Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 17:1-34

17  Wàyí o, wọ́n rin ìrìn àjò la Áńfípólì àti Apolóníà kọjá, wọ́n sì wá sí Tẹsalóníkà,+ níbi tí sínágọ́gù àwọn Júù wà.  Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àṣà Pọ́ọ̀lù,+ ó wọlé lọ bá wọn, fún sábáàtì mẹ́ta ni ó sì fi bá wọn fèrò-wérò láti inú Ìwé Mímọ́,+  ó ń ṣàlàyé, ó sì ń fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn nípasẹ̀ àwọn ìtọ́ka pé ó pọn dandan kí Kristi jìyà,+ kí ó sì dìde kúrò nínú òkú,+ ó sì wí pé: “Èyí ni Kristi náà,+ Jésù yìí tí mo ń kéde fún yín.”  Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, àwọn kan lára wọ́n di onígbàgbọ́,+ wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà,+ àti ògìdìgbó ńlá àwọn Gíríìkì tí ń jọ́sìn Ọlọ́run, kì í sì í ṣe díẹ̀ lára àwọn sàràkí-sàràkí obìnrin ni wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.  Ṣùgbọ́n àwọn Júù, ní jíjowú,+ mú àwọn ọkùnrin burúkú kan tí wọ́n jẹ́ aláìríkan-ṣèkan ibi ọjà wọ àwùjọ ẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì kó àwùjọ onírúgùdù jọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ìlú ńlá náà sínú ìrọ́kẹ̀kẹ̀.+ Wọ́n sì fipá kọlu ilé Jásónì,+ wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti mú wọn wá síwájú àwùjọ màdàrú náà.  Nígbà tí wọn kò rí wọn, wọ́n wọ́ Jásónì àti àwọn arákùnrin kan lọ sọ́dọ̀ àwọn olùṣàkóso ìlú ńlá náà, wọ́n ń ké jáde pé: “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí wọ́n ti sojú ilẹ̀ ayé tí a ń gbé dé+ ti dé síhìn-ín pẹ̀lú,  Jásónì sì ti gbà wọ́n pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò. Gbogbo ọkùnrin wọ̀nyí ni wọ́n sì ń gbé ìgbésẹ̀ ní ìlòdìsí àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀+ Késárì, wí pé ọba+ mìíràn wà, Jésù.” 8  Ní tòótọ́, wọ́n kó ṣìbáṣìbo bá ogunlọ́gọ̀ àti àwọn olùṣàkóso ìlú ńlá náà nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí;  lẹ́yìn kíkọ́kọ́ gba ohun ìdúró tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́ Jásónì àti àwọn yòókù sì ni wọ́n tó jẹ́ kí wọ́n lọ. 10  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní òru,+ àwọn ará rán Pọ́ọ̀lù àti Sílà jáde lọ sí Bèróà, bí àwọn wọ̀nyí sì ti dé ibẹ̀, wọ́n wọ sínágọ́gù àwọn Júù lọ. 11  Wàyí o, àwọn tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn yìí ní ọkàn-rere ju àwọn ti Tẹsalóníkà lọ, nítorí pé wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò+ Ìwé Mímọ́+ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.+ 12  Nítorí náà, púpọ̀ nínú wọ́n di onígbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe díẹ̀ lára àwọn obìnrin àti ọkùnrin Gíríìkì tí wọ́n ní ìsì rere+ ni wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. 13  Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù láti Tẹsalóníkà gbọ́ pé Pọ́ọ̀lù ti kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Bèróà pẹ̀lú, wọ́n wá sí ibẹ̀ pẹ̀lú láti ru àgbájọ ènìyàn náà lọ́kàn sókè+ àti láti kó ṣìbáṣìbo bá wọn.+ 14  Nígbà náà ni àwọn ará rán Pọ́ọ̀lù jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti lọ jìnnà títí dé òkun;+ ṣùgbọ́n Sílà àti Tímótì dúró sẹ́yìn níbẹ̀. 15  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí ń sin Pọ́ọ̀lù lọ mú un wá títí dé Áténì àti pé, lẹ́yìn gbígba àṣẹ pé kí Sílà àti Tímótì+ wá bá òun ní kíákíá bí ó bá ti lè yá tó, wọ́n lọ. 16  Wàyí o, bí Pọ́ọ̀lù ti ń dúró dè wọ́n ní Áténì, ẹ̀mí rẹ̀ ni a sún bínú+ nínú rẹ̀ ní rírí i pé ìlú ńlá náà kún fún òrìṣà. 17  Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí fèrò-wérò nínú sínágọ́gù pẹ̀lú àwọn Júù+ àti àwọn ènìyàn mìíràn tí ń jọ́sìn Ọlọ́run àti ní ojoojúmọ́ ní ibi ọjà+ pẹ̀lú àwọn tí ó wà ní àrọ́wọ́tó. 18  Ṣùgbọ́n àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Epikúréì àti àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí+ Sítọ́ìkì bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà àríyànjiyàn, àwọn kan a sì sọ pé: “Kí ni ohun tí onírèégbè yìí ní í sọ?”+ Àwọn mìíràn a sọ pé: “Ó dà bí pé ó jẹ́ akéde àwọn ọlọ́run àjúbàfún ti ilẹ̀ òkèèrè.” Èyí jẹ́ nítorí pé ó ń polongo ìhìn rere Jésù àti àjíǹde.+ 19  Nítorí náà, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un lọ sí Áréópágù, wọ́n wí pé: “Ǹjẹ́ a lè mọ ohun tí ẹ̀kọ́ tuntun+ tí ìwọ ń sọ yìí jẹ́? 20  Nítorí pé àwọn ohun kan tí ó ṣàjèjì sí etí wa ni ìwọ ń mú wọlé wá. Nítorí náà, àwa fẹ́ láti mọ ìtúmọ̀ tí nǹkan wọ̀nyí gbé yọ.”+ 21  Ní ti tòótọ́, gbogbo ará Áténì àti àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ń ṣàtìpó níbẹ̀ kì í lo àkókò tí ọwọ́ wọ́n dilẹ̀ fún nǹkan mìíràn bí kò ṣe fún sísọ ohun kan tàbí fífetísí ohun tí ó jẹ́ tuntun. 22  Wàyí o, Pọ́ọ̀lù dúró ní àárín Áréópágù,+ ó sì wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn Áténì, mo ṣàkíyèsí pé nínú ohun gbogbo, ó jọ pé ẹ kún fún ìbẹ̀rù àwọn ọlọ́run àjúbàfún+ ju àwọn mìíràn lọ. 23  Fún àpẹẹrẹ, bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo sì ń fẹ̀sọ̀ kíyè sí àwọn ohun tí ẹ ń júbà fún, mo tún rí pẹpẹ kan, lórí èyí tí a kọ àkọlé náà ‘Sí Ọlọ́run Àìmọ̀.’ Nítorí náà, ohun tí ẹ ń fún ní ìfọkànsin Ọlọ́run láìmọ̀, èyí ni mo ń kéde fún yín. 24  Ọlọ́run tí ó dá ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹni yìí ti jẹ́, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,+ kì í gbé inú àwọn tẹ́ńpìlì àfọwọ́kọ́,+ 25  bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn ṣe ìránṣẹ́ fún un bí ẹni pé ó ṣe aláìní nǹkan kan,+ nítorí òun fúnra rẹ̀ ni ó fún gbogbo ènìyàn ní ìyè+ àti èémí+ àti ohun gbogbo. 26  Láti ara ọkùnrin kan+ ni ó sì ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè+ àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá,+ ó sì gbé àṣẹ kalẹ̀ nípa àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀+ àti àwọn ààlà ibùgbé tí a gbé kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn,+ 27  fún wọn láti máa wá Ọlọ́run,+ bí wọ́n bá lè táràrà fún un, kí wọ́n sì rí i+ ní ti gidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní ti tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. 28  Nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa ní ìwàláàyè, tí a ń rìn, tí a sì wà,+ àní gẹ́gẹ́ bí àwọn kan lára àwọn akéwì+ láàárín yín ti wí pé, ‘Nítorí àwa pẹ̀lú jẹ́ àtọmọdọ́mọ rẹ̀.’ 29  “Nítorí náà, ní rírí i pé àwa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ọlọ́run,+ kò yẹ kí a lérò pé Olù-Wà Ọ̀run+ rí bí wúrà tàbí fàdákà tàbí òkúta, bí ohun tí a gbẹ́ lére nípasẹ̀ ọnà àti ìdọ́gbọ́nhùmọ̀ ènìyàn.+ 30  Lóòótọ́, Ọlọ́run ti gbójú fo irúfẹ́ àwọn àkókò àìmọ̀+ bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ nísinsìnyí, ó ń sọ fún aráyé pé kí gbogbo wọn níbi gbogbo ronú pìwà dà.+ 31  Nítorí pé ó ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́+ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti yàn sípò, ó sì ti pèsè ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà fún gbogbo ènìyàn ní ti pé ó ti jí i dìde+ kúrò nínú òkú.” 32  Tóò, nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa àjíǹde àwọn òkú, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ẹlẹ́yà,+ nígbà tí àwọn mìíràn wí pé: “Dájúdájú, àwa yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ nípa èyí àní ní ìgbà mìíràn.” 33  Nípa báyìí, Pọ́ọ̀lù jáde kúrò ní àárín wọn, 34  ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan dara pọ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì di onígbàgbọ́, lára wọn pẹ̀lú ni Díónísíù, adájọ́ kan ní kóòtù Áréópágù,+ àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dámárì, àti àwọn mìíràn ní àfikún sí wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé