Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣe 14:1-28

14  Wàyí o, ní Íkóníónì,+ wọ́n jùmọ̀ wọ sínágọ́gù+ àwọn Júù, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ní irúfẹ́ ọ̀nà tí ó fi jẹ́ pé ògìdìgbó ńlá àwọn Júù àti Gíríìkì+ di onígbàgbọ́.  Ṣùgbọ́n àwọn Júù tí kò gbà gbọ́ ru ọkàn àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè sókè,+ wọ́n sì ní ipa tí kò tọ́ lórí wọn lòdì sí àwọn arákùnrin.+  Nítorí náà, wọ́n lo àkókò gígùn ní sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú àìṣojo nípasẹ̀ ọlá àṣẹ Jèhófà, ẹni tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ nípa yíyọ̀ǹda kí àwọn iṣẹ́ àmì àti àmì àgbàyanu máa ṣẹlẹ̀ láti ọwọ́ wọn.+  Bí ó ti wù kí ó rí, ògìdìgbó ìlú ńlá náà pínyà sí méjì, àwọn kan sì wà fún àwọn Júù ṣùgbọ́n àwọn mìíràn fún àwọn àpọ́sítélì.  Wàyí o, nígbà tí ìgbìdánwò lílenípá ṣẹlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn Júù pẹ̀lú àwọn olùṣàkóso wọn, láti hùwà sí wọn lọ́nà àfojúdi àti láti sọ wọ́n ní òkúta,+  nígbà tí a sọ fún wọn nípa èyí, wọ́n sá lọ+ sí àwọn ìlú ńlá Likaóníà, Lísírà àti Déébè àti ìgbèríko tí ń bẹ ní àyíká;  wọ́n sì ń polongo ìhìn rere+ níbẹ̀.  Wàyí o, ní Lísírà, ọkùnrin kan wà tí ó jókòó, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ rọ, ó yarọ láti inú ilé ọlẹ̀+ ìyá rẹ̀, kò sì tíì rìn rí rárá.  [Ọkùnrin] yìí ń fetí sílẹ̀ bí Pọ́ọ̀lù ti ń sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ pé, bí ó ti tẹjú mọ́ ọn, tí ó sì rí i pé ó ní ìgbàgbọ́+ pé a lè mú òun lára dá, 10  ó wí pẹ̀lú ohùn rara pé: “Dìde nà ró ṣánṣán lórí ẹsẹ̀ rẹ.” Ó fò sókè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn.+ 11  Nígbà tí wọ́n rí ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe, àwọn ogunlọ́gọ̀ náà gbé ohùn wọn sókè, wọ́n wí ní ahọ́n Likaóníà pé: “Àwọn ọlọ́run+ ti dà bí ẹ̀dá ènìyàn, wọ́n sì ti sọ̀ kalẹ̀ tọ̀ wá wá!” 12  Wọ́n sì ń pe Bánábà ní Súúsì, ṣùgbọ́n wọ́n ń pe Pọ́ọ̀lù ní Hẹ́mísì, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé òun ni ó ń mú ipò iwájú nínú ọ̀rọ̀ sísọ. 13  Àlùfáà Súúsì, tí tẹ́ńpìlì rẹ̀ wà ní àtidé ìlú ńlá náà, mú àwọn akọ màlúù àti òdòdó ẹ̀yẹ wá sí ibodè, ó sì fẹ́ láti rú àwọn ẹbọ+ pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ náà. 14  Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí àwọn àpọ́sítélì náà Bánábà àti Pọ́ọ̀lù gbọ́ nípa èyí, wọ́n fa ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn ya, wọ́n sì fò sáàárín ogunlọ́gọ̀ náà, wọ́n ń ké jáde, 15  wọ́n sì wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, èé ṣe tí ẹ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn+ tí ó ní àwọn àìlera+ kan náà tí ẹ̀yin ní, a sì ń polongo ìhìn rere fún yín, kí ẹ lè yí padà kúrò nínú ohun asán+ wọ̀nyí sọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè,+ ẹni tí ó ṣe ọ̀run+ àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti gbogbo ohun tí ń bẹ nínú wọn. 16  Ní àwọn ìran tí ó ti kọjá, ó gba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láyè láti máa bá a lọ ní ọ̀nà wọn,+ 17  bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní tòótọ́, kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láìsí ẹ̀rí ní ti pé ó ṣe rere,+ ó ń fún yín ní òjò+ láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà yín dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”+ 18  Síbẹ̀, nípa sísọ nǹkan wọ̀nyí, agbára káká ni wọ́n fi ṣèdíwọ́ fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà láti má ṣe rúbọ sí wọn. 19  Ṣùgbọ́n àwọn Júù dé láti Áńtíókù àti Íkóníónì, wọ́n yí àwọn ogunlọ́gọ̀+ náà lérò padà, wọ́n sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta, wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú ńlá náà, wọ́n lérò pé ó ti kú.+ 20  Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yí i ká, ó dìde, ó sì wọ ìlú ńlá náà. Ní ọjọ́ kejì, òun pẹ̀lú Bánábà lọ sí Déébè.+ 21  Àti pé lẹ́yìn pípolongo ìhìn rere fún ìlú ńlá yẹn àti sísọ àwọn púpọ̀ díẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn,+ wọ́n padà sí Lísírà àti Íkóníónì àti sí Áńtíókù, 22  wọ́n ń fún ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn lókun,+ wọ́n ń fún wọn ní ìṣírí láti dúró nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì wí pé: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.”+ 23  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n yan àwọn àgbà ọkùnrin+ sípò fún wọn nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan àti pé, ní gbígba àdúrà pẹ̀lú àwọn ààwẹ̀,+ wọ́n fi wọ́n lé Jèhófà lọ́wọ́,+ ẹni tí wọ́n ti di onígbàgbọ́ nínú rẹ̀. 24  Wọ́n sì la Písídíà kọjá, wọ́n sì wá sí Panfílíà,+ 25  àti pé, lẹ́yìn sísọ ọ̀rọ̀ náà ní Pẹ́gà, wọ́n sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Atalíà. 26  Láti ibẹ̀, wọ́n ṣíkọ̀ lọ sí Áńtíókù,+ níbi tí a ti fi wọ́n sábẹ́ ìtọ́jú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run fún iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe ní kíkún.+ 27  Nígbà tí wọ́n dé, tí wọ́n sì ti kó ìjọ jọpọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣèròyìn+ ọ̀pọ̀ ohun tí Ọlọ́run ti tipasẹ̀ wọn ṣe, àti pé ó ti ṣí ilẹ̀kùn ìgbàgbọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè.+ 28  Nítorí náà, wọ́n lo àkókò tí kì í ṣe kékeré pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé