Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣe 24:1-27

24  Ọjọ́ márùn-ún lẹ́yìn náà, àlùfáà àgbà náà, Ananíà+ sọ̀ kalẹ̀ wá pẹ̀lú àwọn àgbà ọkùnrin mélòó kan àti olùbánisọ̀rọ̀ ní gbangba, Tẹ́túlọ́sì kan báyìí, wọ́n sì fún gómìnà+ ní ìsọfúnni+ lòdì sí Pọ́ọ̀lù.  Nígbà tí a pè é, Tẹ́túlọ́sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹ̀sùn kàn án, pé: “Ní rírí i pé àwa ń gbádùn àlàáfíà+ púpọ̀ nípasẹ̀ rẹ àti pé àwọn àtúnṣe ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè yìí nípasẹ̀ ìròtẹ́lẹ̀ rẹ,  ìgbà gbogbo àti ibi gbogbo pẹ̀lú ni a ń fi ọpẹ́ ńláǹlà gbà á, Fẹ́líìsì Ẹni Títayọ Lọ́lá.+  Ṣùgbọ́n kí èmi má bàa dí ọ lọ́wọ́ síwájú sí i, mo fi taratara bẹ̀ ọ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wa ní ṣókí nínú ẹ̀mí inú rere rẹ.  Nítorí a ti rí ọkùnrin yìí gẹ́gẹ́ bí alákòóbá,+ tí ó sì ń ru ìdìtẹ̀ sí ìjọba+ sókè láàárín gbogbo àwọn Júù jákèjádò ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, òun sì ni òléwájú nínú ẹ̀ya ìsìn àwọn ará Násárétì,+  ẹnì tí ó tún gbìyànjú láti sọ tẹ́ńpìlì+ di aláìmọ́, tí a sì gbá mú.  ——  Ìwọ fúnra rẹ lè fi àyẹ̀wò rídìí òtítọ́ láti ẹnu rẹ̀ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ń fẹ̀sùn rẹ̀ kàn án.”  Pẹ̀lú èyíinì, àwọn Júù pẹ̀lú dara pọ̀ nínú ìgbéjàkò náà, wọ́n ń tẹnu mọ́ ọn pé bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí. 10  Nígbà tí gómìnà mi orí sí Pọ́ọ̀lù pé kí ó sọ̀rọ̀, ó dáhùn pé: “Ní mímọ̀ dunjú pé orílẹ̀-èdè yìí ti ní ọ gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, pẹ̀lú ìmúratán ni mo fi ń sọ àwọn nǹkan nípa ara mi ní ìgbèjà+ ara mi, 11  níwọ̀n bí ìwọ ti wà ní ipò láti rídìí òtítọ́ pé ní tèmi, kò tíì ju ọjọ́ méjìlá lọ tí mo gòkè lọ láti jọ́sìn+ ní Jerúsálẹ́mù; 12  wọn kò sì rí mi nínú tẹ́ńpìlì+ kí n máa bá ẹnikẹ́ni jiyàn tàbí mú kí àwùjọ onírúgúdù+ rọ́jọ gììrì, yálà nínú àwọn sínágọ́gù tàbí jákèjádò ìlú ńlá náà. 13  Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè fún ọ ní ẹ̀rí ìdánilójú+ nípa àwọn ohun tí wọ́n ń fẹ̀sùn rẹ̀ kàn mí nísinsìnyí gan-an. 14  Ṣùgbọ́n mo jẹ́wọ́ èyí fún ọ, pé, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní ‘ẹ̀ya ìsìn,’ ní ọ̀nà yìí ni mo gbà ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run àwọn baba ńlá mi,+ níwọ̀n bí mo ti gba gbogbo ohun tí a là sílẹ̀ nínú Òfin+ gbọ́, tí a sì kọ̀wé rẹ̀ nínú àwọn Wòlíì; 15  mo sì ní ìrètí+ sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ìrètí tí ọkùnrin wọ̀nyí pẹ̀lú ní, pé àjíǹde+ àwọn olódodo+ àti àwọn aláìṣòdodo+ yóò wà. 16  Ní ti èyí, ní tòótọ́, mo ń lo ara mi nígbà gbogbo láti ní ìmọ̀lára+ àìṣe ohun ìmúnibínú kankan sí Ọlọ́run àti ènìyàn. 17  Nítorí náà, lẹ́yìn iye ọdún púpọ̀ díẹ̀, mo dé láti mú àwọn ẹ̀bùn àánú wá fún orílẹ̀-èdè mi, àti àwọn ọrẹ ẹbọ.+ 18  Bí mo ti wà lẹ́nu nǹkan wọ̀nyí, wọ́n rí mi nínú tẹ́ńpìlì+ ní ẹni tí a wẹ̀ mọ́ lọ́nà ayẹyẹ, ṣùgbọ́n kì í ṣe pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ tàbí pẹ̀lú ìrúkèrúdò. Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan ń bẹ, láti àgbègbè Éṣíà, 19  tí ó yẹ kí wọ́n wà níhìn-ín níwájú rẹ, kí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn mí, bí wọ́n bá ní ohunkóhun lòdì sí mi.+ 20  Tàbí kẹ̀, kí àwọn ọkùnrin tí ń bẹ níhìn-ín yìí fúnra wọn sọ ohun àìtọ́ tí wọ́n rí bí mo ti dúró síwájú Sànhẹ́dírìn, 21  àyàfi ní ti àsọjáde kan ṣoṣo yìí tí mo ké jáde nígbà tí mo dúró láàárín wọn, ‘Lórí àjíǹde àwọn òkú ni a ṣe ń dá mi lẹ́jọ́ lónìí níwájú yín!’”+ 22  Bí ó ti wù kí ó rí, ní mímọ̀ ọ̀ràn nípa Ọ̀nà+ yìí lọ́nà pípéye, Fẹ́líìsì+ bẹ̀rẹ̀ sí dá ìgbà mìíràn fún àwọn ọkùnrin náà, ó sì wí pé: “Nígbàkigbà tí Lísíà+ ọ̀gágun bá sọ̀ kalẹ̀ wá, èmi yóò pinnu lórí ọ̀ràn wọ̀nyí tí ó kàn yín.” 23  Ó sì pàṣẹ fún ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun pé kí a pa ọkùnrin náà mọ́, kí ó ní ìdẹ̀ra díẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìhámọ́, kí ó má sì kà á léèwọ̀ fún ẹnì kankan lára àwọn ènìyàn rẹ̀ láti ṣèránṣẹ́ fún un.+ 24  Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, Fẹ́líìsì+ dé pẹ̀lú Dùrùsílà aya rẹ̀, tí ó jẹ́ obìnrin Júù,+ ó sì ránṣẹ́ pe Pọ́ọ̀lù, ó sì fetí sí i lórí èrò ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù.+ 25  Ṣùgbọ́n bí ó ti sọ̀rọ̀ nípa òdodo+ àti ìkóra-ẹni-níjàánu+ àti ìdájọ́+ tí ń bọ̀, jìnnìjìnnì bo Fẹ́líìsì, ó sì dáhùn pé: “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ ní ìsinsìnyí ná, ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá ní àkókò tí ó rọgbọ, èmi yóò tún ránṣẹ́ pè ọ́.” 26  Ṣùgbọ́n, ní àkókò kan náà, ó ń retí pé kí Pọ́ọ̀lù fún òun ní owó.+ Ní tìtorí ìyẹn, ó tilẹ̀ ránṣẹ́ pè é lemọ́lemọ́, a sì bá a sọ̀rọ̀ pọ̀.+ 27  Ṣùgbọ́n, nígbà tí ọdún méjì ti kọjá lọ, Pọ́kíọ́sì Fẹ́sítọ́ọ̀sì rọ́pò Fẹ́líìsì; nítorí pé Fẹ́líìsì fẹ́ láti jèrè ojú rere+ lọ́dọ̀ àwọn Júù, ó fi Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ ní dídè.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé