Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 8:1-40

8  Sọ́ọ̀lù, ní tirẹ̀, fọwọ́ sí ṣíṣìkàpa á.+ Ní ọjọ́ yẹn, inúnibíni ńlá+ dìde sí ìjọ tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù; gbogbo wọn àyàfi àwọn àpọ́sítélì ni a tú ká+ jákèjádò àwọn ẹkùn ilẹ̀ Jùdíà àti Samáríà.  Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin tí ó ní ìfọkànsìn gbé Sítéfánù lọ sin,+ wọ́n sì ṣe ìdárò+ ńláǹlà lórí rẹ̀.  Àmọ́ ṣá o, Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí hùwà sí ìjọ lọ́nà bíburú jáì. Ó ń gbógun ti ilé kan tẹ̀ lé òmíràn àti pé, ní wíwọ́ àti ọkùnrin àti obìnrin jáde, òun a fi wọ́n sẹ́wọ̀n.+  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí a tú ká la ilẹ̀ náà já, wọ́n ń polongo ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà.+  Fílípì, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan, sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ìlú ńlá Samáríà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wàásù Kristi fún wọn.  Pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, àwọn ogunlọ́gọ̀ ń fiyè sí àwọn ohun tí Fílípì sọ bí wọ́n ti fetí sílẹ̀, tí wọ́n sì wo àwọn iṣẹ́ àmì tí ó ń ṣe.  Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn wà tí wọ́n ní àwọn ẹ̀mí àìmọ́,+ ìwọ̀nyí a sì ké jáde ní ohùn rara, wọn a sì jáde. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀ tí ó jẹ́ alárùn ẹ̀gbà+ àti àwọn tí ó yarọ ni a wò sàn.  Nítorí náà, ìdùnnú ńláǹlà wá wà ní ìlú ńlá yẹn.+  Wàyí o, ní ìlú ńlá náà, ọkùnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Símónì, ẹni tí ó jẹ́ pé, ṣáájú èyí, ó ti ń fi idán pípa+ ṣiṣẹ́ ṣe, ó sì ti ń mú kí orílẹ̀-èdè Samáríà ṣe kàyéfì, ó ń sọ pé ẹni ńlá ni òun.+ 10  Gbogbo wọn, láti ẹni tí ó kéré jù lọ títí dé orí ẹni tí ó tóbi jù lọ, a sì fún un ní àfiyèsí, wọn a sì sọ pé: “[Ọkùnrin] yìí jẹ́ Agbára Ọlọ́run, tí a lè pè ní Títóbi.” 11  Nítorí náà, wọn a fún un ní àfiyèsí nítorí pé ó ti mú wọn ṣe kàyéfì fún ìgbà tí ó pẹ́ nípasẹ̀ idán pípa rẹ̀. 12  Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gba Fílípì gbọ́, ẹni tí ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run+ àti orúkọ Jésù Kristi, a bẹ̀rẹ̀ sí batisí wọn, lọ́kùnrin àti lóbìnrin.+ 13  Símónì alára di onígbàgbọ́, àti pé, lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀, ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà gbogbo láti ṣèránṣẹ́ fún Fílípì;+ ó sì ṣe kàyéfì ní rírí àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ agbára ńlá tí ń ṣẹlẹ̀. 14  Nígbà tí àwọn àpọ́sítélì ní Jerúsálẹ́mù gbọ́ pé Samáríà ti tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,+ wọ́n rán Pétérù àti Jòhánù lọ bá wọn; 15  àwọn wọ̀nyí sì sọ̀ kalẹ̀ lọ, wọ́n sì gbàdúrà fún wọn kí wọ́n lè gba ẹ̀mí mímọ́.+ 16  Nítorí pé kò tíì bà lé ẹnikẹ́ni nínú wọn, ṣùgbọ́n a kàn batisí wọn ní orúkọ Jésù Olúwa+ nìkan ni. 17  Nígbà náà ni wọ́n wá ń gbé ọwọ́ lé wọn,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rí ẹ̀mí mímọ́ gbà. 18  Wàyí o, nígbà tí Símónì rí i pé a fúnni ní ẹ̀mí nípasẹ̀ ìgbọ́wọ́léni àwọn àpọ́sítélì, ó fi owó lọ̀ wọ́n,+ 19  ó wí pé: “Ẹ fún èmi náà ní ọlá àṣẹ yìí, kí ẹnikẹ́ni tí mo bá gbé ọwọ́ mi lé lè rí ẹ̀mí mímọ́ gbà.” 20  Ṣùgbọ́n Pétérù wí fún un pé: “Kí fàdákà rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí ìwọ rò pé o lè tipasẹ̀ owó rí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ Ọlọ́run gbà.+ 21  Ìwọ kò ní ipa tàbí ìpín kankan nínú ọ̀ràn yìí, nítorí pé ọkàn-àyà rẹ kò tọ́ lójú Ọlọ́run.+ 22  Nítorí náà, ronú pìwà dà ìwà búburú rẹ yìí, kí o sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà+ pé, bí ó bá ṣeé ṣe, kí a lè dárí ète búburú ọkàn-àyà rẹ jì ọ́; 23  nítorí mo rí i pé òróòró onímájèlé+ àti ìdè àìṣòdodo+ ni ọ́.” 24  Ní ìdáhùn, Símónì wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bá mi rawọ́ ẹ̀bẹ̀+ sí Jèhófà kí ìkankan nínú ohun tí ẹ sọ má bàa dé bá mi.” 25  Nítorí náà, nígbà tí wọ́n ti jẹ́rìí kúnnákúnná tán, tí wọ́n sì ti sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, wọ́n padà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì ń polongo ìhìn rere fún ọ̀pọ̀ abúlé àwọn ará Samáríà.+ 26  Bí ó ti wù kí ó rí, áńgẹ́lì+ Jèhófà bá Fílípì sọ̀rọ̀, pé: “Dìde kí o sì lọ sí gúúsù sí ojú ọ̀nà tí ó sọ̀ kalẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Gásà.” (Èyí jẹ́ ojú ọ̀nà aṣálẹ̀.) 27  Pẹ̀lú èyíinì, ó dìde, ó sì lọ, sì wò ó! ìwẹ̀fà+ ará Etiópíà kan,+ ọkùnrin kan tí ó wà ní ipò agbára lábẹ́ Káńdésì ọbabìnrin àwọn ará Etiópíà, ẹni tí ó sì ń bójú tó gbogbo ìṣúra rẹ̀. Ó ti lọ jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù,+ 28  ṣùgbọ́n ó ń padà bọ̀, ó jókòó sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó sì ń ka ìwé wòlíì Aísáyà+ sókè. 29  Nítorí náà, ẹ̀mí sọ+ fún Fílípì pé: “Sún mọ́ ọn, kí o sì da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ ẹṣin yìí.” 30  Fílípì sáré lọ sí ẹ̀gbẹ́, ó sì gbọ́ tí ó ń ka ìwé Aísáyà wòlíì sókè, ó sì wí pé: “Ní ti gidi, ìwọ ha mọ ohun tí o ń kà bí?” 31  Ó wí pé: “Ní ti tòótọ́, báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà?” Ó sì pàrọwà fún Fílípì pé kí ó gòkè wá, kí ó sì jókòó pẹ̀lú òun. 32  Wàyí o, àyọkà Ìwé Mímọ́ tí ó ń kà sókè nìyí: “Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn, a mú un wá fún ìfikúpa, àti gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ àgùntàn tí kò lè fọhùn níwájú olùrẹ́run rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun kò la ẹnu rẹ̀.+ 33  Nígbà ìtẹ́lógo rẹ̀, a mú ìdájọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.+ Ta ni yóò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìran rẹ̀? Nítorí a mú ìwàláàyè rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ ayé.”+ 34  Ní ìdáhùn, ìwẹ̀fà náà sọ fún Fílípì pé: “Mo bẹ̀ ọ́, Ta ni wòlíì náà sọ èyí nípa rẹ̀? Nípa ara rẹ̀ ni tàbí nípa ẹlòmíràn?” 35  Fílípì la ẹnu rẹ̀+ àti pé, ní bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ yìí,+ ó polongo ìhìn rere nípa Jésù fún un. 36  Wàyí o, bí wọ́n ti ń lọ ní ojú ọ̀nà náà, wọ́n dé ibi ìwọ́jọpọ̀ omi, ìwẹ̀fà náà sì wí pé: “Wò ó! Ìwọ́jọpọ̀ omi; kí ni ó dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?”+ 37  —— 38  Pẹ̀lú èyíinì, ó pàṣẹ pé kí kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà dúró, àwọn méjèèjì sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú omi náà, àti Fílípì àti ìwẹ̀fà náà; ó sì batisí rẹ̀. 39  Nígbà tí wọ́n jáde kúrò nínú omi, ẹ̀mí Jèhófà ṣamọ̀nà Fílípì lọ kíákíá,+ ìwẹ̀fà náà kò sì rí i mọ́, nítorí ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀. 40  Ṣùgbọ́n Áṣídódù ni a rí pé Fílípì wà, ó sì la ìpínlẹ̀ náà já, ó sì ń bá a nìṣó ní pípolongo+ ìhìn rere fún gbogbo àwọn ìlú ńlá títí ó fi dé Kesaréà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé