Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 3:1-26

3  Wàyí o, Pétérù àti Jòhánù ń gòkè lọ sínú tẹ́ńpìlì fún wákàtí àdúrà, ní wákàtí kẹsàn-án,+  ọkùnrin kan tí ó ti yarọ láti inú ilé ọlẹ̀+ ìyá rẹ̀ ni a sì máa ń gbé, lójoojúmọ́ ni wọ́n sì máa ń gbé e sí tòsí ẹnu ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì tí a ń pè ní Ẹlẹ́wà,+ kí ó bàa lè máa béèrè àwọn ẹ̀bùn àánú lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ tẹ́ńpìlì.+  Nígbà tí ó tajú kán rí Pétérù àti Jòhánù tí wọ́n fẹ́ wọ tẹ́ńpìlì, ó bẹ̀rẹ̀ sí béèrè fún rírí àwọn ẹ̀bùn àánú gbà.+  Ṣùgbọ́n Pétérù, pa pọ̀ pẹ̀lú Jòhánù, tẹjú mọ́+ ọn, wọ́n sì wí pé: “Bojú wò wá.”  Nítorí náà, ó fi àfiyèsí rẹ̀ sọ́dọ̀ wọn, ó ń fojú sọ́nà láti rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn.  Bí ó ti wù kí ó rí, Pétérù wí pé: “Fàdákà àti wúrà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní ni èmi fún ọ:+ Ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárétì,+ máa rìn!”+  Pẹ̀lú èyíinì, ó di ọwọ́ ọ̀tún+ rẹ̀ mú, ó sì gbé e dìde. Ní ìṣẹ́jú akàn, àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun ọrùn ẹsẹ̀ rẹ̀ ní a mú le gírí;+  àti pé, ó fò sókè,+ ó dìde dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ tẹ́ńpìlì,+ ó ń rìn, ó ń fò sókè, ó sì ń yin Ọlọ́run.  Gbogbo ènìyàn+ sì rí i tí ó ń rìn, tí ó sì ń yin Ọlọ́run. 10  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dá a mọ̀, pé èyí ni ọkùnrin tí ó ti máa ń jókòó fún àwọn ẹ̀bùn àánú ní Ẹnubodè Ẹlẹ́wà+ ti tẹ́ńpìlì, wọ́n sì wá kún fún ìyàlẹ́nu àti ayọ̀ púpọ̀ jọjọ+ nítorí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i. 11  Tóò, bí ọkùnrin náà ti dìrọ̀ mọ́ Pétérù àti Jòhánù, gbogbo ènìyàn sáré pa pọ̀ lọ bá wọn níbi tí a ń pè ní ìloro Sólómọ́nì,+ ó yà wọ́n lẹ́nu gidigidi. 12  Nígbà tí Pétérù rí èyí, ó wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, èé ṣe tí ẹ fi ń ṣe kàyéfì lórí èyí, tàbí èé ṣe tí ẹ fi ń tẹjú mọ́ wa bí ẹni pé nípa agbára ara wa tàbí fífọkànsin Ọlọ́run ni a fi mú un rìn?+ 13  Ọlọ́run Ábúráhámù àti ti Ísákì àti ti Jékọ́bù,+ Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, ti ṣe Ìránṣẹ́ rẹ̀,+ Jésù lógo,+ ẹni tí ẹ̀yin, ní tiyín, fà léni lọ́wọ́+ tí ẹ sì sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní ojú Pílátù, nígbà tí ó ti pinnu láti tú u sílẹ̀.+ 14  Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹni mímọ́ àti olódodo yẹn,+ ẹ sì béèrè fún ọkùnrin kan, òṣìkàpànìyàn,+ pé kí a yọ̀ǹda rẹ̀ fún yín ní fàlàlà, 15  àmọ́ ṣá o, ẹ pa Olórí Aṣojú ìyè.+ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú òkú, òtítọ́ tí àwa jẹ́ ẹlẹ́rìí fún.+ 16  Nítorí náà, orúkọ rẹ̀, nípa ìgbàgbọ́ wa nínú orúkọ rẹ̀, ni ó mú kí ọkùnrin yìí lókun ẹni tí ẹ̀yin rí tí ẹ sì mọ̀, ìgbàgbọ́ tí ó sì jẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀ ni ó fún ọkùnrin náà ní ara dídáṣáṣá yìí lójú gbogbo yín. 17  Wàyí o, ẹ̀yin ará, èmi mọ̀ pé ẹ gbé ìgbésẹ̀ ní àìmọ̀,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn olùṣàkóso+ yín pẹ̀lú ti ṣe. 18  Ṣùgbọ́n lọ́nà yìí ni Ọlọ́run ti gbà mú àwọn ohun tí ó kéde tẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì ṣẹ, pé Kristi òun yóò jìyà.+ 19  “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà,+ kí ẹ sì yí padà,+ kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́,+ kí àwọn àsìkò títunilára+ lè wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, 20  kí ó sì lè rán Kristi tí a yàn sípò jáde fún yín, Jésù, 21  ẹni tí ọ̀run, ní tòótọ́, gbọ́dọ̀ gbà sínú ara rẹ̀+ títí di àwọn àkókò ìmúpadàbọ̀sípò+ ohun gbogbo èyí tí Ọlọ́run sọ láti ẹnu àwọn wòlíì+ rẹ̀ mímọ́ ti ìgbà láéláé. 22  Ní ti tòótọ́, Mósè wí pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi+ dìde fún yín láti àárín àwọn arákùnrin yín. Ẹ gbọ́dọ̀ fetí sí i ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó bá ń sọ fún yín.+ 23  Ní tòótọ́, ọkàn èyíkéyìí tí kò bá fetí sí Wòlíì yẹn ni a ó pa run pátápátá kúrò láàárín àwọn ènìyàn.’+ 24  Gbogbo àwọn wòlíì náà, ní ti tòótọ́, láti ìgbà Sámúẹ́lì síwájú àti àwọn tí ó tẹ̀ lé e, gan-an gẹ́gẹ́ bí iye àwọn tí ó sọ̀rọ̀ ti pọ̀ tó, ni wọ́n sì ti polongo ọjọ́ wọ̀nyí+ ní kedere pẹ̀lú. 25  Ẹ̀yin ni ọmọ+ àwọn wòlíì àti ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run fi bá àwọn baba ńlá yín dá májẹ̀mú, ní sísọ fún Ábúráhámù pé, ‘Nínú irú-ọmọ rẹ ni a ó sì ti bù kún gbogbo àwọn ìdílé ilẹ̀ ayé.’+ 26  Ẹ̀yin ni Ọlọ́run kọ́kọ́+ rán Ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde sí, lẹ́yìn gbígbé e dìde, láti bù kún yín nípa yíyí olúkúlùkù padà kúrò nínú àwọn iṣẹ́ burúkú yín.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé