Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìdárò 1:1-22

א [Áléfì] 1  Wo bí ó ti jókòó ní òun nìkan,+ ìlú ńlá tí ó kún fún ọ̀pọ̀ yanturu ènìyàn!+ Wo bí ó ti dà bí opó,+ òun tí ó jẹ́ elénìyàn púpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè!+ Wo bí òun tí ó jẹ́ ọmọ aládé obìnrin láàárín àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ ṣe wá wà fún òpò àfipámúniṣe!+ ב [Bétì]   Ó ń sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ ní òru,+ omijé rẹ̀ sì wà ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀.+ Kò ní ẹnì kankan láti inú gbogbo olùfẹ́ rẹ̀ láti tù ú nínú.+ Gbogbo alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ti ṣe àdàkàdekè sí i.+ Wọ́n ti di ọ̀tá rẹ̀.+ ג [Gímélì]   Júdà ti lọ sí ìgbèkùn nítorí ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́+ àti nítorí ọ̀pọ̀ yanturu ìsìnrú.+ Ó ti di dandan fún òun alára láti gbé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ Kò rí ibi ìsinmi kankan. Gbogbo àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí i ti bá a nínú àwọn ipò tí ń kó wàhálà báni.+ ד [Dálétì]   Àwọn ọ̀nà Síónì ń ṣọ̀fọ̀, nítorí ẹnì kankan kò wá sí àjọyọ̀.+ Gbogbo ẹnubodè rẹ̀ ni a sọ di ahoro;+ àwọn àlùfáà rẹ̀ ń mí ìmí ẹ̀dùn.+ Ẹ̀dùn-ọkàn ti kọlu àwọn wúńdíá rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ sì ní ìbìnújẹ́ kíkorò.+ ה [Híì]   Àwọn elénìní rẹ̀ ti di olórí.+ Àwọn ọ̀tá rẹ̀ kò bìkítà.+ Nítorí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ti mú ẹ̀dùn-ọkàn wá bá a ní tìtorí ọ̀pọ̀ yanturu ìrélànàkọjá rẹ̀,+ Àwọn ọmọ òun tìkara rẹ̀ ti rìn ní òǹdè níwájú àwọn elénìní.+ ו [Wọ́ọ̀]   Gbogbo ọlá ńlá ọmọbìnrin Síónì sì ti lọ kúrò lára rẹ̀.+ Àwọn ọmọ aládé rẹ̀ dà bí àwọn akọ àgbọ̀nrín tí kò rí pápá ìjẹko;+ Wọ́n sì ń rìn láìní agbára níwájú ẹni tí ń lépa wọn.+ ז [Sáyínì]   Jerúsálẹ́mù ti rántí ní ọjọ́ tí a ń ṣẹ́ ẹ níṣẹ̀ẹ́ àti ní ọjọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ aláìnílé Gbogbo ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra rẹ̀ tí ó ti wà láti àwọn ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.+ Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú sọ́wọ́ àwọn elénìní tí kò sì ní olùrànlọ́wọ́,+ Àwọn elénìní rí i. Wọ́n rẹ́rìn-ín nítorí ìwólulẹ̀ rẹ̀.+ ח [Kétì]   Jerúsálẹ́mù ti dá ẹ̀ṣẹ̀ paraku.+ Ìdí nìyẹn tí ó fi di ohun ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn.+ Gbogbo àwọn tí ń bọlá fún un ti hùwà sí i bí ohun tí ó jẹ́ ọ̀pọ̀kúyọ̀kú,+ nítorí wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀.+ Òun fúnra rẹ̀ ń mí ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú,+ ó sì yí ẹ̀yìn padà. ט [Tétì]   Ohun àìmọ́ rẹ̀ wà ní ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ̀.+ Kò rántí ọjọ́ ọ̀la rẹ̀,+ Ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ́nà àgbàyanu. Kò ní olùtùnú kankan.+ Jèhófà, wo bí a ti ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́,+ nítorí ọ̀tá ti gbé àgbéré ńláǹlà.+ י [Yódì] 10  Elénìní ti tẹ́ ọwọ́ òun fúnra rẹ̀ lòdì sí gbogbo ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra rẹ̀.+ Nítorí ó ti rí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wá sínú ibùjọsìn rẹ̀,+ Àwọn tí o pàṣẹ pé kí wọ́n má ṣe wá sínú ìjọ tí ó jẹ́ tìrẹ. כ [Káfì] 11  Gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ ń mí ìmí ẹ̀dùn; wọ́n ń wá oúnjẹ.+ Wọ́n ti fi ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra wọn fúnni ní pàṣípààrọ̀ fún ohun jíjẹ, láti tu ọkàn wọn lára.+ Rí i, Jèhófà, kí o sì wò ó, nítorí mo ti dà bí obìnrin tí kò ní láárí.+ ל [Lámédì] 12  Ṣe kò jámọ́ nǹkan kan sí gbogbo ẹ̀yin tí ń kọjá lọ lọ́nà ni? Ẹ wò ó, kí ẹ sì rí i.+ Ìrora kankan ha wà tí ó dà bí ìrora mi tí a ti pín fún mi lọ́nà mímúná,+ Èyí tí Jèhófà fi ṣokùnfà ẹ̀dùn-ọkàn ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀ jíjófòfò?+ מ [Mémì] 13  Láti ibi gíga, ó ti rán iná sínú egungun mi,+ ó sì tẹ gbogbo wọn ba. Ó ti na àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi.+ Ó ti yí mi padà sẹ́yìn. Ó ti sọ mí di obìnrin tí a sọ di ahoro. Láti owúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni mo ń ṣàmódi.+ נ [Núnì] 14  Ó wà lójúfò sí àwọn ìrélànàkọjá mi.+ Ní ọwọ́ rẹ̀, wọ́n lọ́pọ̀ mọ́ ara wọn. Wọ́n ti gòkè wá sí ọrùn mi.+ Agbára mi ti kọsẹ̀. Jèhófà ti fi mi lé ọwọ́ àwọn tí èmi kò lè dìde sí.+ ס [Sámékì] 15  Gbogbo àwọn alágbára mi ni Jèhófà ti bì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kúrò ní àárín mi.+ Ó ti pe ìpàdé sí mi, láti fọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi sí wẹ́wẹ́.+ Jèhófà ti tẹ ìfúntí wáìnì+ tí ó jẹ́ ti wúńdíá ọmọbìnrin Júdà.+ ע [Áyínì] 16  Nítorí nǹkan wọ̀nyí ni mo ṣe ń sunkún bí obìnrin.+ Ojú mi, ojú mi ń ṣan omi wálẹ̀.+ Nítorí olùtùnú ti jìnnà réré sí mi, ẹnì kan láti tu ọkàn mi lára. Àwọn ọmọ mi ti di àwọn tí a sọ di ahoro,+ nítorí ọ̀tá ti gbé àgbéré ńláǹlà.+ פ [Péè] 17  Síónì ti tẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+ Kò ní olùtùnú kankan.+ Jèhófà ti pàṣẹ nípa Jékọ́bù fún gbogbo àwọn tí ó yí i ká bí elénìní rẹ̀.+ Jerúsálẹ́mù ti di ohun ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn láàárín wọn.+ צ [Sádì] 18  Jèhófà jẹ́ olódodo,+ nítorí ẹnu rẹ̀ ni mo ṣọ̀tẹ̀ sí.+ Wàyí o, ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn, kí ẹ sì rí ìrora mi. Àwọn wúńdíá tèmi àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin tèmi ti lọ sí oko òǹdè.+ ק [Kófì] 19  Mo ti pe àwọn tí ń fi ìgbónájanjan nífẹ̀ẹ́ mi.+ Àwọn alára ti ṣe àgálámàṣà sí mi. Nínú ìlú ńlá ni àwọn àlùfáà tèmi àti àwọn arúgbó tèmi ti gbẹ́mìí mì,+ Nígbà tí wọ́n ń wá ohun jíjẹ fún ara wọn kí wọ́n lè tu ọkàn wọn lára.+ ר [Réṣì] 20  Wò ó, Jèhófà, nítorí mo wà nínú hílàhílo.+ Àwọn ìfun mi gan-an ń hó. Ọkàn-àyà mi ti dojú dé nínú mi,+ nítorí ọlọ̀tẹ̀ gbáà ni mo jẹ́.+ Ní òde, idà fa ìṣòfò àwọn ọmọ.+ Ní ilé, ọ̀kan náà ni pẹ̀lú ikú.+ ש [Ṣínì] 21  Àwọn ènìyàn ti gbọ́ bí èmi alára ti ń mí ìmí ẹ̀dùn bí obìnrin.+ Kò sí olùtùnú kankan fún mi.+ Gbogbo ọ̀tá mi alára gbọ́ nípa ìyọnu àjálù mi.+ Wọ́n ti yọ ayọ̀ ńláǹlà, nítorí pé ìwọ fúnra rẹ ni ó ṣe é.+ Dájúdájú, ìwọ yóò mú ọjọ́ tí o pòkìkí wá,+ kí wọ́n lè dà bí èmi.+ ת [Tọ́ọ̀] 22  Kí gbogbo ìwà búburú wọn wá síwájú rẹ, kí o sì bá wọn lò lọ́nà mímúná,+ Gan-an gẹ́gẹ́ bí o ti bá mi lò lọ́nà mímúná ní tìtorí gbogbo ìrélànàkọjá mi.+ Nítorí ìmí ẹ̀dùn mi pọ̀,+ ọkàn-àyà mi sì ń ṣàmódi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé