Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 20:1-38

20  Wàyí o, lẹ́yìn tí ìrọ́kẹ̀kẹ̀ náà ti rọlẹ̀, Pọ́ọ̀lù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn, nígbà tí ó sì ti fún wọn ní ìṣírí, tí ó sì ti dá gbére fún wọn pé ó dìgbà kan ná,+ ó jáde lọ láti rin ìrìn àjò lọ sí Makedóníà.+  Lẹ́yìn líla àwọn ibi wọnnì, já tí ó sì ń fún àwọn tí ń bẹ níbẹ̀ ní ìṣírí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀,+ ó wá sí ilẹ̀ Gíríìkì.  Nígbà tí ó sì ti lo oṣù mẹ́ta níbẹ̀, nítorí pé àwọn Júù wéwèé ìdìmọ̀lù+ kan lòdì sí i bí ó ti fẹ́ ṣíkọ̀ lọ sí Síríà, ó ṣe ìpinnu láti gba ti Makedóníà padà.  Àwọn tí ń bá a lọ ni Sópátérì+ ọmọkùnrin Párù ará Bèróà, Àrísítákọ́sì+ àti Sẹ́kúńdù àwọn ará Tẹsalóníkà, àti Gáyọ́sì ará Déébè, àti Tímótì,+ àti láti àgbègbè Éṣíà Tíkíkù+ àti Tírófímù.+  Àwọn wọ̀nyí lọ, wọ́n sì ń dúró dè wá ní Tíróásì;+  ṣùgbọ́n a ṣíkọ̀ sójú òkun láti ìlú Fílípì lẹ́yìn àwọn ọjọ́ àkàrà aláìwú,+ a sì dé ọ̀dọ̀ wọn ní Tíróásì+ láàárín ọjọ́ márùn-ún; a sì lo ọjọ́ méje níbẹ̀.  Ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀,+ nígbà tí a kóra jọpọ̀ láti jẹ oúnjẹ, Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí wí àwíyé fún wọn, níwọ̀n bí òun yóò ti lọ ní ọjọ́ kejì; ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di ọ̀gànjọ́ òru.  Nítorí náà, fìtílà tí ó pọ̀ díẹ̀ wà ní ìyẹ̀wù òkè+ níbi tí a kóra jọpọ̀ sí.  Ọ̀dọ́kùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Yútíkọ́sì, tí ó jókòó sójú fèrèsé, ni oorun àsùnwọra gbé lọ bí Pọ́ọ̀lù ti ń bá ọ̀rọ̀ nìṣó, àti pé, ní sísọranù lójú oorun, ó ṣubú lulẹ̀ láti àjà kẹta, a sì gbé e ní òkú. 10  Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù lọ sísàlẹ̀, ó dùbúlẹ̀ lé e,+ ó sì fi ọwọ́ gbá a mọ́ra, ó sì wí pé: “Ẹ dẹ́kun pípariwo gèè, nítorí pé ọkàn rẹ̀ wà nínú rẹ̀.”+ 11  Ó gòkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì lọ wàyí, ó sì bẹ̀rẹ̀ oúnjẹ, ó sì jẹun, àti lẹ́yìn bíbánisọ̀rọ̀ fún ìgbà tí ó pẹ́ díẹ̀, títí di àfẹ̀mọ́jú, níkẹyìn ó lọ. 12  Nítorí náà, wọ́n mú ọmọdékùnrin náà lọ láàyè, a sì tù wọ́n nínú lọ́nà tí kò ṣeé díwọ̀n. 13  Wàyí o, a tẹ̀ síwájú lọ sídìí ọkọ̀ ojú omi, a sì ṣíkọ̀ lọ sí Ásò, níbi tí a pète-pèrò pé a ó ti fi ọkọ̀ gbé Pọ́ọ̀lù, nítorí pé, lẹ́yìn fífúnni ní àwọn ìtọ́ni láti ṣe èyí, òun fúnra rẹ̀ pète-pèrò láti fi ẹsẹ̀ rìn lọ. 14  Nítorí náà, nígbà tí ó bá wa ní Ásò, a fi ọkọ̀ gbé e, a sì lọ sí Mítílénè; 15  àti pé, ní ṣíṣíkọ̀ lọ láti ibẹ̀ ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, a dé òdì-kejì Kíósì, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, a fi ẹsẹ̀ kan dé Sámósì, a sì dé Mílétù ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e. 16  Nítorí Pọ́ọ̀lù ti pinnu láti wọkọ̀ ojú omi kọjá Éfésù,+ kí ó má bàa lo àkókò kankan ní àgbègbè Éṣíà; nítorí pé ó ń ṣe kánkán láti dé Jerúsálẹ́mù+ ní ọjọ́ àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì, bí ó bá lè ṣeé ṣe fún un. 17  Bí ó ti wù kí ó rí, láti Mílétù, ó ránṣẹ́ sí Éfésù, ó sì pe àwọn àgbà ọkùnrin+ ìjọ wá. 18  Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin mọ̀ dunjú, bí ó ti jẹ́ pé láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí mo dé sí àgbègbè Éṣíà+ ni mo ti wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àkókò,+ 19  tí mo ń sìnrú+ fún Olúwa pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú+ títóbi jù lọ àti omijé àti àwọn àdánwò tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi nípasẹ̀ àwọn ìdìmọ̀lù+ àwọn Júù; 20  bí èmi kò ti fà sẹ́yìn kúrò nínú sísọ èyíkéyìí lára àwọn ohun tí ó lérè nínú fún yín tàbí kúrò nínú kíkọ́+ yín ní gbangba àti láti ilé+ dé ilé. 21  Ṣùgbọ́n mo jẹ́rìí+ kúnnákúnná fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì nípa ìrònúpìwàdà+ sí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù. 22  Ẹ sì wò ó! nísinsìnyí, ní dídè nínú ẹ̀mí,+ mo ń rin ìrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò mọ àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí mi nínú rẹ̀, 23  àyàfi bí ó ti jẹ́ pé láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá ni ẹ̀mí mímọ́+ ti ń jẹ́rìí fún mi léraléra bí ó ti ń sọ pé àwọn ìdè àti ìpọ́njú ń dúró dè mí.+ 24  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan kan tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi,+ bí mo bá sáà ti lè parí ipa ọ̀nà+ mi àti iṣẹ́ òjíṣẹ́+ tí mo gbà+ lọ́wọ́ Jésù Olúwa, láti jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.+ 25  “Ẹ sì wò ó! nísinsìnyí, mo mọ̀ pé gbogbo yín láàárín ẹ̀yin tí mo ti wàásù ìjọba náà kò tún ní rí ojú mi mọ́. 26  Nítorí bẹ́ẹ̀, mo pè yín ṣe ẹlẹ́rìí ní òní yìí gan-an pé ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀+ ènìyàn gbogbo, 27  nítorí pé èmi kò fà sẹ́yìn kúrò nínú sísọ gbogbo ìpinnu+ Ọlọ́run fún yín. 28  Ẹ kíyè sí+ ara yín+ àti gbogbo agbo,+ láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yín ṣe alábòójútó,+ láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run,+ èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀+ Ọmọkùnrin òun fúnra rẹ̀ rà. 29  Mo mọ̀ pé lẹ́yìn lílọ mi, àwọn aninilára ìkookò+ yóò wọlé wá sáàárín yín, wọn kì yóò sì fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo, 30  àti pé láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà+ láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.+ 31  “Nítorí náà, ẹ máa wà lójúfò, kí ẹ sì fi í sọ́kàn pé fún ọdún mẹ́ta,+ ní òru àti ní ọ̀sán, èmi kò jáwọ́ nínú ṣíṣí yín létí+ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú omijé. 32  Nísinsìnyí, mo fi yín lé Ọlọ́run+ lọ́wọ́ àti ọ̀rọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀, ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé yín ró,+ kí ó sì fún yín ní ogún náà láàárín gbogbo àwọn tí a sọ di mímọ́.+ 33  Èmi kò ṣojúkòkòrò fàdákà tàbí wúrà tàbí aṣọ ọ̀ṣọ́ ènìyàn kankan.+ 34  Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé ọwọ́ wọ̀nyí ni ó ti ṣiṣẹ́ fún àwọn àìní tèmi+ àti ti àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú mi. 35  Mo ti fi hàn yín nínú ohun gbogbo pé nípa ṣíṣe òpò+ lọ́nà yìí, ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlera,+ ẹ sì gbọ́dọ̀ fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa sọ́kàn, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ wí pé, ‘Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni+ ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.’” 36  Nígbà tí ó sì ti sọ nǹkan wọ̀nyí tán, ó kúnlẹ̀+ pẹ̀lú gbogbo wọn, ó sì gbàdúrà. 37  Ní tòótọ́, ẹkún sísun tí kò mọ níwọ̀n bẹ́ sílẹ̀ láàárín gbogbo wọn, wọ́n sì rọ̀ mọ́ ọrùn+ Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu+ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, 38  nítorí pé ọ̀rọ̀ tí ó sọ, pé wọn kì yóò tún rí ojú+ òun mọ́, dùn wọ́n ní pàtàkì. Nítorí náà, wọ́n tẹ̀ síwájú láti sìn+ ín dé ìdí ọkọ̀ ojú omi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé