Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣe 18:1-28

18  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ó lọ kúrò ní Áténì, ó sì wá sí Kọ́ríńtì.  Ó sì rí Júù kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ákúílà,+ ọmọ ìbílẹ̀ Pọ́ńtù, ẹni tí ó wá láti Ítálì+ ní lọ́ọ́lọ́ọ́, àti Pírísílà aya rẹ̀, nítorí òtítọ́ náà pé Kíláúdíù+ ti pa àṣẹ pé kí àwọn Júù kúrò ní Róòmù. Nítorí náà, ó lọ bá wọn, 3  àti ní tìtorí pé iṣẹ́ ọwọ́ kan náà ni wọ́n jọ ń ṣe, ó dúró sí ilé wọn, wọ́n sì ṣiṣẹ́,+ nítorí pé ní ti iṣẹ́ ọwọ́, wọ́n jẹ́ olùpàgọ́.  Bí ó ti wù kí ó rí, òun a máa sọ àsọyé nínú sínágọ́gù+ ní gbogbo sábáàtì, a sì máa yí àwọn Júù àti Gíríìkì lérò padà.  Wàyí o, nígbà tí Sílà+ àti Tímótì+ sọ̀ kalẹ̀ wá láti Makedóníà, ọwọ́ Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí dí jọjọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà, ó ń jẹ́rìí fún àwọn Júù láti fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn pé Jésù ni Kristi náà.+  Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí wọ́n ń bá a nìṣó ní ṣíṣàtakò àti ní sísọ̀rọ̀ tèébútèébú,+ ó gbọn ẹ̀wù rẹ̀,+ ó sì wí fún wọn pé: “Kí ẹ̀jẹ̀+ yín wà ní orí ẹ̀yin fúnra yín. Ọrùn mi mọ́.+ Láti ìsinsìnyí lọ, ṣe ni èmi yóò lọ bá àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè.”+  Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣí kúrò níbẹ̀, ó sì lọ sínú ilé ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Títíọ́sì Jọ́sítù, olùjọsìn Ọlọ́run, ẹni tí ilé rẹ̀ gbe sínágọ́gù.  Ṣùgbọ́n Kírípọ́sì+ tí ó jẹ́ alága sínágọ́gù di onígbàgbọ́ nínú Olúwa, bẹ́ẹ̀ sì ni gbogbo agbo ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Kọ́ríńtì tí wọ́n sì gbọ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbà gbọ́, a sì ń batisí wọn.  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní òru, Olúwa sọ fún Pọ́ọ̀lù+ nípasẹ̀ ìran kan pé: “Má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n máa bá a nìṣó ní sísọ̀rọ̀, má sì dákẹ́, 10  nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,+ kò sì sí ènìyàn kankan tí yóò fipá kọlù ọ́ láti ṣe ọ́ léṣe; nítorí tí mo ní ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìlú ńlá yìí.” 11  Nítorí náà, ó dúró pẹ́ níbẹ̀ fún ọdún kan àti oṣù mẹ́fà, ó ń kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàárín wọn. 12  Wàyí o, nígbà tí Gálíò jẹ́ alákòósò ìbílẹ̀+ ti Ákáyà, àwọn Júù dìde sí Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n sì mú un lọ síwájú ìjókòó ìdájọ́,+ 13  wọ́n wí pé: “Ní ìlòdìsí òfin, ẹni yìí ń ṣamọ̀nà+ àwọn ènìyàn sí ọ̀nà ìgbàgbọ́ mìíràn nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run.” 14  Ṣùgbọ́n bí Pọ́ọ̀lù ti fẹ́ la ẹnu rẹ̀, Gálíò sọ fún àwọn Júù pé: “Ní tòótọ́, bí ó bá jẹ́ ìwà àìtọ́ kan ni tàbí ìwà aṣa burúkú kan, ẹ̀yin Júù, pẹ̀lú ìdí rere èmi yóò fi sùúrù fara dà á fún yín. 15  Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ àwọn àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ àti àwọn orúkọ+ àti òfin+ àárín yín, ẹ̀yin fúnra yín ni kí ẹ lọ bójú tó o. Èmi kò fẹ́ jẹ́ onídàájọ́ nǹkan wọ̀nyí.” 16  Pẹ̀lú ìyẹn, ó lé wọn kúrò níbi ìjókòó ìdájọ́. 17  Nítorí náà, gbogbo wọ́n gbá Sótínésì+ mú, ẹni tí í ṣe alága sínágọ́gù, wọ́n sì ń lù ú níwájú ìjókòó ìdájọ́. Ṣùgbọ́n Gálíò kò tilẹ̀ kọbi ara sí nǹkan wọ̀nyí rárá. 18  Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn dídúró fún ọjọ́ mélòó kan sí i, Pọ́ọ̀lù sọ pé ó dìgbòóṣe fún àwọn ará, ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣíkọ̀ lọ sí Síríà, Pírísílà àti Ákúílà sì pẹ̀lú rẹ̀, níwọ̀n bí ó ti gé irun orí rẹ̀ kúrú+ ní Kẹnkíríà,+ nítorí pé ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan. 19  Nípa báyìí, wọ́n dé Éfésù, ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀; ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ wọ sínágọ́gù+ lọ, ó sì fèrò-wérò pẹ̀lú àwọn Júù. 20  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń béèrè pé kí ó dúró fún àkókò gígùn sí i, kò gbà, 21  ṣùgbọ́n ó sọ pé ó dìgbòóṣe,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Èmi yóò tún padà wá sọ́dọ̀ yín, bí Jèhófà bá fẹ́.”+ Ó sì ṣíkọ̀ sójú òkun láti Éfésù, 22  ó sì sọ̀ kalẹ̀ wá sí Kesaréà. Ó gòkè lọ kí ìjọ, ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Áńtíókù. 23  Nígbà tí ó sì ti lo àkókò díẹ̀ níbẹ̀, ó kúrò, ó sì lọ láti ibì kan sí ibì kan, la ilẹ̀ Gálátíà+ àti Fíríjíà+ já, ó ń fún gbogbo ọmọ ẹ̀yìn lókun.+ 24  Wàyí o, Júù kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àpólò,+ ọmọ ìbílẹ̀ Alẹkisáńdíríà, ọkùnrin sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan, dé sí Éfésù; ó sì jẹ́ ògbóǹkangí nínú Ìwé Mímọ́.+ 25  Ọkùnrin yìí ni a ti fi ọ̀rọ̀ ẹnu fún ní ìtọ́ni ní ọ̀nà Jèhófà àti pé, bí iná ẹ̀mí ti ń jó nínú rẹ̀,+ ó ń sọ̀rọ̀, ó sì ń fi àwọn nǹkan nípa Jésù kọ́ni pẹ̀lú ìpérẹ́gí, ṣùgbọ́n ìbatisí+ Jòhánù nìkan ni ó mọ̀. 26  Ọkùnrin yìí sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ láìṣojo nínú sínágọ́gù. Nígbà tí Pírísílà àti Ákúílà+ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un wọ àwùjọ ẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì làdí ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí. 27  Síwájú sí i, nítorí pé ó fẹ́ láti sọdá lọ sí Ákáyà, àwọn ará kọ̀wé sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ní gbígbà wọ́n níyànjú láti fi inú rere gbà á. Nítorí náà, nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó ṣe ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà+ fún àwọn tí wọ́n ti gbà gbọ́ ní tìtorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ [Ọlọ́run]; 28  nítorí pé pẹ̀lú ìgbóná janjan, ó fi hàn délẹ̀délẹ̀ ní gbangba pé àwọn Júù kò tọ̀nà, bí ó ti fi hàn nípasẹ̀ Ìwé Mímọ́+ pé Jésù ni Kristi náà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé