Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 5:1-42

5  Bí ó ti wù kí ó rí, ọkùnrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ananíà, pa pọ̀ pẹ̀lú Sáfírà aya rẹ̀, ta ohun ìní kan,  ó sì yọ lára iye owó náà pa mọ́, aya rẹ̀ pẹ̀lú mọ̀ nípa rẹ̀, ó sì mú kìkì apá kan wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì.+  Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé: “Ananíà, èé ṣe tí Sátánì+ fi kì ọ́ láyà láti ṣèké+ sí ẹ̀mí mímọ́+ àti láti yọ lára iye owó pápá náà pa mọ́?  Ní gbogbo àkókò tí ó wà lọ́wọ́ rẹ, kì í ha ṣe tìrẹ síbẹ̀, lẹ́yìn tí o sì tà á, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ síbẹ̀ bí? Èé ṣe tí o fi pète irúfẹ́ ìwà yìí ní ọkàn-àyà rẹ? Kì í ṣe ènìyàn ni o ṣèké+ sí, bí kò ṣe Ọlọ́run.”+  Nígbà tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Ananíà ṣubú lulẹ̀, ó sì gbẹ́mìí mì.+ Ẹ̀rù ńlá+ sì dé bá gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀.  Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀dọ́kùnrin dìde, wọ́n fi aṣọ wé e,+ wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sì sin ín.  Wàyí o, lẹ́yìn tí nǹkan bí wákàtí mẹ́ta ti kọjá, aya rẹ̀ wọlé wá, láìmọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀.  Pétérù wí fún un pé: “Sọ fún mi, ṣé iye tí ẹ̀yin méjèèjì ta pápá náà nìyẹn?” Ó wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, iye náà nìyẹn.”  Nítorí náà, Pétérù wí fún un pé: “Èé ṣe tí ẹ̀yin méjèèjì fi fohùn ṣọ̀kan láàárín ara yín láti dán ẹ̀mí Jèhófà wò?+ Wò ó! Ẹsẹ̀ àwọn tí wọ́n sin ọkọ rẹ ń bẹ lẹ́nu ilẹ̀kùn, wọn yóò sì gbé ọ jáde.” 10  Ní ìṣẹ́jú akàn, ó ṣubú lulẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì gbẹ́mìí mì.+ Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà wọlé, wọ́n bá a tí ó ti kú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀gbẹ́ ọkọ rẹ̀. 11  Nítorí náà, ẹ̀rù ńlá dé bá gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí. 12  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti àmì àgbàyanu láti ọwọ́ àwọn àpọ́sítélì ń bá a lọ láti máa ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn;+ gbogbo wọ́n sì wà nínú ìloro Sólómọ́nì pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan.+ 13  Lóòótọ́, kò sí ẹyọ ẹnì kan nínú àwọn mìíràn tí ó ní ìgboyà láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ wọn;+ bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ènìyàn náà ń kókìkí wọn.+ 14  Jù èyíinì lọ, ṣe ni a ń fi àwọn onígbàgbọ́ nínú Olúwa kún wọn ṣáá, ògìdìgbó lọ́kùnrin àti lóbìnrin;+ 15  tí ó fi jẹ́ pé wọ́n gbé àwọn aláìsàn jáde, àní sí àwọn ọ̀nà fífẹ̀, tí wọ́n sì tẹ́ wọn síbẹ̀ lórí àwọn ibùsùn kéékèèké àti àkéte, kí ó bàa lè jẹ́ pé, bí Pétérù bá ti ń kọjá lọ, ó kéré tán kí òjìji rẹ̀ lè bọ́ sórí àwọn kan lára wọn.+ 16  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ògìdìgbó láti àwọn ìlú ńlá tí ó wà ní àyíká Jerúsálẹ́mù ń jùmọ̀ wá ṣáá, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn wá àti àwọn tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń dà láàmú, a sì ń wo gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sàn. 17  Ṣùgbọ́n àlùfáà àgbà àti gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, ẹ̀ya ìsìn àwọn Sadusí tí ń bẹ nígbà náà, dìde wọ́n sì kún fún owú,+ 18  wọ́n sì gbé ọwọ́ lé àwọn àpọ́sítélì, wọ́n sì fi wọ́n sí ibi ìhámọ́ ti ìlú.+ 19  Ṣùgbọ́n ní òru áńgẹ́lì+ Jèhófà ṣí àwọn ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n náà,+ ó mú wọn jáde, ó sì wí pé: 20  “Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n, àti pé, nígbà tí ẹ bá ti dúró nínú tẹ́ńpìlì, ẹ máa bá a nìṣó ní sísọ gbogbo àsọjáde nípa ìyè yìí fún àwọn ènìyàn.”+ 21  Lẹ́yìn gbígbọ́ èyí, wọ́n wọ tẹ́ńpìlì lọ ní àfẹ̀mọ́jú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni. Wàyí o, nígbà tí àlùfáà àgbà àti àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ dé, wọ́n pe Sànhẹ́dírìn jọ àti gbogbo àjọ àgbààgbà ọkùnrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ wọ́n sì ránṣẹ́ sí túbú pé kí a mú wọn wá. 22  Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn onípò àṣẹ dé ibẹ̀, wọn kò rí wọn nínú ẹ̀wọ̀n. Nítorí náà, wọ́n padà lọ ròyìn, 23  pé: “A bá túbú ní títì pa pẹ̀lú gbogbo ààbò àti àwọn ẹ̀ṣọ́ tí wọ́n dúró ní ẹnu àwọn ilẹ̀kùn, ṣùgbọ́n nígbà tí a ṣílẹ̀kùn, a kò rí ẹnì kankan nínú rẹ̀.” 24  Tóò, nígbà tí olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì àti àwọn olórí àlùfáà gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ìpòrúùru ọkàn bá wọn lórí nǹkan wọ̀nyí ní ti ohun tí èyí yóò yọrí sí.+ 25  Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan dé, ó sì ròyìn fún wọn pé: “Wò ó! Àwọn ọkùnrin tí ẹ fi sẹ́wọ̀n wà nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n dúró, wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.”+ 26  Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ jáde lọ pẹ̀lú àwọn onípò àṣẹ rẹ̀, ó sì tẹ̀ síwájú láti mú wọn wá, ṣùgbọ́n láìsí ìwà ipá, níwọ̀n bí wọ́n ti ń fòyà+ pé àwọn ènìyàn yóò sọ àwọn lókùúta. 27  Nítorí náà, wọ́n mú wọn wá, wọ́n sì mú wọn dúró nínú gbọ̀ngàn Sànhẹ́dírìn. Àlùfáà àgbà sì bi wọ́n léèrè, 28  ó sì wí pé: “A pa àṣẹ+ fún yín ní pàtó láti má ṣe máa kọ́ni nípa orúkọ yìí, síbẹ̀, sì wò ó! ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún Jerúsálẹ́mù,+ ẹ sì pinnu láti mú ẹ̀jẹ̀+ ọkùnrin yìí wá sórí wa.” 29  Ní ìdáhùn, Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù wí pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.+ 30  Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa gbé Jésù dìde,+ ẹni tí ẹ̀yin pa, ní gbígbé e kọ́ sórí òpó igi.+ 31  Ọlọ́run gbé ẹni yìí ga gẹ́gẹ́ bí Olórí Aṣojú+ àti Olùgbàlà+ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,+ láti fi ìrònúpìwàdà+ fún Ísírẹ́lì àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.+ 32  Àwa sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí,+ bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀mí mímọ́,+ èyí tí Ọlọ́run ti fi fún àwọn tí ń ṣègbọràn sí i gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso.” 33  Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ó dùn wọ́n wọra, wọ́n sì ń fẹ́ láti pa wọ́n.+ 34  Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan dìde nínú Sànhẹ́dírìn, Farisí kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gàmálíẹ́lì,+ olùkọ́ Òfin tí gbogbo ènìyàn kà sí, ó sì pa àṣẹ pé kí a fi àwọn ọkùnrin náà sí òde fún ìgbà díẹ̀.+ 35  Ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì,+ ẹ kíyè sí ara yín ní ti ohun tí ẹ ń pète-pèrò láti ṣe nípa àwọn ọkùnrin wọ̀nyí. 36  Fún àpẹẹrẹ, ní ìjelòó, Téúdásì dìde, ó sọ pé òun jẹ́ ènìyàn pàtàkì,+ iye àwọn ènìyàn kan, nǹkan bí irínwó sì dara pọ̀ mọ́ àjọ ẹgbẹ́ rẹ̀.+ Ṣùgbọ́n wọ́n pa á, gbogbo àwọn tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i fọ́n ká, wọ́n sì di asán. 37  Lẹ́yìn rẹ̀ Júdásì ará Gálílì dìde ní àwọn ọjọ́ ìforúkọsílẹ̀,+ ó sì fa àwọn ènìyàn sẹ́yìn ara rẹ̀. Síbẹ̀, ọkùnrin yẹn ṣègbé, gbogbo àwọn tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i tú ká káàkiri. 38  Nítorí náà, lábẹ́ àwọn ipò ìsinsìnyí, mo wí fún yín pé, Ẹ má tojú bọ ọ̀ràn àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ wọn jẹ́ẹ́; (nítorí pé, bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ ènìyàn ni ìpètepèrò tàbí iṣẹ́ yìí ti wá, a ó bì í ṣubú;+ 39  ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni,+ ẹ kì yóò lè bì wọ́n ṣubú;)+ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè wá rí yín ní ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà ní ti gidi.”+ 40  Látàrí èyí, wọ́n kọbi ara sí i, wọ́n sì fi ọlá àṣẹ pe àwọn àpọ́sítélì, wọ́n nà wọ́n lẹ́gba,+ wọ́n sì pa àṣẹ fún wọn pé kí wọ́n dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù,+ wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lọ. 41  Nítorí náà, àwọn wọ̀nyí bá ọ̀nà wọn lọ kúrò níwájú Sànhẹ́dírìn, wọ́n ń yọ̀+ nítorí a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nítorí orúkọ rẹ̀.+ 42  Ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé+ ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni+ àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé