Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìdárò 2:1-22

א [Áléfì] 2  Wo bí Jèhófà, nínú ìbínú rẹ̀, ti da òwúsúwusù bo ọmọbìnrin Síónì!+Ó ti ju ẹwà Ísírẹ́lì+ láti ọ̀run sí ilẹ̀ ayé.+Kò sì rántí àpótí ìtìsẹ̀+ rẹ̀ ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀. ב [Bétì]   Jèhófà ti gbé mì, kò fi ìyọ́nú kankan hàn sí ibi gbígbé+ èyíkéyìí ti Jékọ́bù.Nínú ìbínú kíkan rẹ̀, ó ti ya àwọn ibi olódi+ ọmọbìnrin Júdà lulẹ̀.Ó ti bá a kanlẹ̀,+ ó ti sọ ìjọba+ náà àti àwọn ọmọ aládé+ rẹ̀ di aláìmọ́. ג [Gímélì]   Nínú ìgbóná ìbínú, ó ti ké gbogbo ìwo Ísírẹ́lì lulẹ̀.+Ó ti yí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ padà níwájú ọ̀tá;+Àti ní Jékọ́bù, ó ń jó bí iná tí ń jó fòfò, èyí tí ó ti jẹ gbogbo àyíká run.+ ד [Dálétì]   Ó ti fa ọrun rẹ̀ bí ọ̀tá.+ Ọwọ́+ ọ̀tún rẹ̀ ti dúró ní ipò rẹ̀Bí elénìní,+ ó sì ń pa gbogbo àwọn tí ó jẹ ojú ní gbèsè.+Inú àgọ́+ ọmọbìnrin Síónì ni ó da ìhónú rẹ̀ jáde sí, gan-an gẹ́gẹ́ bí iná.+ ה [Híì]   Jèhófà dà bí ọ̀tá.+ Ó ti gbé Ísírẹ́lì mì.+Ó ti gbé gbogbo ilé gogoro ibùgbé rẹ̀ mì;+ ó ti run àwọn ibi olódi rẹ̀.+Ó sì mú kí ìṣọ̀fọ̀ àti ìdárò pọ̀ gidigidi nínú ọmọbìnrin Júdà.+ ו [Wọ́ọ̀]   Ó sì ṣe àtíbàbà+ rẹ̀ ṣúkaṣùka bí èyí tí ó wà nínú ọgbà.+ Ó ti run àjọyọ̀ rẹ̀.Jèhófà ti mú kí a gbàgbé àjọyọ̀+ àti sábáàtì ní Síónì,Kò sì fi ọ̀wọ̀ kankan hàn fún ọba àti àlùfáà nínú ìdálẹ́bi rẹ̀.+ ז [Sáyínì]   Jèhófà ti ta pẹpẹ rẹ̀ nù.+ Ó ti kọ ibùjọsìn rẹ̀ sílẹ̀ tẹ̀gàntẹ̀gàn.+Ó ti fi ògiri àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀ lé ọ̀tá lọ́wọ́.+Ilé Jèhófà ni wọ́n ti ké jáde, gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ àjọyọ̀.+ ח [Kétì]   Jèhófà ti ronú láti run ògiri+ ọmọbìnrin Síónì.Ó ti na okùn ìdiwọ̀n.+ Kò yí ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú gbígbé mì.+Ó sì mú kí ohun àfiṣe-odi àti ògiri máa ṣọ̀fọ̀.+ Okun wọn ti tán pa pọ̀. ט [Tétì]   Àwọn ẹnubodè+ rẹ̀ ti rì wọlẹ̀. Ó ti pa run, ó sì ti ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú rẹ̀ sí wẹ́wẹ́.Ọba rẹ̀ àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀ wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ Kò sí òfin.+Àwọn wòlíì rẹ̀ pẹ̀lú kò rí ìran láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.+ י [Yódì] 10  Àwọn àgbààgbà ọmọbìnrin Síónì jókòó sórí ilẹ̀, níbi tí wọ́n ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.+Wọ́n ti bu ekuru sórí.+ Wọ́n ti sán aṣọ àpò ìdọ̀họ.+Àwọn wúńdíá Jerúsálẹ́mù ti tẹ orí wọn kan ilẹ̀yílẹ̀.+ כ [Káfì] 11  Ojú mi ti wá sí òpin rẹ̀ nínú kìkìdá omijé.+ Ìfun mi ń hó.+A ti tú ẹ̀dọ̀ mi jáde sí ilẹ̀yílẹ̀,+ ní tìtorí ìfọ́yángá ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi,+Nítorí dídi tí ọmọ àti ọmọ ẹnu ọmú di aláìlókun ní àwọn ojúde ìlú.+ ל [Lámédì] 12  Wọ́n ń wí ṣáá fún àwọn ìyá wọn pé: “Ọkà àti wáìnì dà?”+Nítorí dídi tí wọ́n ń di aláìlókun bí ẹni tí a pa ní àwọn ojúde ìlú ńlá,Nítorí títú tí a ń tú ọkàn wọn jáde sí oókan àyà àwọn ìyá wọn. מ [Mémì] 13  Ẹlẹ́rìí kí ni èmi yóò fi ọ́ ṣe? Kí ni èmi yóò fi ọ́ wé, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù?+Kí ni èmi yóò mú bá ọ dọ́gba, kí èmi lè tù ọ́ nínú, ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Síónì?+Nítorí ìwópalẹ̀+ rẹ pọ̀ gan-an bí òkun. Ta ní lè mú ọ lára dá?+ נ [Núnì] 14  Àwọn wòlíì tìrẹ ti rí ìran ohun tí kò ní láárí àti àwọn ohun tí kò tẹ́ni lọ́rùn sí ọ,+Wọn kò sì tú ìṣìnà rẹ síta láti lè yí oko òǹdè rẹ padà,+Ṣùgbọ́n wọ́n ń rí ìran àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde tí kò ní láárí tí ó sì ń ṣini lọ́nà sí ọ.+ ס [Sámékì] 15  Gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ ní ojú ọ̀nà ti pàtẹ́wọ́ sí ọ.+Wọ́n ti súfèé,+ wọ́n sì ń mi orí+ wọn sí ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, pé:“Ṣe ìlú ńlá náà nìyí tí wọ́n máa ń sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Òun ni ìjẹ́pípé ẹwà ìfanimọ́ra, ayọ̀ ńláǹlà fún gbogbo ilẹ̀ ayé’?”+ פ [Péè] 16  Gbogbo ọ̀tá rẹ ti la ẹnu sí ọ.+Wọ́n ti súfèé, wọ́n sì ń wa eyín wọn pọ̀.+ Wọ́n ti wí pé: “Ṣe ni a óò gbé e mì.+Ní tòótọ́, èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí.+ Ọwọ́ ti tẹ̀ ẹ́! A ti rí i!”+ ע [Áyínì] 17  Jèhófà ti ṣe ohun tí ó ní lọ́kàn.+ Ó ti ṣàṣeparí àsọjáde rẹ̀,+Ohun tí ó ti pa láṣẹ láti àwọn ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.+ Ó ti ya á lulẹ̀ kò sì fi ìyọ́nú hàn.+Ó sì mú kí ọ̀tá yọ̀ ọ́.+ Ó ti mú kí ìwo àwọn elénìní rẹ ga.+ צ [Sádì] 18  Ọkàn-àyà wọn ti ké jáde sí Jèhófà,+ ìwọ ògiri ọmọbìnrin Síónì.+Mú kí omijé máa ṣàn wálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gbàrá ní ọ̀sán àti ní òru.+Má ṣe mú kí ara rẹ kú tipiri. Kí ọmọlójú rẹ má sì dákẹ́. ק [Kófì] 19  Dìde! Ké tẹ̀dùntẹ̀dùn ní òru ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ìṣọ́ òwúrọ̀.+Tú ọkàn-àyà+ rẹ jáde níwájú+ Jèhófà bí omi.Gbé àtẹ́lẹwọ́+ rẹ sókè sí i ní tìtorí ọkàn àwọn ọmọ rẹ,Àwọn tí okun wọ́n ń tán lọ nítorí ìyàn ní ìkòríta gbogbo ojú pópó.+ ר [Réṣì] 20  Rí i, Jèhófà, sì wo+ ẹni tí o bá lò lọ́nà mímúná ní ọ̀nà yìí.Ó ha yẹ kí àwọn obìnrin máa jẹ èso tiwọn fúnra wọn, àwọn ọmọ tí a bí pẹ̀lú ara pípé,+Tàbí ó ha yẹ kí a pa àlùfáà àti wòlíì nínú ibùjọsìn Jèhófà?+ ש [Ṣínì] 21  Ọmọdékùnrin àti àgbà ọkùnrin+ ti dùbúlẹ̀ sórí erùpẹ̀ tí ó wà ní ojú pópó.+Àwọn wúńdíá mi àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi alára ti tipa idà ṣubú.+Ìwọ ti pani ní ọjọ́ ìbínú rẹ.+ Ìwọ ti fikú pani;+ ìwọ kò sì ní ìyọ́nú.+ ת [Tọ́ọ̀] 22  Gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ àjọyọ̀,+ o tẹ̀ síwájú láti pe gbogbo ibi tí mo ti ṣe àtìpó yí ká.Àti ní ọjọ́ ìrunú Jèhófà, kò sì wá sí olùsálà tàbí olùlàájá kankan;+Àwọn tí mo bí pẹ̀lú ara pípé tí mo sì tọ́ dàgbà, ọ̀tá mi fúnra rẹ̀ pa wọ́n run pátápátá.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé