Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 15:1-41

15  Àwọn ọkùnrin kan sọ̀ kalẹ̀ wá láti Jùdíà,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ará pé: “Láìjẹ́ pé ẹ dádọ̀dọ́+ gẹ́gẹ́ bí àṣà tí Mósè fi lélẹ̀,+ a kò lè gbà yín là.”  Ṣùgbọ́n nígbà tí ìyapa àti ṣíṣe awuyewuye tí kì í ṣe kékeré ti wáyé láti ọ̀dọ̀ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà pẹ̀lú wọn, wọ́n ṣètò pé kí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà àti àwọn mìíràn kan lára wọn gòkè lọ sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù+ nípa awuyewuye yìí.  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, lẹ́yìn tí ìjọ ti sìn wọ́n díẹ̀ dé ọ̀nà,+ àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń bá ọ̀nà wọn lọ la Foníṣíà àti Samáríà já, wọ́n ń ṣèròyìn ní kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìyílọ́kànpadà àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè,+ wọ́n sì ń mú ìdùnnú ńlá bá gbogbo àwọn ará.+  Nígbà tí wọ́n ti dé Jerúsálẹ́mù, ìjọ àti àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin fi inú rere gbà wọ́n,+ wọ́n sì ròyìn àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.+  Síbẹ̀, àwọn kan lára àwọn tí wọ́n jẹ́ ti ẹ̀ya ìsìn àwọn Farisí tí wọ́n ti gbà gbọ́, dìde lórí ìjókòó wọn, wọ́n sì wí pé: “Ó pọn dandan kí wọ́n dádọ̀dọ́+ àti láti pàṣẹ fún wọn láti pa òfin Mósè mọ́.”+  Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin sì kóra jọpọ̀ láti rí sí àlámọ̀rí yìí.+  Wàyí o, nígbà tí ṣíṣe awuyewuye+ púpọ̀ ti wáyé, Pétérù dìde, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, ẹ mọ̀ dunjú pé láti àwọn ọjọ́ ìjímìjí ni Ọlọ́run ti ṣe yíyàn náà láàárín yín pé láti ẹnu mi ni àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè yóò ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìhìn rere, kí wọ́n sì gbà gbọ́;+  Ọlọ́run, ẹni tí ó mọ ọkàn-àyà,+ sì jẹ́rìí nípa fífún wọn ní ẹ̀mí mímọ́,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti fún àwa pẹ̀lú.  Kò sì fi ìyàtọ̀ kankan rárá sí àárín àwa àti àwọn,+ ṣùgbọ́n ó wẹ ọkàn-àyà wọn mọ́ gaara nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.+ 10  Nítorí náà, èé ṣe tí ẹ fi ń dán Ọlọ́run wò nísinsìnyí nípa gbígbé àjàgà+ tí àwọn baba ńlá wa tàbí àwa kò lè rù+ kọ́ ọrùn àwọn ọmọ ẹ̀yìn? 11  Kàkà bẹ́ẹ̀, àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé láti rí ìgbàlà nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ Jésù Olúwa bákan náà bí ti àwọn ènìyàn wọnnì pẹ̀lú.”+ 12  Látàrí èyíinì, gbogbo ògìdìgbó náà pátá dákẹ́ jẹ́ẹ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fetí sílẹ̀ bí Bánábà àti Pọ́ọ̀lù ti ń ṣèròyìn ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti àmì àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ 13  Lẹ́yìn tí wọ́n dẹ́kun sísọ̀rọ̀, Jákọ́bù dáhùn, ó wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, ẹ gbọ́ mi.+ 14  Símíónì+ ti ṣèròyìn ní kínníkínní bí Ọlọ́run ti yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ láti mú àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀ jáde láti inú wọn.+ 15  Ọ̀rọ̀ àwọn Wòlíì sì bá èyí mu, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, 16  ‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, èmi yóò padà, èmi yóò sì tún àtíbàbà Dáfídì tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́; èmi yóò sì tún àwókù rẹ̀ kọ́, èmi yóò sì gbé e nà ró lẹ́ẹ̀kan sí i,+ 17  kí àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára àwọn ènìyàn náà lè fi taratara wá Jèhófà, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ènìyàn tí a fi orúkọ mi pè, ni Jèhófà wí, ẹni tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí,+ 18  tí a mọ̀ láti ìgbà láéláé.’+ 19  Nítorí bẹ́ẹ̀, ìpinnu mi ni pé kí a má ṣe dààmú àwọn tí ń yí padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run láti inú àwọn orílẹ̀-èdè,+ 20  ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé sí wọn láti ta kété sí àwọn ohun tí àwọn òrìṣà+ sọ di eléèérí àti sí àgbèrè+ àti sí ohun tí a fún lọ́rùn pa+ àti sí ẹ̀jẹ̀.+ 21  Nítorí pé láti ìgbàanì ni Mósè ti ní àwọn tí ń wàásù rẹ̀ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá, nítorí a ń kà á sókè nínú àwọn sínágọ́gù ní gbogbo sábáàtì.”+ 22  Nígbà náà ni àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìjọ fara mọ́ rírán àwọn ọkùnrin tí a yàn láti àárín wọn lọ sí Áńtíókù pa pọ̀ pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, èyíinì ni, Júdásì tí a ń pè ní Básábà+ àti Sílà, àwọn ọkùnrin tí ń mú ipò iwájú láàárín àwọn ará; 23  wọ́n sì fi ọwọ́ wọn kọ̀wé pé: “Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin, àwọn ará, sí àwọn ará wọnnì ní Áńtíókù+ àti Síríà àti Sìlíṣíà+ tí wọ́n wá láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè: A kí yín! 24  Níwọ̀n bí a ti gbọ́ pé àwọn kan láti àárín wa ti fi àwọn ọ̀rọ̀ fa ìdààmú bá yín,+ tí wọ́n ń gbìyànjú láti dojú ọkàn yín dé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò fún wọn ní ìtọ́ni èyíkéyìí,+ 25  a ti dé orí ìfìmọ̀ṣọ̀kan,+ a sì ti fara mọ́ yíyan àwọn ọkùnrin tí a óò rán sí yín pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ wa, Bánábà àti Pọ́ọ̀lù,+ 26  àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti jọ̀wọ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ nítorí orúkọ Jésù Kristi Olúwa wa.+ 27  Nítorí náà, àwa ń rán Júdásì àti Sílà bọ̀,+ kí àwọn pẹ̀lú lè fi ọ̀rọ̀ ròyìn àwọn ohun kan náà.+ 28  Nítorí ẹ̀mí mímọ́+ àti àwa fúnra wa ti fara mọ́ ṣíṣàìtún fi ẹrù ìnira+ kankan kún un fún yín, àyàfi nǹkan pípọn dandan wọ̀nyí, 29  láti máa ta kété sí àwọn ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà+ àti sí ẹ̀jẹ̀+ àti sí ohun tí a fún lọ́rùn pa+ àti sí àgbèrè.+ Bí ẹ bá fi tìṣọ́ra-tìṣọ́ra pa ara yín mọ́ kúrò nínú nǹkan wọ̀nyí,+ ẹ óò láásìkí. Kí ara yín ó le o!” 30  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, nígbà tí a jẹ́ kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ, wọ́n sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Áńtíókù, wọ́n sì kó ògìdìgbó jọpọ̀, wọ́n sì fi lẹ́tà náà lé wọn lọ́wọ́.+ 31  Lẹ́yìn tí wọ́n kà á, wọ́n yọ̀ nítorí ìṣírí náà.+ 32  Níwọ̀n bí àwọn fúnra wọn sì ti jẹ́ wòlíì+ pẹ̀lú, Júdásì àti Sílà fi ọ̀pọ̀ àwíyé fún àwọn ará ní ìṣírí wọ́n sì fún wọn lókun.+ 33  Nítorí náà, nígbà tí wọ́n ti lo àkókò díẹ̀, àwọn ará jẹ́ kí wọ́n lọ ní àlàáfíà+ sọ́dọ̀ àwọn tí ó ti rán wọn jáde. 34  —— 35  Bí ó ti wù kí ó rí, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn pẹ̀lú, ń bá a lọ ní lílo àkókò ní Áńtíókù+ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere ọ̀rọ̀ Jèhófà.+ 36  Wàyí o, lẹ́yìn àwọn ọjọ́ díẹ̀, Pọ́ọ̀lù wí fún Bánábà pé: “Lékè ohun gbogbo, jẹ́ kí a padà lọ bẹ àwọn ará wò ní gbogbo ìlú ńlá tí a ti kéde ọ̀rọ̀ Jèhófà fáyé gbọ́, láti rí bí wọ́n ṣe wà.”+ 37  Ní tirẹ̀, Bánábà pinnu láti mú Jòhánù pẹ̀lú dání, ẹni tí a ń pè ní Máàkù.+ 38  Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù kò ronú pé ó bẹ́tọ̀ọ́ mu láti mú ẹni yìí dání pẹ̀lú wọn, nítorí pé ó fi wọ́n sílẹ̀ láti Panfílíà,+ kò sì bá wọn lọ sẹ́nu iṣẹ́. 39  Látàrí èyí, ìbújáde ìbínú mímúná wáyé, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n pínyà kúrò lọ́dọ̀ ara wọn; Bánábà+ mú Máàkù dání, ó sì ṣíkọ̀ lọ sí Kípírù.+ 40  Pọ́ọ̀lù yan Sílà,+ ó sì lọ lẹ́yìn tí àwọn ará ti fi í sábẹ́ ìtọ́jú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà.+ 41  Ṣùgbọ́n ó la Síríà àti Sìlíṣíà já, ó ń fún àwọn ìjọ lókun.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé