Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 4:1-37

4  Wàyí o, bí àwọn méjèèjì ti ń bá àwọn ènìyàn náà sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà àti olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì+ àti àwọn Sadusí+ dé bá wọn,  inú ń bí wọn nítorí pé wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì ń polongo ní kedere àjíǹde kúrò nínú òkú ní ti ọ̀ràn Jésù;+  wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì fi wọ́n sí ìhámọ́ títí di ọjọ́ kejì,+ nítorí ó ti di ìrọ̀lẹ́ nísinsìnyí.  Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n ti fetí sí ọ̀rọ̀ náà gbà gbọ́,+ iye àwọn ọkùnrin náà sì di nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún.+  Ní ọjọ́ kejì, ìkórajọpọ̀ àwọn olùṣàkóso wọn àti àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn akọ̀wé òfin+ wáyé ní Jerúsálẹ́mù  (àti Ánásì+ olórí àlùfáà pẹ̀lú àti Káyáfà+ àti Jòhánù àti Alẹkisáńdà àti gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹbí olórí àlùfáà),  wọ́n sì mú wọn dúró ní àárín wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí pé: “Agbára wo tàbí orúkọ ta ni ẹ fi ṣe èyí?”+  Nígbà náà ni Pétérù, tí ó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́,+ wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin olùṣàkóso àwọn ènìyàn àti ẹ̀yin àgbà ọkùnrin,  bí a bá ń wádìí wa wò lónìí yìí, nítorí iṣẹ́ rere fún ọkùnrin kan tí ń ṣòjòjò,+ ní ti ipasẹ̀ ẹni tí a gbà mú [ọkùnrin] yìí lára dá, 10  kí ó di mímọ̀ fún gbogbo yín àti fún gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì, pé ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárétì,+ ẹni tí ẹ̀yin kàn mọ́gi+ ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run gbé dìde kúrò nínú òkú,+ nípasẹ̀ ẹni yìí ni ọkùnrin yìí fi dúró níhìn-ín pẹ̀lú ara dídá níwájú yín. 11  Èyí ni ‘òkúta tí ẹ̀yin akọ́lé hùwà sí bí aláìjámọ́ nǹkan kan tí ó ti di olórí igun ilé.’+ 12  Síwájú sí i, kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn, nítorí kò sí orúkọ mìíràn+ lábẹ́ ọ̀run tí a ti fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a ó fi gbà wá là.”+ 13  Wàyí o, nígbà tí wọ́n rí àìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀ Pétérù àti Jòhánù, tí wọ́n sì róye pé wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rí i kedere nípa wọn pé wọ́n ti máa ń wà pẹ̀lú Jésù;+ 14  bí wọ́n sì ti ń wo ọkùnrin tí a ti wòsàn tí ó dúró pẹ̀lú wọn,+ wọn kò ní nǹkan kan láti sọ ní ìjáníkoro.+ 15  Nítorí náà, wọ́n pàṣẹ fún wọn láti lọ sóde gbọ̀ngàn Sànhẹ́dírìn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fikùn lukùn láàárín ara wọn, 16  wọ́n wí pé: “Kí ni kí a ti ṣe àwọn ọkùnrin wọ̀nyí?+ Nítorí, ní ti tòótọ́, iṣẹ́ àmì tí ó yẹ fún àfiyèsí ti ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ wọn, ọ̀kan tí ó fara hàn kedere fún gbogbo olùgbé Jerúsálẹ́mù;+ a kò sì lè sẹ́ ẹ. 17  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kí a má bàa tàn án káàkiri síwájú sí i láàárín àwọn ènìyàn, ẹ jẹ́ kí a sọ fún wọn pẹ̀lú ìhalẹ̀mọ́ni pé kí wọ́n má ṣe bá ènìyàn kankan sọ̀rọ̀ mọ́ ní orúkọ yìí.”+ 18  Pẹ̀lú èyíinì, wọ́n pè wọ́n, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn, láti má ṣe sọ àsọjáde kankan níbikíbi tàbí kọ́ni ní orúkọ Jésù. 19  Ṣùgbọ́n ní ìfèsìpadà, Pétérù àti Jòhánù wí fún wọn pé: “Bí ó bá jẹ́ òdodo lójú Ọlọ́run láti fetí sí yín dípò Ọlọ́run, ẹ fúnra yín ṣèdájọ́. 20  Ṣùgbọ́n ní tiwa, àwa kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.”+ 21  Nítorí náà, nígbà tí wọ́n ti halẹ̀ mọ́ wọn síwájú sí i, wọ́n tú wọn sílẹ̀, níwọ̀n bí wọn kò ti rí ìdí kankan láti fìyà jẹ wọ́n àti ní tìtorí àwọn ènìyàn náà,+ nítorí pé gbogbo wọ́n ń yin Ọlọ́run lógo nítorí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀; 22  nítorí pé ọkùnrin tí iṣẹ́ àmì ìmúláradá yìí ṣẹlẹ̀ sí ju ẹni ogójì ọdún. 23  Lẹ́yìn tí a tú wọn sílẹ̀, wọ́n lọ bá àwọn ènìyàn tiwọn,+ wọ́n sì ròyìn ohun tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin wí fún wọn. 24  Ní gbígbọ́ èyí, wọ́n gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run+ pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n sì wí pé: “Olúwa Ọba Aláṣẹ,+ ìwọ ni Ẹni tí ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn,+ 25  àti ẹni tí ó sọ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ẹnu baba ńlá wa Dáfídì,+ ìránṣẹ́ rẹ pé, ‘Èé ṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi di onírúkèrúdò, tí àwọn ènìyàn sì ń ṣe àṣàrò lórí àwọn nǹkan òfìfo?+ 26  Àwọn ọba ilẹ̀ ayé mú ìdúró wọn, àwọn olùṣàkóso sì wọ́ jọpọ̀ ṣe ọ̀kan lòdì sí Jèhófà àti lòdì sí ẹni àmì òróró rẹ̀.’+ 27  Bí èyí tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àti Hẹ́rọ́dù àti Pọ́ńtíù Pílátù+ pẹ̀lú àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì ní ti gidi ti kóra jọpọ̀ ní ìlú ńlá yìí lòdì sí Jésù ìránṣẹ́ rẹ mímọ́,+ ẹni tí ìwọ fòróró yàn,+ 28  kí wọ́n lè ṣe àwọn ohun tí ọwọ́ àti ète rẹ ti yàn ṣáájú pé kí ó ṣẹlẹ̀.+ 29  Àti pé nísinsìnyí, Jèhófà, fiyè sí àwọn ìhalẹ̀mọ́ni wọn,+ kí o sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹrú rẹ láti máa bá a nìṣó ní fífi àìṣojo rárá sọ ọ̀rọ̀ rẹ,+ 30  bí o ti ń na ọwọ́ rẹ jáde fún ìmúniláradá àti bí àwọn iṣẹ́ àmì àti àmì àgbàyanu+ ti ń ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ orúkọ+ Jésù ìránṣẹ́ rẹ mímọ́.”+ 31  Nígbà tí wọ́n sì ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ tán, ibi tí wọ́n kóra jọpọ̀ sí mì;+ gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sì kún fún ẹ̀mí mímọ́,+ wọ́n sì ń fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.+ 32  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ògìdìgbó àwọn tí wọ́n ti gbà gbọ́, ní ọkàn-àyà àti ọkàn kan,+ àti pé kò tilẹ̀ sí ẹni tí ń sọ pé èyíkéyìí lára àwọn ohun tí òun ní jẹ́ tòun; ṣùgbọ́n wọ́n ní ohun gbogbo ní àpapọ̀.+ 33  Bákan náà, pẹ̀lú agbára ńlá ni àwọn àpọ́sítélì fi ń bá a lọ ní jíjẹ́ ẹ̀rí nípa àjíǹde Jésù Olúwa;+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ní ìwọ̀n púpọ̀ gan-an sì wà lórí gbogbo wọn. 34  Ní ti tòótọ́, kò sí ọ̀kan láàárín wọn tí ó wà nínú àìní;+ nítorí gbogbo àwọn tí ó ní pápá tàbí ilé a tà wọ́n, wọn a sì mú iye owó àwọn ohun tí wọ́n tà wá, 35  wọn a sì fi wọ́n lélẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì.+ Ẹ̀wẹ̀, wọn a pín nǹkan+ fún olúkúlùkù, gan-an gẹ́gẹ́ bí àìní rẹ̀ bá ṣe rí. 36  Nítorí náà, Jósẹ́fù, tí àwọn àpọ́sítélì fún ní orúkọ àpèlé náà Bánábà,+ èyí tí ó túmọ̀ sí Ọmọ Ìtùnú, nígbà tí a bá túmọ̀ rẹ̀, ọmọ Léfì kan, ọmọ ìbílẹ̀ Kípírù, 37  tí ó ní ilẹ̀ kan, ó tà á, ó sì mú owó náà wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé