Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 6:1-15

6  Wàyí o, ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú dìde níhà ọ̀dọ̀ àwọn Júù tí ń sọ èdè Gíríìkì+ lòdì sí àwọn Júù tí ń sọ èdè Hébérù, nítorí pé àwọn opó wọn ni a ń gbójú fò dá nínú ìpín-fúnni ojoojúmọ́.+  Nítorí náà, àwọn méjìlá náà pe ògìdìgbó àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ ara wọn, wọ́n sì wí pé: “Kò dùn mọ́ wa nínú láti fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀ lọ máa pín oúnjẹ sórí àwọn tábìlì.+  Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ ṣàwárí+ fún ara yín, ọkùnrin méje tí a jẹ́rìí gbè láàárín yín, tí wọ́n kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n,+ kí a lè yàn wọ́n sípò lórí iṣẹ́ àmójútó tí ó pọn dandan yìí;  ṣùgbọ́n àwa yóò fi ara wa fún àdúrà àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”+  Ohun tí wọ́n sọ sì dùn mọ́ gbogbo ògìdìgbó náà nínú, wọ́n sì yan Sítéfánù, ọkùnrin kan tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí mímọ́,+ àti Fílípì+ àti Pírókórọ́sì àti Níkánọ̀ àti Tímónì àti Páménásì àti Níkóláọ́sì, aláwọ̀ṣe kan ará Áńtíókù;  wọ́n sì fi wọ́n sí iwájú àwọn àpọ́sítélì, àti pé, lẹ́yìn tí wọ́n ti gbàdúrà, àwọn wọ̀nyí gbé ọwọ́+ lé wọn.  Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń bá a lọ ní gbígbilẹ̀,+ iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń di púpọ̀ sí i ṣáá ní Jerúsálẹ́mù;+ ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn àlùfáà+ sì bẹ̀rẹ̀ sí di onígbọràn+ sí ìgbàgbọ́ náà.  Wàyí o, Sítéfánù, ẹni tí ó kún fún oore ọ̀fẹ́ àti agbára, ń ṣe àwọn àmì àgbàyanu ńlá àti àwọn iṣẹ́ àmì+ láàárín àwọn ènìyàn.  Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin kan dìde lára àwọn tí wọ́n wá láti inú èyí tí àwọn ènìyàn ń pè ní Sínágọ́gù Àwọn Olómìnira, àti lára àwọn ará Kírénè àti àwọn ará Alẹkisáńdíríà+ àti lára àwọn tí wọ́n wá láti Sìlíṣíà+ àti Éṣíà, láti bá Sítéfánù ṣe awuyewuye; 10  síbẹ̀, wọn kò lè dúró lòdì sí ọgbọ́n+ àti ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀.+ 11  Lẹ́yìn náà, ní bòókẹ́lẹ́, wọ́n sún àwọn ènìyàn láti sọ pé:+ “Àwa ti gbọ́ tí ó ń sọ àwọn àsọjáde tí ó kún fún ọ̀rọ̀ òdì+ sí Mósè àti Ọlọ́run.” 12  Wọ́n sì ru àwọn ènìyàn náà sókè àti àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn akọ̀wé òfin, àti pé, ní dídé bá a lójijì, wọ́n fi ipá mú un, wọ́n sì mú un lọ síwájú Sànhẹ́dírìn.+ 13  Wọ́n sì mú àwọn ẹlẹ́rìí èké+ wá síwájú, tí wọ́n wí pé: “Ọkùnrin yìí kò dẹ́kun sísọ àwọn nǹkan lòdì sí ibi mímọ́ yìí àti lòdì sí Òfin.+ 14  Fún àpẹẹrẹ, a gbọ́ tí ó wí pé Jésù yìí tí í ṣe ará Násárétì yóò wó ibí yìí palẹ̀, yóò sì yí àwọn àṣà tí Mósè fi lé wa lọ́wọ́ padà.” 15  Bí gbogbo àwọn tí ó jókòó ní Sànhẹ́dírìn sì ti tẹjú mọ́ ọn,+ wọ́n rí i pé ojú rẹ̀ rí bí ojú áńgẹ́lì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé