Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 27:1-44

27  Wàyí o, bí a ti pinnu rẹ̀ pé kí a ṣíkọ̀ lọ sí Ítálì,+ wọ́n tẹ̀ síwájú láti fi Pọ́ọ̀lù àti àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn kan lé ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan lọ́wọ́ ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Júlíọ́sì ti àwùjọ ọmọ ogun Ọ̀gọ́sítọ́sì.  Ní wíwọ ọkọ̀ ojú omi kan láti Adiramítíúmù tí ó máa tó ṣí lọ sí àwọn ibi tí ó wà ní etí òkun àgbègbè Éṣíà, a ṣíkọ̀, Àrísítákọ́sì+ ará Makedóníà láti Tẹsalóníkà wà pẹ̀lú wa.  Ní ọjọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sídónì, Júlíọ́sì sì hùwà sí Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú inú rere ẹ̀dá ènìyàn,+ ó sì gbà á láyè láti lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kí ó sì gbádùn ìtọ́jú wọn.+  Bí a sì ti ṣíkọ̀ sójú òkun láti ibẹ̀, a tukọ̀ lábẹ́ ààbò Kípírù, nítorí pé ẹ̀fúùfù ṣọwọ́ òdì;  a sì tukọ̀ la òkun gbalasa kọjá Sìlíṣíà àti Panfílíà, a sì gúnlẹ̀ sí èbúté ọkọ̀ ní Máírà ní Líkíà.  Ṣùgbọ́n níbẹ̀, ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun rí ọkọ̀ ojú omi kan láti Alẹkisáńdíríà+ tí ń lọ sí Ítálì, ó sì mú wa wọ̀ ọ́.  Nígbà náà, lẹ́yìn títukọ̀ lọ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ díẹ̀, tí a sì dé Kínídọ́sì pẹ̀lú ìṣòro, nítorí pé ẹ̀fúùfù kò jẹ́ kí a tẹ̀ síwájú, a tukọ̀ lábẹ́ ààbò Kírétè ní Sálímónè, 8  àti pé ní títukọ̀ lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ etíkun rẹ̀ pẹ̀lú ìṣòro, a dé ibi tí a ń pè ní Èbúté Rere, nítòsí èyí tí ìlú ńlá náà Láséà wà.  Níwọ̀n bí àkókò gígùn ti kọjá, tí ó sì léwu nísinsìnyí láti tukọ̀ nítorí pé ààwẹ̀ [ọjọ́ ètùtù]+ pàápàá ti kọjá lọ ná, Pọ́ọ̀lù dá a lámọ̀ràn, 10  ní sísọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, mo róye pé ìtukọ̀ yóò mú òfò àti àdánù ńlá lọ́wọ́, kì í ṣe kìkì sí ẹrù àti ọkọ̀ ojú omi nìkan ni, ṣùgbọ́n sí ọkàn wa pẹ̀lú.”+ 11  Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà ń bá a lọ ní gbígbọ́ ti atukọ̀ àti ọlọ́kọ̀ dípò àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ. 12  Wàyí o, níwọ̀n bí èbúté ọkọ̀ òkun náà kò ti dẹrùn fún lílo ìgbà òtútù, àwọn tí ó pọ̀ jù dámọ̀ràn ṣíṣíkọ̀ kúrò níbẹ̀, láti rí i bí wọ́n bá lè dé Fóníìsì lọ́nà kan ṣáá láti lo ìgbà òtútù, èbúté ọkọ̀ òkun kan ní Kírétè tí ó ṣí sílẹ̀ síhà àríwá ìlà-oòrùn àti síhà gúúsù ìlà-oòrùn. 13  Síwájú sí i, nígbà tí ẹ̀fúùfù gúúsù fẹ́ yẹ́ẹ́, wọ́n rò pé àwọn kúkú ti rí ìmúṣẹ ète wọn ni, wọ́n sì gbé ìdákọ̀ró sókè, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tukọ̀ lọ níhà èbúté lẹ́gbẹ̀ẹ́ Kírétè. 14  Àmọ́ ṣá o, lẹ́yìn tí kò pẹ́ púpọ̀, ẹ̀fúùfù oníjì líle+ tí a ń pè ní Yúrákúílò rọ́ lù ú. 15  Bí ó ti gba ọkọ̀ ojú omi náà lọ́nà lílenípá, tí kò sì lè da orí rẹ̀ kọ ẹ̀fúùfù náà, a juwọ́ sílẹ̀, a sì ń gbá wa lọ. 16  Wàyí o, a sáré lábẹ́ ààbò erékùṣù kékeré tí a ń pè ní Káúdà, síbẹ̀, èkukáká ni a fi lè ṣèkáwọ́ ọkọ̀ ìgbájá+ tí ó wà ní ìdí ọkọ̀. 17  Ṣùgbọ́n lẹ́yìn gbígbé e sókè sínú ọkọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn ìrànlọ́wọ́ láti mú ọkọ̀ ojú omi le gírígírí lábẹ́; níwọ̀n bí wọ́n sì ti bẹ̀rù rírọ́lu ilẹ̀ níbi tí òkun kò ti jìn ní Sítísì, wọ́n rọ ohun ìgbọ́kọ̀sáré sílẹ̀, a sì tipa báyìí ń gbá wọn lọ. 18  Síbẹ̀, nítorí tí ìjì líle náà ń bì wá síwá-sẹ́yìn lọ́nà lílenípá, ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí mú ọkọ̀ òkun náà fúyẹ́;+ 19  ní ọjọ́ kẹta, ọwọ́ ara wọn ni wọ́n sì fi sọ ohun èlò inú ọkọ̀ ojú omi nù. 20  Wàyí o, nígbà tí oòrùn tàbí àwọn ìràwọ̀ kò fara hàn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, tí ìjì líle+ tí ń bẹ lórí wa kì í sì í ṣe kékeré, gbogbo ìrètí fún gbígbà wá là ní ìkẹyìn wá bẹ̀rẹ̀ sí pòórá. 21  Nígbà tí ìtakété sí oúnjẹ sì ti wà fún ìgbà pípẹ́, nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù dìde dúró ní àárín wọn,+ ó sì wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú, ó yẹ kí ẹ ti gba àmọ̀ràn mi, kí ẹ má sì ti ṣíkọ̀ sójú òkun láti Kírétè, ẹ kì bá sì ti fara gba ìbàjẹ́ àti àdánù yìí.+ 22  Síbẹ̀, nísinsìnyí mo dá a lámọ̀ràn fún yín pé kí ẹ túra ká, nítorí kò sí ọkàn kan láàárín yín tí a ó pàdánù, kìkì ọkọ̀ ojú omi ni a ó pàdánù. 23  Nítorí ní òru yìí, áńgẹ́lì+ kan ti Ọlọ́run tí mo jẹ́ tirẹ̀, tí mo sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀+ fún dúró tì mí, 24  ó wí pé, ‘Má bẹ̀rù, Pọ́ọ̀lù. Ìwọ gbọ́dọ̀ dúró níwájú Késárì,+ sì wò ó! Ọlọ́run ti fi gbogbo àwọn tí ẹ jọ ń lọ lójú omi fún ọ lọ́fẹ̀ẹ́.’ 25  Nítorí náà, ẹ túra ká; nítorí mo gba Ọlọ́run gbọ́+ pé gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ fún mi ni yóò rí. 26  Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ gbá wa jù sí èbúté lórí erékùṣù kan.”+ 27  Wàyí o, bí ó ti di òru kẹrìnlá, tí a sì ń bì wá síwá-sẹ́yìn lórí òkun Ádíríà, ní ọ̀gànjọ́ òru, àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fura pé wọn ń sún mọ́ ilẹ̀ kan. 28  Wọ́n sì wọn jíjìn omi náà wò, wọ́n sì rí i pé ó jẹ́ ogún ìgbọ̀nká; nítorí náà, wọ́n tẹ̀ síwájú díẹ̀, wọ́n sì tún wọn omi náà, wọ́n sì rí i pé ó jẹ́ ìgbọ̀nká mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. 29  Àti pé nítorí bíbẹ̀rù pé a lè gbá wa jù sí ibì kan lórí àwọn àpáta, wọ́n ju ìdákọ̀ró mẹ́rin sínú omi láti ìdí ọkọ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dàníyàn pé kí ilẹ̀ mọ́. 30  Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti sá àsálà kúrò nínú ọkọ̀ ojú omi, tí wọ́n sì rọ ọkọ̀ ìgbájá sílẹ̀ sínú òkun lábẹ́ ìdíbọ́n pé ṣe ni àwọn ń pète-pèrò láti rọ àwọn ìdákọ̀ró sísàlẹ̀ láti iwájú ọkọ̀, 31  Pọ́ọ̀lù wí fún ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti àwọn ọmọ ogun pé: “Láìjẹ́ pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí dúró sínú ọkọ̀ ojú omi, a kò lè gbà yín là.”+ 32  Nígbà náà ni àwọn ọmọ ogun gé ìjàrá ọkọ̀ ìgbájá+ náà kúrò, wọ́n sì jẹ́ kí ó jábọ́. 33  Wàyí o, nígbà tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́, Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí fún gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ìṣírí láti jẹ oúnjẹ, ó wí pé: “Òní ni ó pé ọjọ́ kẹrìnlá tí ẹ ti ń ṣọ́nà, tí ẹ sì ń bá a lọ láìsí oúnjẹ, tí ẹ kò jẹ nǹkan kan sínú ara yín. 34  Nítorí náà, mo fún yín ní ìṣírí láti jẹ oúnjẹ, nítorí kí ó má bàa sí ewu fún yín; nítorí kò sí irun+ kan láti orí ọ̀kan nínú yín tí yóò ṣègbé.” 35  Lẹ́yìn tí ó sọ èyí, òun pẹ̀lú mú ìṣù búrẹ́dì kan, ó dúpẹ́+ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn, ó bù ú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹun. 36  Nítorí náà, gbogbo wọ́n tújú ká, àwọn alára sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ oúnjẹ. 37  Wàyí o, lápapọ̀, àwa ọkàn tí ó wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà jẹ́ igba ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́rin. 38  Nígbà tí wọ́n ti jẹ oúnjẹ yó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí mú ọkọ̀ ojú omi náà fúyẹ́+ nípa sísọ àlìkámà láti inú ọkọ̀ sínú òkun. 39  Ní ìkẹyìn, nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọn kò lè dá ilẹ̀ mọ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàkíyèsí ìyawọ̀ omi kan tí ó ní etíkun, wọ́n sì pinnu pé, bí ó bá ṣeé ṣe fún àwọn, lórí èyí ni àwọn yóò ti mú ọkọ̀ ojú omi náà gúnlẹ̀ sí etíkun.+ 40  Nítorí náà, ní gígé àwọn ìdákọ̀ró kúrò, wọ́n jẹ́ kí wọ́n jábọ́ sínú òkun, ní àkókò kan náà, wọ́n ń tú àwọn okùn tí a fi so àwọn àjẹ̀ ìtọ́kọ̀ àti pé, lẹ́yìn títa ìgbòkun iwájú ọkọ̀ sínú ẹ̀fúùfù, wọ́n dorí kọ etíkun náà. 41  Nígbà tí wọ́n dé orí àpápá kan tí òkun ń bì lù ní ìhà kọ̀ọ̀kan, wọ́n rọ́ lu ilẹ̀ níbi tí òkun kò ti jìn, iwájú ọkọ̀ sì fẹnu múlẹ̀, ó dúró láìṣeé ṣí nípò, ṣùgbọ́n ìdí ọkọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ sí wẹ́wẹ́ lọ́nà lílenípá.+ 42  Látàrí èyí, ó di ìpinnu àwọn ọmọ ogun láti pa àwọn ẹlẹ́wọ̀n, kí ẹnì kankan má bàa wẹ̀ lọ, kí ó sì sá àsálà. 43  Ṣùgbọ́n ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun fẹ́ láti gba Pọ́ọ̀lù là láìséwu, ó sì ṣèdíwọ́ fún wọn nínú ète wọn. Ó sì pàṣẹ fún àwọn tí wọ́n lè wẹ̀ láti bẹ́ sínú òkun, kí wọ́n sì kọ́kọ́ dé ilẹ̀, 44  kí àwọn yòókù sì ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn kan lórí pátákó àti àwọn kan lórí àwọn ohun kan láti ara ọkọ̀ ojú omi. Nípa báyìí, ó ṣẹlẹ̀ pé gbogbo wọn ni a mú wá sórí ilẹ̀ láìséwu.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé