Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣe 25:1-27

25  Nítorí náà, lẹ́yìn dídé orí+ ipò ìjọba àgbègbè ìpínlẹ̀ náà, Fẹ́sítọ́ọ̀sì gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù láti Kesaréà+ ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà;  àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn sàràkí-sàràkí lára àwọn Júù fún un ní ìsọfúnni+ lòdì sí Pọ́ọ̀lù. Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pàrọwà fún un,  wọ́n ń béèrè ojú rere fún ara wọn ní ìlòdìsí ọkùnrin náà, pé kí ó ránṣẹ́ pè é wá sí Jerúsálẹ́mù, bí wọ́n ti ba ní ibùba+ láti pa á lójú ọ̀nà.  Bí ó ti wù kí ó rí, Fẹ́sítọ́ọ̀sì dáhùn pé Pọ́ọ̀lù ni a ó pa mọ́ ní Kesaréà àti pé òun fúnra òun máa tó gbéra lọ síbẹ̀ láìpẹ́ láìjìnnà.  Ó wí pé: “Nítorí bẹ́ẹ̀, kí àwọn tí wọ́n wà ní ipò agbára láàárín yín sọ̀ kalẹ̀ wá pẹ̀lú mi, kí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn án,+ bí ohunkóhun tí kò tọ̀nà bá wà nípa ọkùnrin náà.”  Nítorí náà, nígbà tí ó ti lo èyí tí kò ju ọjọ́ mẹ́jọ tàbí mẹ́wàá láàárín wọn, ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Kesaréà, ó sì jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́+ ní ọjọ́ kejì, ó sì pàṣẹ pé kí a mú Pọ́ọ̀lù wọlé wá.  Nígbà tí ó dé, àwọn Júù tí wọ́n ti sọ̀ kalẹ̀ wá láti Jerúsálẹ́mù dúró yí i ká, wọ́n ń fi ẹ̀sùn+ púpọ̀, tí ó sì wúwo rinlẹ̀ kàn án, èyí tí wọn kò lè fi ẹ̀rí rẹ̀ hàn.  Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù sọ ní ìgbèjà pé: “Èmi kò dá ẹ̀ṣẹ̀+ kankan sí Òfin àwọn Júù tàbí sí tẹ́ńpìlì+ tàbí sí Késárì.”  Fẹ́sítọ́ọ̀sì, tí ó fẹ́ láti jèrè ojú rere+ lọ́dọ̀ àwọn Júù, sọ ní ìfèsìpadà fún Pọ́ọ̀lù pé: “Ìwọ ha fẹ́ láti gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí a sì ṣèdájọ́ rẹ níbẹ̀ níwájú mi nípa nǹkan wọ̀nyí?”+ 10  Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù wí pé: “Mo dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Késárì,+ níbi tí ó yẹ kí a ti ṣèdájọ́ mi. Èmi kò ṣe àìtọ́ kankan sí àwọn Júù,+ gẹ́gẹ́ bí ìwọ pẹ̀lú ti ń rídìí òtítọ́ rẹ̀ dáadáa. 11  Ní ọwọ́ kan, bí mo bá jẹ́ oníwà àìtọ́+ ní ti tòótọ́, tí mo sì ti ṣe ohunkóhun tí ó yẹ fún ikú,+ èmi kò tọrọ gáfárà láti má ṣe kú; ní ọwọ́ kejì, bí ìkankan lára ohun wọnnì tí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń fẹ̀sùn rẹ̀ kàn mí kò bá sí, ènìyàn kankan kò lè fi mí lé wọn lọ́wọ́ láti fi wá ojú rere. Mo ké gbàjarè sí Késárì!”+ 12  Nígbà náà, lẹ́yìn bíbá àjọ àwọn agbani-nímọ̀ràn sọ̀rọ̀, Fẹ́sítọ́ọ̀sì fèsì pé: “Késárì ni ìwọ ké gbàjarè sí; ọ̀dọ̀ Késárì ni ìwọ yóò lọ.” 13  Wàyí o, nígbà tí ọjọ́ mélòó kan ti kọjá, Ágírípà Ọba àti Bẹ̀níísì dé sí Kesaréà fún ìbẹ̀wò àyẹ́sí sọ́dọ̀ Fẹ́sítọ́ọ̀sì. 14  Nítorí náà, bí wọ́n ti ń lo ọjọ́ púpọ̀ díẹ̀ níbẹ̀, Fẹ́sítọ́ọ̀sì gbé àwọn ọ̀ràn nípa Pọ́ọ̀lù kalẹ̀ níwájú ọba, wí pé: “Ọkùnrin kan wà tí Fẹ́líìsì fi sílẹ̀ ní ẹlẹ́wọ̀n, 15  nígbà tí mo sì wà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin Júù mú ìsọfúnni+ wá nípa rẹ̀, wọ́n ń béèrè ìdájọ́ ìdálẹ́bi lòdì sí i. 16  Ṣùgbọ́n mo fèsì fún wọn pé kì í ṣe ọ̀nà-ìgbàṣe-nǹkan àwọn ara Róòmù láti fi ènìyàn èyíkéyìí léni lọ́wọ́ láti fi wá ojú rere kí ẹni tí a fẹ̀sùn kàn tó fojú-kojú pẹ̀lú àwọn olùfisùn rẹ̀,+ kí ó sì rí àyè sọ̀rọ̀ ní ìgbèjà ara rẹ̀ nípa ẹ̀sùn náà. 17  Nítorí náà, nígbà tí wọ́n kóra jọ níhìn-ín, èmi kò jáfara rárá, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì mo jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́ mo sì pàṣẹ pé kí a mú ọkùnrin náà wọlé wá. 18  Ní bíbọ́ sórí àpótí ìdúrórojọ́, àwọn olùfisùn náà kò mú ẹ̀sùn+ kankan wá nípa àwọn ohun burúkú tí mo ti rò nípa rẹ̀. 19  Àwọn awuyewuye kan ni wọ́n kàn ní pẹ̀lú rẹ̀ nípa ìjọsìn+ tiwọn fún ọlọ́run àjúbàfún àti nípa Jésù kan tí ó kú ṣùgbọ́n tí Pọ́ọ̀lù ń tẹnu mọ́ ọn ṣáá pé ó wà láàyè.+ 20  Nítorí náà, bí awuyewuye nípa ọ̀ràn wọ̀nyí ti dà mí lọ́kàn rú, mo tẹ̀ síwájú láti béèrè bí òun yóò bá fẹ́ láti lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí a sì ṣèdájọ́ rẹ̀ níbẹ̀ nípa ọ̀ràn wọ̀nyí.+ 21  Ṣùgbọ́n nígbà tí Pọ́ọ̀lù ké gbàjarè+ pé kí a pa òun mọ́ fún ìpinnu láti ọwọ́ Ẹni Ọlọ́lá náà, mo pàṣẹ pé kí a pa á mọ́ títí èmi yóò fi fi í ránṣẹ́ gòkè lọ sọ́dọ̀ Késárì.” 22  Lórí kókó yìí, Ágírípà wí fún Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé: “Èmi alára yóò fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọkùnrin náà.”+ “Ọ̀la ni ìwọ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀,” ni ó wí. 23  Nítorí náà, ní ọjọ́ kejì, Ágírípà àti Bẹ̀níísì dé pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àṣehàn aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀,+ wọ́n sì wọnú gbọ̀ngàn àwùjọ lọ, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀gágun àti àwọn ọkùnrin jàǹkàn-jàǹkàn ní ìlú ńlá náà, nígbà tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì sì paṣẹ, a mú Pọ́ọ̀lù wọlé wá. 24  Fẹ́sítọ́ọ̀sì sì wí pé: “Ọba Ágírípà àti gbogbo ẹ̀yin ọkùnrin tí ẹ wà níhìn-ín pẹ̀lú wa, ẹ ń wo ọkùnrin yìí nípa ẹni tí gbogbo ògìdìgbó àwọn Júù lápapọ̀ ti mú ọ̀ràn rẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi ní Jerúsálẹ́mù àti níhìn-ín, tí wọ́n ń kígbe pé kò yẹ láti wà láàyè mọ́.+ 25  Ṣùgbọ́n mo róye pé kò ṣe nǹkan kan tí ó yẹ fún ikú.+ Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin yìí fúnra rẹ̀ ké gbàjarè+ sí Ẹni Ọlọ́lá náà, mo pinnu láti fi í ránṣẹ́. 26  Ṣùgbọ́n nípa rẹ̀ èmi kò ní ohunkóhun pàtó láti kọ sí Olúwa mi. Nítorí náà, mo mú un wá síwájú yín, àti ní pàtàkì síwájú rẹ, Ọba Ágírípà, kí èmi lè rí nǹkan kọ, lẹ́yìn tí àyẹ̀wò ìdájọ́ bá ti ṣẹlẹ̀.+ 27  Nítorí pé lójú tèmi, ó dà bí ẹni pé kò lọ́gbọ́n nínú láti fi ẹlẹ́wọ̀n kan ránṣẹ́, kí n má sì tọ́ka sí àwọn ẹ̀sùn lòdì sí i.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé