Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 9:1-43

9  Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù, tí ó ṣì ń mí èémí ìhalẹ̀mọ́ni àti ìṣìkàpànìyàn+ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn+ Olúwa, lọ bá àlùfáà àgbà,  ó sì béèrè fún àwọn lẹ́tà sí àwọn sínágọ́gù ní Damásíkù, kí ó lè mú ẹnikẹ́ni tí ó bá rí tí ó jẹ́ ti Ọ̀nà Náà+ wá sí Jerúsálẹ́mù ní dídè, àti ọkùnrin àti obìnrin.  Wàyí o, bí ó ti ń rin ìrìn àjò lọ, ó sún mọ́ Damásíkù, nígbà tí ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run kọ mànà yí i ká lójijì,+  ó sì ṣubú lulẹ̀, ó sì gbọ́ tí ohùn kan sọ fún un pé: “Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?”+  Ó wí pé: “Ta ni ọ́, Olúwa?” Ó wí pé: “Èmi ni Jésù, ẹni tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí.+  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, dìde,+ kí o sì wọ ìlú ńlá náà, a ó sì sọ ohun tí o gbọ́dọ̀ ṣe fún ọ.”  Wàyí o, àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ ń rin ìrìn àjò+ dúró láìlèsọ̀rọ̀,+ ní tòótọ́, wọ́n ń gbọ́ ìró ohùn,+ ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹnì kankan.  Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù dìde kúrò ní ilẹ̀, bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé ojú rẹ̀ là sílẹ̀, kò rí nǹkan kan.+ Nítorí náà, wọ́n fi ọwọ́ mú un lọ, wọ́n sì sìn ín wọ Damásíkù.  Kò sì rí ohunkóhun fún ọjọ́ mẹ́ta,+ kò jẹ, bẹ́ẹ̀ sì ni kò mu. 10  Ní Damásíkù, ọmọ ẹ̀yìn kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ananíà,+ Olúwa sì wí fún un nínú ìran kan pé: “Ananíà!” Ó wí pé: “Èmi nìyí, Olúwa.” 11  Olúwa wí fún un pé: “Dìde, lọ sí ojú pópó tí a ń pè ní Títọ́, àti pé nínú ilé Júdásì, wá ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù, láti Tásù.+ Nítorí, wò ó! ó ń gbàdúrà, 12  nínú ìran, ó ti rí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ananíà tí ó wọlé wá, tí ó sì gbé ọwọ́ lé e kí ó lè tún máa ríran.”+ 13  Ṣùgbọ́n Ananíà dáhùn pé: “Olúwa, mo ti gbọ́ nípa ọkùnrin yìí láti ẹnu ọ̀pọ̀ ènìyàn, bí ohun aṣeniléṣe tí ó ṣe sí àwọn ẹni mímọ́ rẹ ní Jerúsálẹ́mù ti pọ̀ tó. 14  Ní báyìí, ó ti gba ọlá àṣẹ láti ọwọ́ àwọn olórí àlùfáà láti fi gbogbo àwọn tí ń ké pe orúkọ rẹ sínú àwọn ìdè.”+ 15  Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé: “Mú ọ̀nà rẹ pọ̀n, nítorí ohun èlò tí a ti yàn+ ni ọkùnrin yìí jẹ́ fún mi láti gbé orúkọ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè+ àti àwọn ọba+ àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 16  Nítorí èmi yóò fi hàn án ní kedere bí ohun tí yóò jìyà nítorí orúkọ mi ti pọ̀ tó.”+ 17  Nítorí náà, Ananíà lọ, ó sì wọ ilé náà, ó sì gbé ọwọ́ lé e, ó sì wí pé: “Sọ́ọ̀lù, arákùnrin, Olúwa náà, Jésù tí ó fara hàn ọ́ lójú ọ̀nà tí ìwọ ń gbà bọ̀, ni ó rán mi jáde, kí o lè tún máa ríran, kí o sì kún fún ẹ̀mí mímọ́.”+ 18  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ohun tí ó rí bí ìpẹ́ jábọ́ kúrò ní ojú rẹ̀, ó sì tún ń riran; ó dìde, a sì batisí rẹ̀, 19  ó jẹ oúnjẹ, ó sì jèrè okun.+ Ó wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Damásíkù fún ọjọ́ mélòó kan,+ 20  lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù Jésù+ nínú àwọn sínágọ́gù, pé Ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run. 21  Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ìyàlẹ́nu bá, wọn a sì sọ pé: “Èyí ha kọ́ ni ọkùnrin tí ó run+ àwọn tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù, àwọn tí ń ké pe orúkọ yìí, tí ó sì ti wá síhìn-ín fún ète yìí gan-an, kí ó lè mú wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà ní dídè?”+ 22  Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù ń bá a nìṣó ní títúbọ̀ gba agbára, ó sì ń mú ẹnu àwọn Júù tí ń gbé ní Damásíkù wọhò bí ó ti fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu pé èyí ni Kristi náà.+ 23  Wàyí o, nígbà tí ọ̀pọ̀ ọjọ́ ń bọ̀ wá sí ìparí, àwọn Júù gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.+ 24  Bí ó ti wù kí ó rí, ìdìmọ̀lù wọn lòdì sí i di mímọ̀ fún Sọ́ọ̀lù. Ṣùgbọ́n wọ́n ń ṣọ́ ẹnubòdè pẹ̀lú lójú méjèèjì ní tọ̀sán-tòru, kí wọ́n lè pa á.+ 25  Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbé e, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní òru gba ojú ihò kan lára ògiri, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ nínú apẹ̀rẹ̀.+ 26  Nígbà tí ó dé Jerúsálẹ́mù,+ ó sapá láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn; ṣùgbọ́n gbogbo wọ́n ń fòyà rẹ̀, nítorí wọn kò gbà gbọ́ pé ọmọ ẹ̀yìn ni. 27  Nítorí náà, Bánábà wá ṣe àrànṣe fún un,+ ó sì mú un lọ bá àwọn àpọ́sítélì, ó sì sọ fún wọn ní kúlẹ̀kúlẹ̀ bí òun ti rí Olúwa ní ojú ọ̀nà+ àti pé ó bá òun sọ̀rọ̀,+ àti bí òun ti sọ̀rọ̀ láìṣojo ní orúkọ Jésù ní Damásíkù.+ 28  Ó sì ń bá a lọ ní wíwà pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé wọ̀de ní Jerúsálẹ́mù, ó ń sọ̀rọ̀ láìṣojo ní orúkọ Olúwa;+ 29  ó sì ń bá àwọn Júù tí ń sọ èdè Gíríìkì sọ̀rọ̀, ó sì ń bá wọn ṣe awuyewuye. Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí gbìdánwò láti pa á.+ 30  Nígbà tí àwọn ará jádìí èyí, wọ́n mú un sọ̀ kalẹ̀ wá sí Kesaréà, wọ́n sì rán an lọ sí Tásù.+ 31  Ní tòótọ́, nígbà náà, ìjọ+ jákèjádò Jùdíà àti Gálílì àti Samáríà wọnú sáà àlàáfíà, a ń gbé e ró; bí ó sì ti ń rìn ní ìbẹ̀rù Jèhófà+ àti ní ìtùnú ẹ̀mí mímọ́,+ ó ń di púpọ̀ sí i ṣáá. 32  Wàyí o, bí Pétérù ti ń gba apá gbogbo kọjá, ó sọ̀ kalẹ̀ wá sọ́dọ̀ àwọn ẹni mímọ́ tí ń gbé ní Lídà+ pẹ̀lú. 33  Ibẹ̀ ni ó ti rí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Énéà, ẹni tí ó ti dùbúlẹ̀ gbalaja lórí àkéte rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ alárùn ẹ̀gbà. 34  Pétérù sì wí fún un pé:+ “Énéà, Jésù Kristi mú ọ lára dá.+ Dìde, kí o sì tẹ́ ibùsùn rẹ.” Ó sì dìde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 35  Gbogbo àwọn tí ń gbé Lídà àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣárónì+ rí i, àwọn wọ̀nyí sì yí padà sọ́dọ̀ Olúwa.+ 36  Ṣùgbọ́n ní Jópà,+ ọmọ ẹ̀yìn kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tàbítà, èyí tí ó túmọ̀ sí Dọ́káàsì, nígbà tí a bá túmọ̀ rẹ̀. Ó pọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ rere+ àti àwọn ẹ̀bùn àánú tí òun ń fi fúnni. 37  Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ wọnnì, ó ṣẹlẹ̀ pé ó dùbúlẹ̀ àìsàn, ó sì kú. Nítorí náà, wọ́n wẹ̀ ẹ́, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ìyẹ̀wù òkè. 38  Wàyí o, níwọ̀n bí Lídà ti sún mọ́ Jópà,+ nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn gbọ́ pé Pétérù wà ní ìlú ńlá yìí, wọ́n rán ọkùnrin méjì lọ bá a láti pàrọwà fún un pé: “Jọ̀wọ́ má ṣe lọ́tìkọ̀ láti dé ọ̀dọ̀ wa.” 39  Látàrí èyíinì, Pétérù dìde, ó sì bá wọn lọ. Nígbà tí ó sì dé, wọ́n mú un lọ sí ìyẹ̀wù òkè; gbogbo àwọn opó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń sunkún, wọ́n sì ń fi ọ̀pọ̀ ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti ẹ̀wù àwọ̀lékè+ tí Dọ́káàsì ti máa ń ṣe nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn hàn.+ 40  Ṣùgbọ́n Pétérù lé gbogbo ènìyàn síta,+ ó sì tẹ eékún rẹ̀ ba, ó gbàdúrà, àti pé, ní yíyíjú sí òkú náà, ó wí pé: “Tàbítà, dìde!” Ó la ojú rẹ̀, bí ó sì ti tajú kán rí Pétérù, ó dìde jókòó.+ 41  Ní fífún un ní ọwọ́ rẹ̀, ó gbé e dìde,+ ó sì pe àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn opó, ó sì fà á lé wọn lọ́wọ́ láàyè.+ 42  Èyí di mímọ̀ jákèjádò Jópà, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì di onígbàgbọ́ nínú Olúwa.+ 43  Ó dúró ní Jópà+ fún ọjọ́ púpọ̀ díẹ̀ pẹ̀lú Símónì kan, tí ó jẹ́ oníṣẹ́ awọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé