Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 7:1-60

7  Ṣùgbọ́n àlùfáà àgbà wí pé: “Nǹkan wọ̀nyí ha rí bẹ́ẹ̀ bí?”  Ó wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará àti ẹ̀yin baba, ẹ gbọ́. Ọlọ́run ògo+ fara han Ábúráhámù baba ńlá wa nígbà tí ó wà ní Mesopotámíà, kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Háránì,+  ó sì wí fún un pé, ‘Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, kí o sì wá sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́.’+  Nígbà náà ni ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Háránì. Láti ibẹ̀, lẹ́yìn tí baba rẹ̀ kú,+ Ọlọ́run mú kí ó yí ibùgbé rẹ̀ padà sí ilẹ̀ yìí tí ẹ ń gbé nísinsìnyí.+  Síbẹ̀, kò fún un ní ohun ìní kankan tí ó ṣeé jogún nínú rẹ̀, rárá o, kì í tilẹ̀ ṣe ìbú ẹsẹ̀ kan;+ ṣùgbọ́n ó ṣèlérí láti fi í fún un gẹ́gẹ́ bí ohun ìní,+ àti lẹ́yìn rẹ̀ fún irú-ọmọ rẹ̀,+ nígbà tí kò tíì ní ọmọ kankan.+  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa èyí, pé irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ àwọn àtìpó+ ní ilẹ̀ òkèèrè,+ àwọn ènìyàn náà yóò sì sọ wọ́n di ẹrú, wọn yóò sì ṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́ fún irínwó ọdún.+  ‘Orílẹ̀-èdè tí wọn yóò sì sìnrú fún ni èmi yóò dá lẹ́jọ́,’+ ni Ọlọ́run wí, ‘àti lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, wọn yóò jáde wá, wọn yóò sì ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún mi ní ibí yìí.’+  “Ó fún un ní májẹ̀mú ìdádọ̀dọ́+ pẹ̀lú; ó sì tipa báyìí bí Ísákì,+ ó sì dádọ̀dọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kẹjọ,+ Ísákì sì bí Jékọ́bù, Jékọ́bù sì bí àwọn olórí ìdílé méjìlá.+  Àwọn olórí ìdílé náà sì jowú+ Jósẹ́fù, wọ́n sì tà á sí Íjíbítì.+ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀,+ 10  ó sì dá a nídè kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀, ó sì fún un ní oore ọ̀fẹ́ àti ọgbọ́n lójú Fáráò ọba Íjíbítì. Ó sì yàn án sípò ṣe alákòóso Íjíbítì àti gbogbo ilé rẹ̀.+ 11  Ṣùgbọ́n ìyàn kan mú ní gbogbo Íjíbítì àti Kénáánì, àní ìpọ́njú ńlá; àwọn baba ńlá wa kò sì rí ìpèsè oúnjẹ kankan.+ 12  Ṣùgbọ́n Jékọ́bù gbọ́ pé àwọn èlò oúnjẹ wà ní Íjíbítì,+ ó sì rán àwọn baba ńlá wa jáde ní ìgbà àkọ́kọ́.+ 13  Àti ní ìgbà kejì, a sọ Jósẹ́fù di mímọ̀ fún àwọn arákùnrin rẹ̀;+ ìlà ìran ìdílé Jósẹ́fù sì fara hàn kedere fún Fáráò.+ 14  Nítorí náà, Jósẹ́fù ránṣẹ́ pe Jékọ́bù baba rẹ̀ àti gbogbo ìbátan rẹ̀ láti ibẹ̀,+ iye àwọn tí ó jẹ́ ọkàn márùndínlọ́gọ́rin.+ 15  Jékọ́bù sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì.+ Ó sì di olóògbé;+ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn baba ńlá wa,+ 16  a sì gbé wọn lọ sí Ṣékémù,+ a sì tẹ́ wọn sínú ibojì+ tí Ábúráhámù ti fi owó fàdákà rà ní iye kan lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì ní Ṣékémù.+ 17  “Gan-an gẹ́gẹ́ bí àkókò ti ń sún mọ́lé fún ìmúṣẹ ìlérí tí Ọlọ́run ti polongo ní gbangba fún Ábúráhámù, àwọn ènìyàn náà gbilẹ̀, wọ́n sì di púpọ̀ sí i ní Íjíbítì,+ 18  títí di ìgbà tí ọba mìíràn jẹ lórí Íjíbítì, ẹni tí kò mọ̀ nípa Jósẹ́fù.+ 19  Ẹni yìí lo ọgbọ́n ìṣèlú lòdì sí ẹ̀yà wa,+ ó sì fi ipá mú àwọn baba lọ́nà àìtọ́ láti gbé àwọn ọmọdé jòjòló wọn síta fún ikú, kí a má bàa pa wọ́n mọ́ láàyè.+ 20  Ní àkókò yẹn gan-an ni a bí Mósè,+ ó sì rẹwà lójú Ọlọ́run.+ A sì ṣọlọ́jọ̀jọ̀ rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta ní ilé baba rẹ̀. 21  Ṣùgbọ́n nígbà tí a gbé e síta, ọmọbìnrin Fáráò gbé e, ó sì tọ́ ọ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin òun fúnra rẹ̀.+ 22  Nítorí náà, Mósè ni a fún ní ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n+ àwọn ará Íjíbítì. Ní ti tòótọ́, ó jẹ́ alágbára nínú ọ̀rọ̀+ àti ìṣe rẹ̀. 23  “Wàyí o, nígbà tí àkókò ọdún ogójì rẹ̀ ń pé bọ̀, ó wá sí ọkàn-àyà rẹ̀ láti ṣe àbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 24  Nígbà tí ó sì tajú kán rí ẹnì kan tí a ń hùwà sí lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu, ó gbèjà rẹ̀, ó sì mú ẹ̀san ṣẹ ní kíkún fún ẹni tí a ń ṣe àìdára sí nípa ṣíṣá ará Íjíbítì náà balẹ̀.+ 25  Ó rò pé àwọn arákùnrin òun yóò mòye pé Ọlọ́run ń fún wọn ní ìgbàlà láti ọwọ́ òun,+ ṣùgbọ́n wọn kò mòye èyí. 26  Ní ọjọ́ kejì, ó yọ sí wọn bí wọ́n ti ń jà, ó sì gbìyànjú láti tún mú wọn wà pa pọ̀ ní àlàáfíà,+ ó wí pé: ‘Ẹ̀yin ènìyàn, ará ni yín. Èé ṣe tí ẹ fi ń hùwà sí ara yín lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu?’+ 27  Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń hùwà sí aládùúgbò rẹ̀ lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu sọ́gọ rẹ̀ dànù, ó wí pé, ‘Ta ní yàn ọ́ ṣe olùṣàkóso àti onídàájọ́ lórí wa?+ 28  O kò fẹ́ pa mi lọ́nà kan náà tí o gbà pa ará Íjíbítì náà lánàá, àbí o fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀?’+ 29  Látàrí ọ̀rọ̀ yìí, Mósè fẹsẹ̀ fẹ, ó sì di àtìpó ní ilẹ̀ Mídíánì,+ níbi tí ó ti bí ọmọkùnrin méjì.+ 30  “Nígbà tí ogójì ọdún sì pé, áńgẹ́lì kan fara hàn án nínú aginjù Òkè Ńlá Sínáì nínú ọwọ́ iná ajófòfò ti igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún.+ 31  Wàyí o, nígbà tí Mósè rí i, ẹnu yà á sí ìran náà.+ Ṣùgbọ́n bí ó ti ń sún mọ́ tòsí láti ṣe àyẹ̀wò, ohùn Jèhófà dé, 32  ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ, Ọlọ́run Ábúráhámù àti ti Ísákì àti ti Jékọ́bù.’+ Bí ìwárìrì ti mú un, Mósè kò gbójúgbóyà láti ṣe àyẹ̀wò síwájú sí i. 33  Jèhófà wí fún un pé, ‘Bọ́ sálúbàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí ìwọ dúró lé.+ 34  Dájúdájú, mo ti rí bí a ṣe ń hùwà sí àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ní Íjíbítì+ láìtọ́, mo sì ti gbọ́ ìkérora wọn,+ mo sì ti sọ̀ kalẹ̀ wá láti dá wọn nídè.+ Sì wá nísinsìnyí, èmi yóò rán ọ lọ sí Íjíbítì.’+ 35  Mósè yìí, tí wọ́n sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ní sísọ pé, ‘Ta ní yàn ọ́ ṣe olùṣàkóso àti onídàájọ́?’+ ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run rán+ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso àti olùdáǹdè láti ọwọ́ áńgẹ́lì tí ó fara hàn án nínú igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún. 36  [Ọkùnrin] yìí mú wọn jáde+ lẹ́yìn ṣíṣe àwọn àmì àgbàyanu àti iṣẹ́ àmì ní Íjíbítì+ àti ní Òkun Pupa+ àti ní aginjù fún ogójì ọdún.+ 37  “Èyí ni Mósè tí ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde fún yín láti àárín àwọn arákùnrin yín.’+ 38  Èyí ni ẹni+ tí ó wá wà láàárín ìjọ+ nínú aginjù pẹ̀lú áńgẹ́lì+ tí ó bá a sọ̀rọ̀ lórí Òkè Ńlá Sínáì àti pẹ̀lú àwọn baba ńlá wa, ó sì gba àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde+ ààyè ọlọ́wọ̀ láti fi fún yín. 39  Àwọn baba ńlá wa kọ̀ láti jẹ́ onígbọràn sí i, ṣùgbọ́n wọ́n sọ́gọ rẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan,+ wọ́n sì padà sí Íjíbítì nínú ọkàn-àyà wọn,+ 40  wọ́n sọ fún Áárónì pé, ‘Ṣe àwọn ọlọ́run fún wa tí yóò máa ṣáájú wa. Nítorí Mósè yìí, tí ó mú wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, àwa kò mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.’+ 41  Nítorí náà, wọ́n ṣe ọmọ màlúù kan ní ọjọ́ wọnnì,+ wọ́n sì mú ẹbọ wá fún òrìṣà náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn ara wọn nínú àwọn iṣẹ́ ọwọ́ wọn.+ 42  Nítorí náà, Ọlọ́run yí padà, ó sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́+ láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì+ pé, ‘Èmi kọ́ ni ẹ fi àwọn ẹran ẹbọ àti ẹbọ rúbọ sí fún ogójì ọdún ní aginjù, àbí èmi ni, ilé Ísírẹ́lì?+ 43  Ṣùgbọ́n àgọ́ Mólókù+ àti ìràwọ̀+ ọlọ́run Réfánì ni èyí tí ẹ̀yin tẹ́wọ́ gbà, àwọn àwòrán tí ẹ ṣe láti máa jọ́sìn wọn. Nítorí náà, ṣe ni èmi yóò kó yín lọ+ ré kọjá Bábílónì.’ 44  “Àwọn baba ńlá wa ní àgọ́ ẹ̀rí nínú aginjù, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pa àṣẹ ìtọ́ni nígbà tí ó ń bá Mósè sọ̀rọ̀ láti ṣe é ní ìbámu pẹ̀lú àwòṣe tí ó rí.+ 45  Àwọn baba ńlá wa tí wọ́n sì jogún rẹ̀ tún gbé e wá pẹ̀lú Jóṣúà+ sí ilẹ̀ tí ó jẹ́ ohun ìní àwọn orílẹ̀-èdè,+ àwọn tí Ọlọ́run tì jáde kúrò níwájú àwọn baba ńlá wa.+ Níhìn-ín ni ó wà títí di àwọn ọjọ́ Dáfídì. 46  Ó rí ojú rere+ lójú Ọlọ́run, ó sì béèrè fún àǹfààní pípèsè ibi gbígbé+ fún Ọlọ́run Jékọ́bù. 47  Àmọ́ ṣá o, Sólómọ́nì ni ó kọ́ ilé fún un.+ 48  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ẹni Gíga Jù Lọ kì í gbé àwọn ilé tí a fi ọwọ́ kọ́;+ gan-an gẹ́gẹ́ bí wòlíì náà ti wí, 49  ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,+ ilẹ̀ ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.+ Irú ilé wo ni ẹ óò kọ́ fún mi? ni Jèhófà wí. Tàbí ibo ni ó wà fún ìsinmi mi?+ 50  Ọwọ́ mi ni ó ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?’+ 51  “Ẹ̀yin olóríkunkun àti aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà+ àti etí, nígbà gbogbo ni ẹ máa ń dúró tiiri lòdì sí ẹ̀mí mímọ́; gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá yín ti ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ ń ṣe.+ 52  Èwo nínú àwọn wòlíì ni àwọn baba ńlá yín kò ṣe inúnibíni sí?+ Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n pa+ àwọn tí ó ṣe ìkéde ṣáájú nípa bíbọ̀ Ẹni+ olódodo náà, olùfihàn àti olùṣìkàpa ẹni tí ẹ̀yin jẹ́ nísinsìnyí,+ 53  ẹ̀yin tí ẹ gba Òfin gẹ́gẹ́ bí a ti ta á látaré nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì+ ṣùgbọ́n tí ẹ kò pa á mọ́.” 54  Tóò, ní gbígbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ọkàn-àyà wọn gbọgbẹ́,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí payín keke+ sí i. 55  Ṣùgbọ́n òun, bí ó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó tẹjú mọ́ ọ̀run, ó sì tajú kán rí ògo Ọlọ́run àti Jésù tí ó dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ 56  ó sì wí pé: “Wò ó! mo rí tí ọ̀run ṣí+ sílẹ̀, Ọmọ ènìyàn+ sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”+ 57  Látàrí èyí, wọ́n ké jáde ní bí ohùn wọ́n ṣe lè ròkè tó, wọ́n sì fi ọwọ́ bo etí wọn,+ wọ́n sì rọ́lù ú pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan. 58  Lẹ́yìn tí wọ́n sì sọ ọ́ sẹ́yìn òde ìlú ńlá náà,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ òkúta lù ú.+ Àwọn ẹlẹ́rìí+ sì fi ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn lélẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ ọ̀dọ́kùnrin kan tí a ń pè ní Sọ́ọ̀lù.+ 59  Wọ́n sì ń bá a lọ ní sísọ òkúta lu Sítéfánù bí ó ti ń ké gbàjarè, tí ó sì wí pé: “Jésù Olúwa, gba ẹ̀mí mi.”+ 60  Nígbà náà, ní títẹ eékún rẹ̀ ba, ó ké jáde pẹ̀lú ohùn líle pé: “Jèhófà, má ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.”+ Lẹ́yìn sísọ èyí, ó sì sùn nínú ikú.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé