Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 23:1-35

23  Ní títẹjúmọ́ Sànhẹ́dírìn, Pọ́ọ̀lù wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, mo ti hùwà níwájú Ọlọ́run pẹ̀lú ẹ̀rí-ọkàn+ mímọ́ kedere lọ́nà pípé títí di òní.”  Látàrí èyí, àlùfáà àgbà náà Ananíà, pàṣẹ fún àwọn tí wọ́n dúró nítòsí pé kí wọ́n gbá+ a lẹ́nu.  Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù wí fún un pé: “Ọlọ́run yóò gbá ọ, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun.+ Ìwọ ha jókòó láti ṣèdájọ́ mi ní ìbámu pẹ̀lú Òfin,+ ní àkókò kan náà, ní ríré Òfin+ kọjá, ìwọ sì pàṣẹ pé kí a gbá mi?”  Àwọn tí wọ́n dúró nítòsí wí pé: “Ṣé ìwọ ń kẹ́gàn àlùfáà àgbà Ọlọ́run ni?”  Pọ́ọ̀lù sì wí pé: “Ẹ̀yin ará, èmi kò mọ̀ pé àlùfáà àgbà ni. Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ olùṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ lọ́nà ìbàjẹ́.’”+  Wàyí o, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ṣàkíyèsí pé apá kan jẹ́ ti àwọn Sadusí,+ ṣùgbọ́n èkejì jẹ́ ti àwọn Farisí, ó bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde ní Sànhẹ́dírìn pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, Farisí ni mí,+ ọmọ àwọn Farisí. Lórí ìrètí àjíǹde+ àwọn òkú ni a ṣe ń dá mi lẹ́jọ́.”+  Nítorí tí ó sọ èyí, ìyapa+ dìde láàárín àwọn Farisí àti àwọn Sadusí, ògìdìgbó náà sì pínyà sí méjì.  Nítorí àwọn Sadusí+ wí pé kò sí àjíǹde+ tàbí áńgẹ́lì tàbí ẹ̀mí, ṣùgbọ́n àwọn Farisí polongo gbogbo ìwọ̀nyí ní gbangba.  Nítorí náà, ìlọgun tòò bẹ́ sílẹ̀,+ àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n jẹ́ ti àjọ ẹgbẹ́ àwọn Farisí dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàríyànjiyàn kíkankíkan, pé: “Àwa kò rí ohun àìtọ́ kankan nínú ọkùnrin yìí;+ ṣùgbọ́n bí ẹ̀mí kan tàbí áńgẹ́lì kan bá bá a sọ̀rọ̀,+—.” 10  Wàyí o, nígbà tí ìyapa náà di ńlá, ọ̀gágun fòyà pé wọn yóò fa Pọ́ọ̀lù já sí wẹ́wẹ́, ó pàṣẹ pé kí agbo àwọn ọmọ ogun+ sọ̀ kalẹ̀ lọ, kí wọ́n já a gbà kúrò láàárín wọn, kí wọ́n sì mú un wá sí ibùdó àwọn ọmọ ogun.+ 11  Ṣùgbọ́n ní òru tí ó tẹ̀ lé e, Olúwa dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ ó sì wí pé: “Jẹ́ onígboyà gidi gan-an!+ Nítorí pé bí o ti ń jẹ́rìí+ kúnnákúnná nípa àwọn nǹkan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú mi ní Jerúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ tún gbọ́dọ̀ jẹ́rìí ní Róòmù.”+ 12  Wàyí o, nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Júù di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun,+ wọ́n sì fi ègún de ara wọn,+ pé àwọn kò ní jẹ tàbí mu títí àwọn yóò fi pa Pọ́ọ̀lù.+ 13  Ó ju ogójì ọkùnrin tí ó di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun àfìbúradè yìí; 14  wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí+ àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin, wọ́n sì wí pé: “Àwa ti fi ègún de ara wa lọ́nà tí ó wúwo rinlẹ̀ láti má fẹnu ba oúnjẹ títí a ó fi pa Pọ́ọ̀lù. 15  Nítorí náà, nísinsìnyí, ẹ̀yin, pa pọ̀ pẹ̀lú Sànhẹ́dírìn, ẹ mú un ṣe kedere sí ọ̀gágun ìdí tí òun fi ní láti mú un sọ̀ kalẹ̀ wá sọ́dọ̀ yín bí ẹni pé ẹ pète-pèrò láti pinnu lọ́nà tí ó túbọ̀ péye àwọn ọ̀ràn tí ó kàn án.+ Ṣùgbọ́n kí ó tó sún mọ́ tòsí, ṣe ni àwa yóò ti wà ní sẹpẹ́ láti pa á.”+ 16  Bí ó ti wù kí ó rí, ọmọkùnrin arábìnrin Pọ́ọ̀lù gbọ́ nípa ìlúgọdeni+ wọn, ó sì wá, ó wọ ibùdó àwọn ọmọ ogun, ó sì ròyìn rẹ̀ fún Pọ́ọ̀lù. 17  Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù pe ọ̀kan lára àwọn ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun sọ́dọ̀, ó sì wí pé: “Mú ọ̀dọ́kùnrin yìí lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, nítorí ó ní ohun kan láti ròyìn fún un.” 18  Nítorí náà, ọkùnrin yìí mú un, ó sì ṣamọ̀nà rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, ó sì wí pé: “Pọ́ọ̀lù tí í ṣe ẹlẹ́wọ̀n pè mí sọ́dọ̀, ó sì béèrè pé kí n mú ọ̀dọ́kùnrin yìí wá sọ́dọ̀ rẹ, níwọ̀n bí òun ti ní ohun kan láti sọ fún ọ.” 19  Ọ̀gágun fà á lọ́wọ́,+ ó sì fi ibẹ̀ sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí níkọ̀kọ̀ pé: “Kí ni ìwọ ní láti ròyìn fún mi?” 20  Ó wí pé: “Àwọn Júù ti fohùn ṣọ̀kan láti béèrè lọ́wọ́ rẹ pé kí o mú Pọ́ọ̀lù sọ̀ kalẹ̀ wá sí Sànhẹ́dírìn ní ọ̀la bí ẹni pé wọ́n pète-pèrò láti mọ ohun kan lọ́nà tí ó túbọ̀ péye nípa rẹ̀.+ 21  Lékè ohun gbogbo, má ṣe jẹ́ kí wọ́n yí ọ lérò padà, nítorí pé ó ju ogójì ọkùnrin lára wọn tí ń lúgọ+ dè é, wọ́n sì ti fi ègún de ara wọn láti má ṣe jẹ tàbí mu títí wọn yóò fi pa á;+ wọ́n sì ti múra tán nísinsìnyí, wọ́n ń dúró de ìlérí láti ọ̀dọ̀ rẹ.” 22  Nítorí náà, ọ̀gágun jẹ́ kí ọ̀dọ́kùnrin náà lọ lẹ́yìn pípa àṣẹ ìtọ́ni fún un pé: “Má ṣẹnu fóró sọ fún ẹnikẹ́ni pé o ti mú nǹkan wọ̀nyí ṣe kedere sí mi.” 23  Ó sì fi ọlá àṣẹ pe àwọn méjì kan lára ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ó sì wí pé: “Ẹ múra igba ọmọ ogun sílẹ̀ láti lọ títí dé Kesaréà, pẹ̀lúpẹ̀lù àádọ́rin àwọn ẹlẹ́ṣin àti igba àwọn afọ̀kọ̀jà, ní wákàtí kẹta òru. 24  Pẹ̀lúpẹ̀lù, pèsè àwọn ẹranko arẹrù fún Pọ́ọ̀lù láti gùn, kí ẹ sì gbé e dé ọ̀dọ̀ gómìnà Fẹ́líìsì láìséwu.” 25  Ó sì kọ lẹ́tà kan tí ó lọ báyìí: 26  “Kíláúdíù Lísíà sí ẹni títayọ lọ́lá, Gómìnà Fẹ́líìsì:+ Mo kí ọ! 27  Ọkùnrin yìí ni àwọn Júù gbá mú, tí wọ́n sì fẹ́ pa, ṣùgbọ́n mo dé lójijì pẹ̀lú agbo àwọn ọmọ ogun, mo sì gbà á sílẹ̀,+ nítorí mo gbọ́ pé ará Róòmù ni.+ 28  Bí mo sì ti ń fẹ́ láti mọ ìdí tí wọ́n fi ń fẹ̀sùn kàn án dájú, mo mú un sọ̀ kalẹ̀ wá sí Sànhẹ́dírìn wọn.+ 29  Mo rí i pé wọ́n fẹ̀sùn kàn án lórí àwọn ọ̀ràn Òfin wọn,+ ṣùgbọ́n wọn kò fi í sùn fún ẹyọ ohun kan tí ó yẹ fún ikú tàbí àwọn ìdè.+ 30  Ṣùgbọ́n nítorí pé a ti sọ ìdìmọ̀lù+ tí wọ́n fẹ́ ṣe sí ọkùnrin yìí di mímọ̀ fún mi, mo ń fi í ránṣẹ́ sí ọ ní kíákíá, mo sì pàṣẹ fún àwọn olùfisùn rẹ̀ láti sọ̀rọ̀ lòdì sí i níwájú rẹ.”+ 31  Nítorí náà, ọmọ ogun+ wọ̀nyí mú Pọ́ọ̀lù ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ìtọ́ni tí a fún wọn, wọ́n sì mú un wá sí Antipátírísì ní òru. 32  Ní ọjọ́ kejì, wọ́n gba àwọn ẹlẹ́ṣin náà láyè láti bá a lọ, àwọn sì padà sí ibùdó àwọn ọmọ ogun. 33  Àwọn ẹlẹ́ṣin náà wọ Kesaréà,+ wọ́n sì fi lẹ́tà náà jíṣẹ́ fún gómìnà, wọ́n mú Pọ́ọ̀lù wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 34  Nítorí náà, ó kà á, ó ṣe ìwádìí àgbègbè ìpínlẹ̀ tí ó ti wá, ó sì rí i dájú+ pé Sìlíṣíà+ ni ó ti wá. 35  Ó wí pé: “Èmi yóò gbọ́ ẹjọ́ rẹ látòkèdélẹ̀ nígbà tí àwọn olùfisùn rẹ bá dé pẹ̀lú.”+ Ó sì pàṣẹ pé kí a fi í sábẹ́ ìṣọ́ ní ààfin Hẹ́rọ́dù tí í ṣe ibùgbé ọba.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé