Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 26:1-32

26  Ágírípà+ wí fún Pọ́ọ̀lù pé: “A gbà ọ́ láyè láti sọ̀rọ̀ nítorí ara rẹ.” Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù na ọwọ́ rẹ̀,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ní ìgbèjà ara rẹ̀+ pé:  “Nípa gbogbo ohun tí àwọn Júù fẹ̀sùn rẹ̀ kàn mí,+ Ọba Ágírípà, mo ka ara mi sí aláyọ̀ pé iwájú rẹ ni èmi yóò ti gbèjà ara mi lónìí yìí,  ní pàtàkì, níwọ̀n bí ìwọ ti jẹ́ ògbógi nínú gbogbo àṣà+ àti àríyànjiyàn láàárín àwọn Júù. Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́ láti fi sùúrù gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.  “Ní tòótọ́, ní ti ọ̀nà ìgbésí ayé+ láti ìgbà èwe wá, èyí tí mo gbé láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ láàárín orílẹ̀-èdè mi àti ní Jerúsálẹ́mù, gbogbo àwọn Júù,  tí wọ́n ti dojúlùmọ̀ mi ṣáájú láti ìbẹ̀rẹ̀ mọ̀, bí wọ́n bá fẹ́ jẹ́rìí, pé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀ya ìsìn aláìgbagbẹ̀rẹ́+ rárá ti ọ̀nà ìjọsìn wa ni mo fi gbé ìgbésí ayé Farisí.+  Síbẹ̀, nísinsìnyí nítorí ìrètí+ ìlérí+ tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn baba ńlá wa ni a fi pè mí dúró fún ìdájọ́;  nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ẹ̀yà méjìlá wa ń retí láti rí ìmúṣẹ ìlérí yìí gbà nípasẹ̀ fífi ìgbónájanjan ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un ní òru àti ní ọ̀sán.+ Nípa ìrètí yìí ni àwọn Júù fi fẹ̀sùn kan mí,+ ìwọ ọba.  “Èé ti rí tí a kà á sí ohun tí kò ṣeé gbà gbọ́ láàárín yín pé Ọlọ́run ń gbé àwọn òkú dìde?+  Èmi, gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, ní ti gidi rò nínú ara mi pé ó yẹ kí n gbé ọ̀pọ̀ ìgbésẹ̀ àtakò lòdì sí orúkọ Jésù ará Násárétì; 10  èyí tí mo ṣe ní Jerúsálẹ́mù ní ti tòótọ́, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni mímọ́ ni mo sì tì mọ́ inú ẹ̀wọ̀n,+ níwọ̀n bí mo ti gba ọlá àṣẹ lọ́wọ́ àwọn olórí àlùfáà;+ nígbà tí wọ́n sì fẹ́ fi ikú pa wọ́n, mo di ìbò mi lòdì sí wọn. 11  Àti pé nípa jíjẹ wọ́n níyà ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní gbogbo sínágọ́gù,+ mo gbìyànjú láti fi ipá mú wọn láti kó ọ̀rọ̀ wọn jẹ; níwọ̀n bí orí mi sì ti gbóná sí wọn dé góńgó, mo lọ jìnnà dé ṣíṣe inúnibíni sí wọn, kódà ní àwọn ìlú ńlá tí ń bẹ lẹ́yìn òde. 12  “Láàárín ìsapá wọ̀nyí, bí mo ṣe ń rin ìrìn àjò lọ sí Damásíkù+ pẹ̀lú ọlá àṣẹ àti ìwé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, 13  ní ọjọ́kanrí lójú ọ̀nà, ìwọ ọba, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan tí ó ré kọjá ìdányanran oòrùn, tí ó kọ mànà láti ọ̀run yí mi ká àti yí ká àwọn tí ń rin ìrìn àjò pẹ̀lú mi.+ 14  Nígbà tí gbogbo wa sì ti ṣubú lulẹ̀ tán, mo gbọ́ ohùn kan tí ó sọ fún mi ní èdè Hébérù pé, ‘Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Láti máa bá a nìṣó ní títàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́ mú kí ó nira fún ọ.’+ 15  Ṣùgbọ́n mo wí pé, ‘Ta ni ọ́, Olúwa?’ Olúwa sì wí pé, ‘Èmi ni Jésù, ẹni tí ìwọ ń ṣe inúnibíni+ sí. 16  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ.+ Nítorí fún ète yìí ni mo ṣe mú kí o rí mi, kí èmi lè yàn ọ́ ṣe ẹmẹ̀wà àti ẹlẹ́rìí+ àwọn ohun tí ìwọ ti rí àti àwọn ohun tí èmi yóò mú kí o rí nípa mi; 17  nígbà tí èmi yóò dá ọ nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn yìí àti kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, tí èmi ń rán ọ sí,+ 18  láti la ojú wọn,+ láti yí wọn padà láti inú òkùnkùn+ sí ìmọ́lẹ̀+ àti láti inú ọlá àṣẹ Sátánì+ sí Ọlọ́run, kí wọ́n lè rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀+ gbà àti ogún+ láàárín àwọn tí a sọ di mímọ́+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn nínú mi.’ 19  “Nípa bẹ́ẹ̀, Ọba Ágírípà, èmi kò di aláìgbọràn sí ìran ti ọ̀run náà,+ 20  ṣùgbọ́n mo ń mú ìhìn-iṣẹ́ náà wá fún àwọn tí ń bẹ ní Damásíkù+ lákọ̀ọ́kọ́ àti àwọn tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù,+ àti fún gbogbo ilẹ̀ Jùdíà, àti fún àwọn orílẹ̀-èdè+ pé kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yí padà sí Ọlọ́run nípa ṣíṣe àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà.+ 21  Ní tìtorí nǹkan wọ̀nyí ni àwọn Júù fi gbá mi mú nínú tẹ́ńpìlì, tí wọ́n sì gbìdánwò láti pa mí.+ 22  Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí pé mo ti rí ìrànlọ́wọ́+ tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run gbà, mo ń bá a lọ títí di òní yìí ní jíjẹ́rìí fún àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá, ṣùgbọ́n èmi kò sọ nǹkan kan àyàfi àwọn ohun tí àwọn Wòlíì+ àti Mósè+ sọ pé yóò ṣẹlẹ̀, 23  pé Kristi yóò jìyà+ àti pé, gẹ́gẹ́ bí ẹni àkọ́kọ́ tí a óò jí dìde+ kúrò nínú òkú, òun yóò kéde ìmọ́lẹ̀+ fún àwọn ènìyàn yìí àti àwọn orílẹ̀-èdè.”+ 24  Wàyí o, bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí ní ìgbèjà ara rẹ̀, Fẹ́sítọ́ọ̀sì wí ní ohùn rara pé: “Orí rẹ ti ń dà rú,+ Pọ́ọ̀lù! Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ti ń dà ọ́ lórí rú!” 25  Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù wí pé: “Kì í ṣe pé orí mi ti ń dà rú, Fẹ́sítọ́ọ̀sì Ẹni Títayọ Lọ́lá, ṣùgbọ́n àwọn àsọjáde tí ó jẹ́ òtítọ́ àti ti ìyèkooro èrò inú ni mo ń sọ jáde. 26  Ní ti gidi, ọba tí mo ń bá sọ̀rọ̀ pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ mọ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí dáadáa; nítorí mo gbà pé kò sí ọ̀kan lára nǹkan wọ̀nyí tí ó bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí rẹ̀, nítorí a kò ṣe ohun yìí ní kọ́lọ́fín.+ 27  Ọba Ágírípà, ìwọ ha gba àwọn Wòlíì gbọ́ bí? Mo mọ̀ pé o gbà gbọ́.”+ 28  Ṣùgbọ́n Ágírípà wí fún Pọ́ọ̀lù pé: “Ní àkókò kúkúrú, ìwọ yóò yí mi lérò padà di Kristẹni.” 29  Látàrí èyí, Pọ́ọ̀lù wí pé: “Ẹ̀bẹ̀ mi sọ́dọ̀ Ọlọ́run ni pé yálà ní àkókò kúkúrú tàbí ní àkókò gígùn, kì í ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú yóò di irú ènìyàn tí èmi náà jẹ́, láìsí ìdè wọ̀nyí.” 30  Ọba sì dìde, bẹ́ẹ̀ sì ni gómìnà àti Bẹ̀níísì àti àwọn ènìyàn tí wọ́n jókòó pẹ̀lú wọn. 31  Ṣùgbọ́n bí wọ́n ti ń fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì, pé: “Ọkùnrin yìí kò ṣe nǹkan kan tí ó yẹ fún ikú+ tàbí àwọn ìdè.” 32  Síwájú sí i, Ágírípà wí fún Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé: “À bá ti tú ọkùnrin yìí sílẹ̀ ká ní kò ké gbàjarè+ sí Késárì.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé