Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣe 13:1-52

13  Wàyí o, ní Áńtíókù, àwọn wòlíì+ àti àwọn olùkọ́ wà nínú ìjọ àdúgbò, Bánábà àti Símíónì tí a ń pè ní Nígérì, àti Lúkíọ́sì+ ará Kírénè, àti Mánáénì ẹni tí ó gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ pẹ̀lú Hẹ́rọ́dù olùṣàkóso àgbègbè náà, àti Sọ́ọ̀lù.  Bí wọ́n ti ń ṣèránṣẹ́+ fún Jèhófà ní gbangba, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ wí pé: “Nínú gbogbo ènìyàn, ẹ ya Bánábà àti Sọ́ọ̀lù+ sọ́tọ̀ gedegbe fún mi fún iṣẹ́ tí mo pè wọ́n sí.”  Nígbà náà ni wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́+ lé wọn, wọ́n sì jẹ́ kí wọn lọ.  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, tí ẹ̀mí mímọ́ rán jáde, sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Séléúkíà, wọ́n sì ṣíkọ̀ láti ibẹ̀ lọ sí Kípírù.  Nígbà tí wọ́n sì wà ní Sálámísì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú àwọn sínágọ́gù àwọn Júù. Jòhánù+ pẹ̀lú wà lọ́dọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ẹmẹ̀wà.  Nígbà tí wọ́n ti la gbogbo erékùṣù náà já títí dé Páfò, wọ́n bá ọkùnrin kan pàdé, tí ó jẹ́ oníṣẹ́ oṣó, wòlíì èké,+ Júù kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Baa-Jésù,  ó sì wà pẹ̀lú alákòóso ìbílẹ̀ náà Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, ọkùnrin onílàákàyè. Ní pípe Bánábà àti Sọ́ọ̀lù sọ́dọ̀ ara rẹ̀, [ọkùnrin] yìí fi taratara wá ọ̀nà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.  Ṣùgbọ́n Élímà oníṣẹ́ oṣó náà (èyíinì, ní ti tòótọ́, ni ọ̀nà tí a gbà túmọ̀ orúkọ rẹ̀) bẹ̀rẹ̀ sí takò wọ́n,+ ó ń wá ọ̀nà láti yí alákòóso ìbílẹ̀ náà kúrò nínú ìgbàgbọ́.  Bí Sọ́ọ̀lù, ẹni tí ó tún ń jẹ́ Pọ́ọ̀lù, ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó tẹjú mọ́ ọn, 10  ó sì wí pé: “Ìwọ ọkùnrin tí ó kún fún gbogbo onírúurú jìbìtì àti gbogbo onírúurú ìwà aṣa, ìwọ ọmọ Èṣù,+ ìwọ ọ̀tá ohun gbogbo tí ó jẹ́ òdodo, ṣé ìwọ kò ní ṣíwọ́ fífi èrú yí àwọn ọ̀nà títọ́ Jèhófà po ni? 11  Tóò, nígbà náà, wò ó! ọwọ́ Jèhófà ń bẹ lára rẹ, ìwọ yóò sì fọ́jú, láìrí ìmọ́lẹ̀ oòrùn fún sáà àkókò kan.” Ní ìṣẹ́jú akàn, ìkùukùu ṣíṣúdùdù àti òkùnkùn ṣú bò ó, ó sì lọ yí ká, ó ń wá àwọn ènìyàn láti mú òun lọ́wọ́ lọ.+ 12  Nígbà náà ni alákòóso ìbílẹ̀,+ ní rírí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, di onígbàgbọ́, níwọ̀n bí háà ti ṣe é sí ẹ̀kọ́ Jèhófà. 13  Wàyí o, àwọn ènìyàn náà, pa pọ̀ pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, ṣíkọ̀ sójú òkun láti Páfò, wọ́n sì dé Pẹ́gà ní Panfílíà.+ Ṣùgbọ́n Jòhánù+ fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà+ sí Jerúsálẹ́mù. 14  Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n tẹ̀ síwájú láti Pẹ́gà, wọ́n sì wá sí Áńtíókù ní Písídíà, bí wọ́n sì ti wọ sínágọ́gù+ ní ọjọ́ sábáàtì, wọ́n mú ìjókòó. 15  Lẹ́yìn kíka Òfin+ àti ìwé àwọn Wòlíì ní gbangba, àwọn alága+ sínágọ́gù ránṣẹ́ sí wọn, pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, bí ọ̀rọ̀ ìṣírí èyíkéyìí bá wà tí ẹ ní fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́.” 16  Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù dìde, bí ó sì ti ju+ ọwọ́ rẹ̀, ó wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì àti ẹ̀yin yòókù tí ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ gbọ́.+ 17  Ọlọ́run àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì yìí yan àwọn baba ńlá wa, ó sì gbé àwọn ènìyàn náà ga ní àkókò tí wọ́n ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì, ó sì mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀ pẹ̀lú apá ríròkè.+ 18  Fún sáà tí ó tó nǹkan bí ogójì ọdún+ ni ó sì fi fara da ìṣesí wọn ní aginjù. 19  Lẹ́yìn pípa orílẹ̀-èdè méje run ní ilẹ̀ Kénáánì, ó fi kèké pín ilẹ̀ náà fún wọn:+ 20  gbogbo èyíinì láàárín nǹkan bí irínwó ó lé àádọ́ta ọdún. “Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ó fún wọn ní àwọn onídàájọ́ títí di ìgbà Sámúẹ́lì wòlíì.+ 21  Ṣùgbọ́n láti ìgbà náà lọ, wọ́n fi dandan béèrè fún ọba,+ Ọlọ́run sì fún wọn ní Sọ́ọ̀lù ọmọkùnrin Kíṣì, ọkùnrin kan láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,+ fún ogójì ọdún. 22  Lẹ́yìn tí ó sì mú un kúrò,+ ó gbé Dáfídì dìde fún wọn gẹ́gẹ́ bí ọba,+ ẹni tí ó jẹ́rìí nípa rẹ̀, tí ó sì wí pé, ‘Èmi ti rí Dáfídì ọmọkùnrin Jésè,+ ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà mi lọ́rùn,+ ẹni tí yóò ṣe gbogbo ohun tí mo fẹ́.’+ 23  Láti inú ọmọ+ ọkùnrin yìí, ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, ni Ọlọ́run ti mú olùgbàlà+ kan, Jésù, wá fún Ísírẹ́lì, 24  lẹ́yìn tí Jòhánù,+ ṣáájú ìwọlé dé Ẹni+ yẹn, ti wàásù ní gbangba fún gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì nípa ìbatisí gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìrònúpìwàdà. 25  Ṣùgbọ́n bí Jòhánù ti ń mú ipa ọ̀nà rẹ̀ ṣẹ, òun a sọ pé, ‘Kí ni ẹ rò pé mo jẹ́? Èmi kọ́ ni ẹni náà. Ṣùgbọ́n, wò ó! ẹnì kan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, sálúbàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó láti tú.’+ 26  “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, ẹ̀yin ọmọ ìlà ìran Ábúráhámù àti àwọn yòókù wọnnì láàárín yín tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí ni a ti rán jáde sí wa.+ 27  Nítorí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù àti àwọn olùṣàkóso wọn kò mọ Ẹni+ yìí, ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́, wọ́n mú àwọn ohun tí a sọ láti ẹnu àwọn Wòlíì+ ṣẹ, àwọn ohun tí a ń kà sókè ní gbogbo Sábáàtì, 28  bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò rí ìdí kankan fún ikú,+ wọ́n fi dandan béèrè lọ́wọ́ Pílátù pé kí a fi ikú pa á.+ 29  Wàyí o, nígbà tí wọ́n ṣàṣeparí ohun gbogbo tí a kọ̀wé nípa rẹ̀,+ wọ́n gbé e sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí òpó igi,+ wọ́n sì tẹ́ ẹ sínú ibojì ìrántí+ kan. 30  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú òkú;+ 31  fún ọjọ́ púpọ̀, ó di rírí fún àwọn tí wọ́n ti bá a gòkè láti Gálílì lọ sí Jerúsálẹ́mù, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsìnyí fún àwọn ènìyàn.+ 32  “Nítorí náà, ìhìn rere nípa ìlérí tí a ṣe fún àwọn baba ńlá+ ni àwa sì ń polongo fún yín, 33  pé Ọlọ́run ti mú un ṣẹ pátápátá fún àwa ọmọ wọn ní ti pé ó jí Jésù dìde;+ àní gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ nínú sáàmù kejì pé, ‘Ìwọ ni ọmọ mi, mo ti di Baba rẹ lónìí yìí.’+ 34  Òtítọ́ yẹn pé ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí a sì yàn án tẹ́lẹ̀ pé kì yóò tún padà sínú ìdíbàjẹ́ mọ́, ni òun ti sọ ní ọ̀nà yìí pé, ‘Dájúdájú, èmi yóò fún yín ní àwọn inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí Dáfídì, àwọn èyí tí ó ṣeé gbíyè lé.’+ 35  Nítorí bẹ́ẹ̀, ó tún sọ nínú sáàmù mìíràn pé, ‘Ìwọ kì yóò jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́.’+ 36  Nítorí Dáfídì,+ ní ọwọ́ kan, ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tí a fi hàn kedere ní ìran tirẹ̀, ó sì sùn nínú ikú, a sì tẹ́ ẹ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, ó sì rí ìdíbàjẹ́ ní tòótọ́.+ 37  Ní ọwọ́ kejì, ẹni tí Ọlọ́run gbé dìde kò rí ìdíbàjẹ́.+ 38  “Nítorí náà, kí ó di mímọ̀ fún yín, ẹ̀yin ará, pé nípasẹ̀ Ẹni yìí ni a fi ń kéde ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ fún yín;+ 39  àti pé nínú gbogbo ohun tí a kò ti lè polongo yín ní aláìjẹ̀bi nípasẹ̀ òfin Mósè,+ gbogbo ẹni tí ó bá gbà gbọ́ ni a ń polongo ní aláìjẹ̀bi nípasẹ̀ Ẹni yìí.+ 40  Nítorí náà, ẹ rí i pé ohun tí a sọ nínú ìwé àwọn Wòlíì kò wá sórí yín, 41  ‘Ẹ kíyè sí i, ẹ̀yin pẹ̀gànpẹ̀gàn, kí ó ṣe yín ní kàyéfì, kí ẹ sì pòórá dànù, nítorí pé èmi ń ṣe iṣẹ́ kan ní àwọn ọjọ́ yín, iṣẹ́ kan tí ẹ kì yóò gbà gbọ́ lọ́nàkọnà bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ ṣèròyìn rẹ̀ fún yín ní kúlẹ̀kúlẹ̀.’”+ 42  Wàyí o, nígbà tí wọ́n ń jáde lọ, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí pàrọwà pé kí a sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn ní sábáàtì tí ó tẹ̀ lé e.+ 43  Nítorí náà, lẹ́yìn tí wọ́n tú àpéjọ sínágọ́gù ká, ọ̀pọ̀ àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà,+ àwọn tí ó jẹ́ pé ní bíbá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀+ wọ́n láti máa bá a lọ nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.+ 44  Ní sábáàtì tí ó tẹ̀ lé e, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìlú ńlá náà ni ó kóra jọpọ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.+ 45  Nígbà tí àwọn Júù tajú kán rí àwọn ogunlọ́gọ̀ náà, wọ́n kún fún owú,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàtakò lọ́nà ìsọ̀rọ̀ òdì sí àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ.+ 46  Nítorí náà, ní fífi àìṣojo sọ̀rọ̀, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wí pé: “Ó pọn dandan kí a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín.+ Níwọ̀n bí ẹ ti ń sọ́gọ rẹ̀ dànù+ kúrò lọ́dọ̀ yín, tí ẹ kò sì ka ara yín yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó! a yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè.+ 47  Ní ti tòótọ́, Jèhófà ti pàṣẹ fún wa ní ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé, ‘Mo ti yàn ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+ fún ọ láti jẹ́ ìgbàlà títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.’”+ 48  Nígbà tí àwọn tí í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀, wọ́n sì ń yin ọ̀rọ̀ Jèhófà+ lógo, gbogbo àwọn tí wọ́n sì ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun di onígbàgbọ́.+ 49  Síwájú sí i, ọ̀rọ̀ Jèhófà ni a ń mú lọ sí gbogbo ilẹ̀ náà.+ 50  Ṣùgbọ́n àwọn Júù+ ru àwọn obìnrin tí ó ní ìsì rere sókè, àwọn tí ń jọ́sìn Ọlọ́run àti àwọn ọkùnrin sàràkí-sàràkí ìlú ńlá náà, wọ́n sì gbé inúnibíni+ dìde sí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n sì jù wọ́n sí ẹ̀yìn òde ààlà wọn. 51  Àwọn wọ̀nyí gbọn ekuru ẹsẹ̀ wọn dànù lòdì sí wọn,+ wọ́n sì lọ sí Íkóníónì. 52  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń bá a lọ ní kíkún fún ìdùnnú+ àti ẹ̀mí mímọ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé