Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣe 21:1-40

21  Wàyí o, nígbà tí a ti já ara wa gbà lọ́wọ́ wọn, tí a sì ṣíkọ̀ sójú òkun, a lọ tààrà ní ipa ọ̀nà kan, a sì wá sí Kọ́sì, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì sí Ródésì, àti láti ibẹ̀ sí Pátárà.  Nígbà tí a sì ti rí ọkọ̀ ojú omi kan tí ń sọdá lọ sí Foníṣíà, a wọ̀ ọ́, a sì ṣíkọ̀ lọ.  Lẹ́yìn tí a dé itòsí erékùṣù Kípírù,+ a fi í sílẹ̀ sẹ́yìn ní apá òsì, a sì tukọ̀ nìṣó lọ sí Síríà,+ a sì gúnlẹ̀ sí Tírè, nítorí pé ibẹ̀ ni ọkọ̀ ojú omi náà yóò ti já ẹrù rẹ̀.+  Nípa ìwákáàkiri, a rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, a sì dúró níhìn-ín fún ọjọ́ méje. Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹ̀mí,+ wọ́n sọ fún Pọ́ọ̀lù léraléra láti má fi ẹsẹ̀ tẹ Jerúsálẹ́mù.  Nítorí náà, nígbà tí a ti lo àwọn ọjọ́ náà pé, a jáde lọ, a sì bẹ̀rẹ̀ sí bá ọ̀nà wa lọ; ṣùgbọ́n gbogbo wọn, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, sìn wá títí dé ẹ̀yìn òde ìlú ńlá náà. Bí a sì ti kúnlẹ̀+ ní etíkun, a gba àdúrà,  a sì sọ pé ó dìgbòóṣe+ fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, a sì gòkè sínú ọkọ̀ ojú omi, ṣùgbọ́n wọ́n padà sí ilé wọn.  Nígbà náà ni a parí ìrìn àjò ojú omi láti Tírè, a sì dé Tólémáísì, a kí àwọn ará, a sì dúró lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ kan.  Ní ọjọ́ kejì, a mú ọ̀nà wa pọ̀n, a sì dé Kesaréà,+ a sì wọ ilé Fílípì ajíhìnrere, ẹni tí í ṣe ọ̀kan lára ọkùnrin méje náà,+ a sì dúró lọ́dọ̀ rẹ̀.  Ọkùnrin yìí ní ọmọbìnrin mẹ́rin, wúńdíá, tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀.+ 10  Ṣùgbọ́n bí a ti dúró fún iye ọjọ́ púpọ̀ díẹ̀, wòlíì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ágábù+ sọ̀ kalẹ̀ wá láti Jùdíà, 11  ó wá sọ́dọ̀ wa, ó mú àmùrè Pọ́ọ̀lù, ó de ẹsẹ̀ àti ọwọ́ ara rẹ̀, ó sì wí pé: “Báyìí ni ẹ̀mí mímọ́ wí, ‘Ọkùnrin tí àmùrè yìí jẹ́ tirẹ̀ ni àwọn Júù yóò dè+ lọ́nà yìí ní Jerúsálẹ́mù, wọn yóò sì fi í lé àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́.’”+ 12  Wàyí o, nígbà tí a gbọ́ èyí, àti àwa àti àwọn ará ibẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí pàrọwà fún un láti má gòkè lọ+ sí Jerúsálẹ́mù. 13  Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù dáhùn pé: “Kí ni ẹ ń ṣe nípa sísunkún,+ tí ẹ sì ń sọ mí di aláìlera ní ọkàn-àyà?+ Kí ó dá yín lójú pé, mo ti múra tán, kì í ṣe fún dídè nìkan ni, ṣùgbọ́n láti kú+ pẹ̀lú ní Jerúsálẹ́mù nítorí orúkọ Jésù Olúwa.” 14  Nígbà tí a kò lè mú kí ó pa èrò rẹ̀ dà, a gbà láìjanpata pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Kí ìfẹ́+ Jèhófà ṣẹ.” 15  Wàyí o, lẹ́yìn ọjọ́ wọ̀nyí, a múra sílẹ̀ fún ìrìn àjò náà, a sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù.+ 16  Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn kan láti Kesaréà+ pẹ̀lú bá wa lọ, láti mú wa wá sọ́dọ̀ ọkùnrin náà ní ilé ẹni tí a ó ti ṣe wá lálejò, Mínásónì kan tí í ṣe ará Kípírù, ọmọ ẹ̀yìn kan láti ìjímìjí. 17  Nígbà tí a wọ Jerúsálẹ́mù,+ àwọn ará fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà wá.+ 18  Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, Pọ́ọ̀lù lọ pẹ̀lú wa sọ́dọ̀ Jákọ́bù;+ gbogbo àwọn àgbà ọkùnrin sì wà níbẹ̀. 19  Ó kí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣèròyìn+ ní kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe láàárín àwọn orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun.+ 20  Lẹ́yìn gbígbọ́ èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé: “Arákùnrin, ìwọ rí bí ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún onígbàgbọ́ tí ń bẹ láàárín àwọn Júù ti pọ̀ tó; gbogbo wọ́n sì jẹ́ onítara fún Òfin.+ 21  Ṣùgbọ́n wọ́n ti gbọ́ tí a sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ àhesọ nípa rẹ pé ìwọ ń kọ́ gbogbo Júù tí ń bẹ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè ní ìpẹ̀yìndà sí Mósè,+ ní sísọ fún wọn láti má ṣe dádọ̀dọ́+ àwọn ọmọ wọn tàbí rìn nínú àwọn àṣà aláàtò ìsìn. 22  Kí wá ni ṣíṣe nípa rẹ̀? Bí ó ti wù kí ó rí, wọn yóò gbọ́ pé o ti dé. 23  Nítorí náà, ṣe èyí tí a sọ fún ọ: Ọkùnrin mẹ́rin wà lọ́dọ̀ wa tí wọ́n ti fi ara wọn jẹ́jẹ̀ẹ́. 24  Mú àwọn ọkùnrin yìí dání,+ kí o sì wẹ ara rẹ mọ́ lọ́nà ayẹyẹ pẹ̀lú wọn, kí o sì bójú tó ìnàwó wọn,+ kí wọ́n lè fá orí wọn.+ Nítorí náà, gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé kò sí nǹkan kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ àhesọ tí a sọ fún wọn nípa rẹ, ṣùgbọ́n pé ìwọ ń rìn létòletò, pé ìwọ alára pẹ̀lú ń pa Òfin mọ́.+ 25  Ní ti àwọn onígbàgbọ́ láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwa ti ránṣẹ́, ní sísọ ìpinnu wa pé kí wọ́n pa ara wọn mọ́ kúrò nínú nǹkan tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà+ àti pẹ̀lú kúrò nínú ẹ̀jẹ̀+ àti ohun tí a fún lọ́rùn pa+ àti kúrò nínú àgbèrè.”+ 26  Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù mú àwọn ọkùnrin náà dání ní ọjọ́ kejì, ó sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ lọ́nà ayẹyẹ pẹ̀lú wọn,+ ó sì wọ tẹ́ńpìlì lọ, láti pèsè ìsọfúnni nípa àwọn ọjọ́ tí ìwẹ̀nùmọ́ aláyẹyẹ náà yóò gbà,+ kí ó tó di pé a mú ọrẹ ẹbọ+ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn wá.+ 27  Wàyí o, nígbà tí ọjọ́ méje+ náà fẹ́rẹ̀ẹ́ parí, rírí tí àwọn Júù láti Éṣíà rí i nínú tẹ́ńpìlì, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kó gbogbo ogunlọ́gọ̀ náà sínú ìdàrúdàpọ̀,+ wọ́n sì nawọ́ mú un, 28  wọ́n ké jáde pé: “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbani o! Èyí ni ọkùnrin tí ń kọ́ gbogbo ènìyàn níbi gbogbo lòdì sí àwọn ènìyàn+ àti Òfin àti ibí yìí àti pé, jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó tilẹ̀ mú àwọn Gíríìkì wá sínú tẹ́ńpìlì, ó sì ti sọ ibi mímọ́ yìí di ẹlẹ́gbin.”+ 29  Nítorí pé wọ́n ti rí Tírófímù+ ará Éfésù tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìlú ńlá náà, ṣùgbọ́n wọ́n lérò pé Pọ́ọ̀lù ti mú un wá sínú tẹ́ńpìlì. 30  A sì kó gbogbo ìlú ńlá náà sínú ìrọ́kẹ̀kẹ̀,+ ìsáré-papọ̀ àwọn ènìyàn náà sì ṣẹlẹ̀; wọ́n sì nawọ́ mú Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì wọ́ ọ lọ sí ẹ̀yìn òde tẹ́ńpìlì.+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n sé àwọn ilẹ̀kùn. 31  Bí wọ́n sì ti ń wá ọ̀nà láti pa á, ìsọfúnni gòkè wá sọ́dọ̀ ọ̀gágun àwùjọ ọmọ ogun pé gbogbo Jerúsálẹ́mù wà nínú ìdàrúdàpọ̀;+ 32  ní kíákíá, ó kó àwọn ọmọ ogun àti àwọn ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ó sì sáré sọ̀ kalẹ̀ lọ bá wọn.+ Nígbà tí wọ́n tajú kán rí ọ̀gágun+ náà àti àwọn ọmọ ogun, wọ́n ṣíwọ́ lílu Pọ́ọ̀lù. 33  Nígbà náà ni ọ̀gágun náà sún mọ́ tòsí, ó dì í mú, ó sì pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é;+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí nípa ẹni tí òun jẹ́ àti ohun tí ó ṣe. 34  Ṣùgbọ́n àwọn kan nínú ogunlọ́gọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí kígbe ohun kan, àti àwọn mìíràn ohun mìíràn.+ Nítorí náà, níwọ̀n bí kò ti ṣeé ṣe fún un láti gbọ́ ohun kan pàtó nítorí ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ pé kí a mú un wá sí ibùdó àwọn ọmọ ogun.+ 35  Ṣùgbọ́n nígbà tí ó dé orí àtẹ̀gùn, ipò náà wá di pé gbígbé ni àwọn ọmọ ogun gbé e kọjá nítorí ìwà ipá ogunlọ́gọ̀ náà; 36  nítorí pé ògìdìgbó àwọn ènìyàn náà ń tẹ̀ lé wọn, tí wọ́n ń ké jáde pé: “Mú un kúrò!”+ 37  Bí wọ́n sì ti fẹ́ mú un wọ ibùdó àwọn ọmọ ogun, Pọ́ọ̀lù wí fún ọ̀gágun náà pé: “A ha yọ̀ǹda fún mi láti sọ ohun kan fún ọ bí?” Ó wí pé: “Ìwọ lè sọ èdè Gíríìkì bí? 38  Ní ti gidi, ǹjẹ́ ìwọ kọ́ ni ará Íjíbítì tí ó ru ìdìtẹ̀ sí ìjọba+ sókè ní ìjelòó, tí ó sì mú ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àwọn ọkùnrin ọlọ́bẹ aṣóró jáde lọ sí aginjù?” 39  Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù wí pé: “Ní ti tòótọ́, Júù ni mí,+ láti Tásù+ ní Sìlíṣíà, aráàlú ìlú ńlá kan tí kò mù rárá. Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́, gbà mí láyè láti bá àwọn ènìyàn náà sọ̀rọ̀.” 40  Lẹ́yìn tí ó gbà á láyè, Pọ́ọ̀lù, ní dídúró lórí àtẹ̀gùn náà, juwọ́+ sí àwọn ènìyàn náà. Nígbà tí kẹ́kẹ́ pa, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù,+ pé:

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé