Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 16:1-40

16  Nítorí náà, ó dé Déébè àti Lísírà+ pẹ̀lú. Sì wò ó! ọmọ ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tímótì,+ ọmọkùnrin obìnrin Júù kan tí ó gbà gbọ́, ṣùgbọ́n tí baba rẹ̀ jẹ́ Gíríìkì,  àwọn ará ní Lísírà àti Íkóníónì sì ròyìn rẹ̀ dáadáa.  Pọ́ọ̀lù sọ ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ jáde pé kí ọkùnrin yìí bá òun jáde lọ, ó sì mú un, ó sì dádọ̀dọ́+ rẹ̀ nítorí àwọn Júù tí wọ́n wà ní àwọn ibi wọnnì, nítorí gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan mọ̀ pé Gíríìkì ni baba rẹ̀.  Wàyí o, bí wọ́n ti ń rin ìrìn àjò la àwọn ìlú ńlá náà já, wọn a fi àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù ti ṣe ìpinnu lé lórí jíṣẹ́ fún àwọn tí ń bẹ níbẹ̀, kí wọ́n lè máa pa wọ́n mọ́.+  Nítorí náà, ní tòótọ́, àwọn ìjọ ń bá a lọ ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́+ àti ní pípọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n gba Fíríjíà àti ilẹ̀ Gálátíà+ kọjá, nítorí pé ẹ̀mí mímọ́ ka sísọ ọ̀rọ̀ náà ní àgbègbè Éṣíà léèwọ̀ fún wọn.  Síwájú sí i, nígbà tí wọ́n dé Máísíà, wọ́n sapá láti lọ sí Bítíníà,+ ṣùgbọ́n ẹ̀mí Jésù kò gbà wọ́n láyè.  Nítorí náà, wọ́n ré Máísíà kọjá, wọ́n sì sọ̀ kalẹ̀ wá sí Tíróásì.+  Ní òru, ìran+ kan sì fara han Pọ́ọ̀lù: ọkùnrin kan ará Makedóníà dúró, ó ń pàrọwà fún un, ó sì wí pé: “Rékọjá wá sí Makedóníà, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.” 10  Wàyí o, gbàrà tí ó ti rí ìran náà, a wá ọ̀nà láti lọ sí Makedóníà,+ ní dídé ìparí èrò náà pé Ọlọ́run ti fi ọlá àṣẹ pè wá láti polongo ìhìn rere fún wọn. 11  Nítorí náà, a ṣíkọ̀ sójú òkun láti Tíróásì, a sì lọ tààrà sí Sámótírásì, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e sí Neapólísì, 12  àti láti ibẹ̀ sí ìlú Fílípì,+ ìlú àtòkèèrè ṣàkóso, èyí tí í ṣe olú ìlú ńlá ní àgbègbè Makedóníà.+ A ń bá a lọ ní wíwà ní ìlú ńlá yìí, ní lílo àwọn ọjọ́ díẹ̀. 13  Ní ọjọ́ sábáàtì, a jáde lọ sẹ́yìn òde ibodè lẹ́bàá odò kan, níbi tí a ń ronú pé ibi àdúrà wà; a sì jókòó, a sì bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn obìnrin tí wọ́n ti pé jọ sọ̀rọ̀. 14  Obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lìdíà, ẹni tí ń ta ohun aláwọ̀ àlùkò, ará ìlú ńlá Tíátírà,+ ẹni tí ó jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run, ó ń fetí sílẹ̀, Jèhófà sì ṣí ọkàn-àyà+ rẹ̀ sílẹ̀ láti fiyè sí àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ. 15  Wàyí o, nígbà tí a batisí òun àti agbo ilé rẹ̀,+ ó sọ pẹ̀lú ìpàrọwà pé: “Bí ẹ bá kà mí sí olùṣòtítọ́ sí Jèhófà, ẹ wọ ilé mi, kí ẹ sì dúró níbẹ̀.”+ Ó sáà mú kí a wá.+ 16  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé bí a ti ń lọ sí ibi àdúrà, ìránṣẹ́bìnrin kan tí ó ní ẹ̀mí kan,+ ẹ̀mí èṣù ìwoṣẹ́,+ pàdé wa. Ó ti máa ń mú èrè+ púpọ̀ wá fún àwọn ọ̀gá rẹ̀ nípa fífi ìsọtẹ́lẹ̀ ṣiṣẹ́ ṣe. 17  Ọmọdébìnrin yìí ń tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àti àwa ṣáá, ó sì ń ké jáde+ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ọkùnrin wọ̀nyí ni ẹrú Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ, àwọn ẹni tí ń kéde ọ̀nà ìgbàlà fún yín.” 18  Èyí ni ó ń ṣe ṣáá fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Níkẹyìn, ó sú Pọ́ọ̀lù,+ ó sì yí padà, ó sì wí fún ẹ̀mí náà pé: “Mo pa àṣẹ fún ọ ní orúkọ Jésù Kristi láti jáde kúrò nínú rẹ̀.”+ Ó sì jáde ní wákàtí yẹn gan-an.+ 19  Tóò, nígbà tí àwọn ọ̀gá rẹ̀ rí i pé ìrètí wọn fún èrè ti lọ,+ wọ́n gbá Pọ́ọ̀lù àti Sílà mú, wọ́n sì wọ́ wọn lọ sí ibi ọjà lọ́dọ̀ àwọn olùṣàkóso,+ 20  bí wọ́n sì ti mú wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn agbófinró ìlú, wọ́n wí pé: “Ọkùnrin wọ̀nyí ń yọ ìlú ńlá wa lẹ́nu+ gan-an ni, ní ti pé Júù ni wọ́n, 21  wọ́n sì ń kéde àwọn àṣà+ tí kò bófin mu fún wa láti tẹ́wọ́ gbà tàbí láti sọ dàṣà, nítorí pé a jẹ́ ará Róòmù.” 22  Ogunlọ́gọ̀ náà sì jùmọ̀ dìde sí wọn; lẹ́yìn tí àwọn agbófinró ìlú sì ya ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn kúrò lára wọn, wọ́n pàṣẹ pé kí a fi ọ̀pá nà wọ́n.+ 23  Lẹ́yìn tí wọ́n ti lù wọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀,+ wọ́n sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n pa àṣẹ pé kí onítúbú sé wọn mọ́.+ 24  Nítorí pé ó gba irúfẹ́ àṣẹ ìtọ́ni bẹ́ẹ̀, ó sọ wọ́n sí ẹ̀wọ̀n inú lọ́hùn-ún,+ ó sì de ẹsẹ̀ wọn pinpin nínú àbà.+ 25  Ṣùgbọ́n ní nǹkan bí àárín òru,+ Pọ́ọ̀lù àti Sílà ń gbàdúrà, wọ́n sì ń fi orin yin Ọlọ́run;+ bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ń gbọ́ wọn. 26  Lójijì ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà kan sẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ìpìlẹ̀ túbú fi mì. Síwájú sí i, gbogbo ilẹ̀kùn ṣí ní ìṣẹ́jú akàn, àwọn ìdè gbogbo wọ́n sì tú.+ 27  Bí onítúbú náà ti jí lójú oorun, tí ó sì rí i pé àwọn ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n ṣí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì ti fẹ́ pa ara rẹ̀,+ ó lérò pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti sá lọ.+ 28  Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù ké ni ohùn rara pé: “Má ṣe ara rẹ lọ́ṣẹ́,+ nítorí pé gbogbo wa wà níhìn-ín!” 29  Nítorí náà, ó béèrè fún ìmọ́lẹ̀, ó sì bẹ́ wọlé àti pé, nítorí tí ìwárìrì mú un, ó wólẹ̀+ níwájú Pọ́ọ̀lù àti Sílà. 30  Ó sì mú wọn wá sóde, ó sì wí pé: “Ẹ̀yin ọ̀gá, kí ni kí n ṣe+ láti rí ìgbàlà?” 31  Wọ́n wí pé: “Gba Jésù Olúwa gbọ́, ìwọ yóò sì rí ìgbàlà,+ ìwọ àti agbo ilé rẹ.”+ 32  Wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún un pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ń bẹ ní ilé rẹ̀.+ 33  Ó sì mú wọn lọ ní wákàtí yẹn ní òru, ó sì wẹ ojú ibi tí a ti nà wọ́n; gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, òun àti àwọn tirẹ̀ ni a sì batisí+ láìjáfara. 34  Ó sì mú wọn wá sínú ilé rẹ̀, ó tẹ́ tábìlì kan níwájú wọn, ó sì yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo agbo ilé rẹ̀, nísinsìnyí tí ó ti gba Ọlọ́run gbọ́. 35  Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn agbófinró+ ìlú rán àwọn akọ́dà lọ láti sọ pé: “Tú ọkùnrin wọnnì sílẹ̀.” 36  Nítorí náà, onítúbú ròyìn ọ̀rọ̀ wọn fún Pọ́ọ̀lù pé: “Àwọn agbófinró ìlú ti rán àwọn ènìyàn wá kí a lè tú ẹ̀yin méjèèjì sílẹ̀. Nítorí náà, nísinsìnyí ẹ jáde wá, kí ẹ sì máa bá ọ̀nà yín lọ ní àlàáfíà.” 37  Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù wí fún wọn pé: “Wọ́n nà wá lẹ́gba ní gbangba láìdá wa lẹ́bi, àwa ọkùnrin tí a jẹ́ ará Róòmù,+ wọ́n sì sọ wá sẹ́wọ̀n; ṣé wọ́n ń tì wá jáde nísinsìnyí ní bòókẹ́lẹ́ ni? Rárá o! ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí àwọn fúnra wọn wá mú wa jáde.” 38  Nítorí náà, àwọn akọ́dà ròyìn àsọjáde wọ̀nyí fún àwọn agbófinró ìlú. Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí ba àwọn wọ̀nyí nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ará Róòmù ni àwọn ọkùnrin náà.+ 39  Nítorí náà, wọ́n wá, wọ́n sì pàrọwà fún wọn, lẹ́yìn mímú wọn jáde, wọ́n sì béèrè pé kí wọ́n lọ kúrò ní ìlú ńlá náà. 40  Ṣùgbọ́n wọ́n jáde kúrò ní ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì lọ sí ilé Lìdíà, nígbà tí wọ́n sì rí àwọn ará, wọ́n fún wọn ní ìṣírí,+ wọ́n sì lọ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé