Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣe 22:1-30

22  “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará+ àti ẹ̀yin baba, ẹ gbọ́ ìgbèjà+ mi sí yín nísinsìnyí.”  (Tóò, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù,+ wọ́n wá túbọ̀ dákẹ́, ó sì wí pé:)  “Júù ni mí,+ tí a bí ní Tásù ti Sìlíṣíà,+ ṣùgbọ́n tí a fún ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ní ìlú ńlá yìí lẹ́bàá ẹsẹ̀ Gàmálíẹ́lì,+ tí a fún ní ìtọ́ni ní ìbámu pẹ̀lú àìgbagbẹ̀rẹ́+ Òfin àwọn baba ńlá ìgbàanì, tí mo jẹ́ onítara+ fún Ọlọ́run, gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti jẹ́ lónìí yìí.  Mo sì ṣe inúnibíni sí Ọ̀nà yìí títí dé ikú,+ ní dídè àti fífi tọkùnrin tobìnrin sínú ẹ̀wọ̀n,+  gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà àti gbogbo àjọ àgbààgbà ọkùnrin+ ti lè jẹ́ mi lẹ́rìí. Ọ̀dọ̀ wọn pẹ̀lú ni mo ti gba àwọn lẹ́tà+ lọ sọ́dọ̀ àwọn ará ní Damásíkù, mo sì wà lójú ọ̀nà mi láti mú àwọn tí ó wà níbẹ̀ pẹ̀lú wá sí Jerúsálẹ́mù ní dídè láti jẹ wọ́n níyà.  “Ṣùgbọ́n bí mo ti ń rin ìrìn àjò lọ, tí mo sì ń sún mọ́ Damásíkù, ní nǹkan bí ọjọ́kanrí, lójijì, ìmọ́lẹ̀ ńlá kan láti ọ̀run kọ mànà ní gbogbo àyíká mi,+  mo sì ṣubú lulẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan tí ó wí fún mi pé, ‘Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?’+  Mo dáhùn pé, ‘Ta ni ọ́, Olúwa?’ Ó sì wí fún mi pé, ‘Èmi ni Jésù ará Násárétì, ẹni tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí.’+  Wàyí o, àwọn ènìyàn tí wọ́n wà pẹ̀lú mi+ rí ìmọ́lẹ̀ náà ní tòótọ́, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ohùn ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀.+ 10  Látàrí èyíinì, mo wí pé, ‘Kí ni kí n ṣe,+ Olúwa?’ Olúwa wí fún mi pé, ‘Dìde, bá ọ̀nà rẹ lọ sí Damásíkù, ibẹ̀ sì ni wọn yóò ti sọ fún ọ nípa ohun gbogbo tí a ti yàn kalẹ̀ fún ọ láti ṣe.’+ 11  Ṣùgbọ́n bí èmi kò ti lè rí ohunkóhun nítorí ògo ìmọ́lẹ̀ yẹn, mo dé Damásíkù, bí àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú mi ti fà mí lọ́wọ́ lọ.+ 12  “Wàyí o, Ananíà, ọkùnrin kan tí ó ní ìfọkànsìn ní ìbámu pẹ̀lú Òfin, tí gbogbo àwọn Júù tí ń gbé ibẹ̀ ròyìn rẹ̀ dáadáa,+ 13  wá sọ́dọ̀ mi, bí ó sì ti dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó wí fún mi pé, ‘Sọ́ọ̀lù, arákùnrin, tún ríran!’+ Mo sì gbójú sókè wò ó ní wákàtí yẹn gan-an. 14  Ó wí pé: ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa+ ti yàn ọ́+ láti wá mọ ìfẹ́ rẹ̀ àti láti rí+ Ẹni+ olódodo náà àti láti gbọ́ ohùn ẹnu rẹ̀,+ 15  nítorí pé ìwọ yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí fún un sí gbogbo ènìyàn nípa àwọn ohun tí ìwọ ti rí, tí o sì ti gbọ́.+ 16  Nísinsìnyí, èé ti ṣe tí ìwọ fi ń jáfara? Dìde, kí a batisí rẹ,+ kí o sì wẹ+ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù nípa kíké tí o bá ń ké pe orúkọ rẹ̀.’+ 17  “Ṣùgbọ́n nígbà tí mo ti padà sí Jerúsálẹ́mù,+ tí mo sì ń gbàdúrà nínú tẹ́ńpìlì, mo bọ́ sínú ojúran,+ 18  mo sì rí i tí ó ń wí fún mi pé, ‘Ṣe wéré, kí o sì jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù ní kíákíá, nítorí pé wọn kì yóò gba+ ẹ̀rí rẹ nípa mi.’ 19  Mo sì wí pé, ‘Olúwa, àwọn fúnra wọn mọ̀ dunjú pé tẹ́lẹ̀rí mo máa ń sọ àwọn tí wọ́n gbà ọ́ gbọ́ sẹ́wọ̀n,+ mo sì máa ń nà wọ́n lẹ́gba ní sínágọ́gù kan tẹ̀ lé òmíràn;+ 20  nígbà tí a sì ń ta ẹ̀jẹ̀ Sítéfánù+ ẹlẹ́rìí rẹ sílẹ̀, èmi alára dúró nítòsí, mo fọwọ́ sí,+ mo sì ń ṣọ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè àwọn tí ó pa á.’ 21  Síbẹ̀, ó wí fún mi pé: ‘Mú ọ̀nà rẹ pọ̀n, nítorí pé èmi yóò rán ọ jáde lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè jíjìnnàréré.’”+ 22  Wàyí o, wọ́n ń fetí sí i títí dé orí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, pé: “Mú irúfẹ́ ọkùnrin bẹ́ẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀ ayé, nítorí pé kò yẹ kí ó wà láàyè!”+ 23  Àti nítorí pé wọ́n ń ké jáde, tí wọ́n sì ń ju ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn káàkiri, tí wọ́n sì ń da ekuru sókè sínú afẹ́fẹ́,+ 24  ọ̀gágun náà pàṣẹ pé kí a mú un wá sí ibùdó àwọn ọmọ ogun, ó sì ní kí wọ́n fi ìnàlọ́rẹ́ wádìí rẹ̀ wò, kí òun lè mọ̀ ní kíkún, ìdí tí wọ́n fi ń kígbe+ lòdì sí i báyìí. 25  Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n ti nà án tàntàn fún nínà ní pàṣán, Pọ́ọ̀lù wí fún ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó dúró níbẹ̀ pé: “Ó ha bófin mu fún yín láti na ẹni tí ó jẹ́ ará Róòmù,+ tí a kò sì dá lẹ́bi lọ́rẹ́?” 26  Tóò, nígbà tí ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà gbọ́ èyí, ó lọ bá ọ̀gágun, ó sì ròyìn, pé: “Kí ni ìwọ ń pète-pèrò láti ṣe? Họ́wù, ará Róòmù ni ọkùnrin yìí.” 27  Nítorí náà, ọ̀gágun sún mọ́ tòsí, ó sì wí fún un pé: “Sọ fún mi, Ṣé ará Róòmù ni ọ́?”+ Ó wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” 28  Ọ̀gágun dáhùn padà pé: “Iye owó gọbọi ni mo fi ra ẹ̀tọ́ wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí aráàlú.” Pọ́ọ̀lù wí pé: “Ṣùgbọ́n inú wọn ni a tilẹ̀ bí+ mi sí.” 29  Nítorí náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ fi ìdálóró wádìí rẹ̀ wò fi í sílẹ̀; ọ̀gágun náà sì fòyà nígbà tí ó rí i dájú pé ará Róòmù ni,+ tí òun sì ti dè é tẹ́lẹ̀. 30  Nítorí náà, ní ọjọ́ kejì, bí ó ti fẹ́ láti mọ̀ dájú, ìdí rẹ̀ gan-an tí àwọn Júù fi ń fẹ̀sùn kàn án, ó tú u, ó sì pàṣẹ pé kí àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo Sànhẹ́dírìn péjọ. Ó sì mú Pọ́ọ̀lù sọ̀ kalẹ̀ wá, ó sì mú un dúró láàárín wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé