọlọ́run ní ọ̀run:+ 42  “Àwa fúnra wa ti ré ìlànà kọjá, a sì ti ṣọ̀tẹ̀.+ Ìwọ fúnra rẹ kò sì tíì dárí jì.+ ס [Sámékì] 43  O ti fi ìbínú dí ọ̀nà àbáwọlé,+ o sì ń lépa wa ṣáá.+ O ti pa; ìwọ kò sì fi ìyọ́nú hàn.+ 44  O ti fi ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà dí ọ̀nà àbáwọlé sọ́dọ̀ ara rẹ,+ kí àdúrà má lè là á kọjá.+ 45  Ó sọ wá di ohun ìtanù lásán àti pàǹtírí ní àárín àwọn ènìyàn.”+ פ [Péè] 46  Gbogbo ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn sí wa.+ 47  Ìbẹ̀rùbojo àti ibi jíjinkòtò pàápàá ti di tiwa,+ ìdahoro àti ìwópalẹ̀.+ 48  Ìṣàn omi ni ojú mi ń ṣàn wálẹ̀ ní tìtorí ìwópalẹ̀ ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi.+ ע [Áyínì] 49  Ojú mi gan-an ti yọ́, kì yóò sì dákẹ́, tí kò fi ṣíwọ́ fún ìgbà díẹ̀,+ 50  Títí Jèhófà yóò fi bojú wolẹ̀ kí ó sì rí i láti ọ̀run.+ 51  Ojú tèmi ti bá ọkàn mi lò lọ́nà mímúná,+ nítorí gbogbo ọmọbìnrin ìlú ńlá mi.+ צ [Sádì] 52  Ní ti gidi, àwọn ọ̀tá mi ti ṣọdẹ mi bí ìgbà tí a ń ṣọdẹ ẹyẹ,+ láìnídìí.+ 53  Wọ́n ti mú kí ìwàláàyè mi dákẹ́, àní nínú kòtò,+ wọ́n sì ń sọ òkúta lù mí ṣáá. 54  Omi ti ṣàn bò mí lórí.+ Mo ti wí pé: “Dájúdájú, a óò ké mi kúrò!”+ ק [Kófì] 55  Mo ti ké pe orúkọ rẹ, Jèhófà, láti inú kòtò irú èyí tí ó jìn jù lọ.+ 56  Gbọ́ ohùn mi.+ Má fi etí rẹ pa mọ́ fún ìtura mi, fún igbe mi fún ìrànlọ́wọ́.+ 57  O ti sún mọ́ tòsí ní ọjọ́ tí mo ń pè ọ́ ṣáá.+ Ìwọ wí pé: “Má fòyà.”+ ר [Réṣì] 58  O ti gba ìjà ọkàn mi jà, Jèhófà.+ O ti tún ìwàláàyè mi rà.+ 59  O ti rí àìtọ́ tí a ṣe sí mi, Jèhófà.+ Bá mi ṣe ìdájọ́ ọ̀ràn mi.+ 60  O ti rí gbogbo ẹ̀san wọn, gbogbo ìrònú wọn lòdì sí mi.+ ש [Sínì] tàbí [Ṣínì] 61  O ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn, Jèhófà, gbogbo ìrònú wọn lòdì sí mi,+ 62  Ètè àwọn tí ń dìde sí mi àti ìsọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ wọn lòdì sí mi+ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+ 63  Bojú wo jíjókòó wọn àti dídìde wọn.+ Èmi ni ẹṣin ọ̀rọ̀ orin wọn.+ ת [Tọ́ọ̀] 64  Ìwọ yóò fi ìbálò kan bá wọn lò padà, Jèhófà, ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ ọwọ́ wọn.+ 65  Ìwọ yóò fún wọn ní àfojúdi ọkàn-àyà,+ ègún rẹ fún wọn.+ 66  Ìwọ yóò lépa nínú ìbínú, ìwọ yóò sì pa wọ́n rẹ́ ráúráú+ kúrò lábẹ́ ọ̀run ti Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé