Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣe 12:1-25

12  Ní nǹkan bí àkókò yẹn gan-an, Hẹ́rọ́dù ọba na ọwọ́ rẹ̀ sí fífojú àwọn kan lára àwọn tí ó jẹ́ ti ìjọ gbolẹ̀.+  Ó fi idà+ pa Jákọ́bù arákùnrin Jòhánù.+  Bí ó ti rí i pé ó dùn mọ́ àwọn Júù nínú,+ ó tẹ̀ síwájú láti fi àṣẹ ọba mú Pétérù pẹ̀lú. (Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́, ọjọ́ wọnnì jẹ́ ọjọ́ àkàrà aláìwú.)+  Bí ó sì ti gbá a mú, ó fi í sẹ́wọ̀n,+ ó fi í sábẹ́ ọ̀wọ́ mẹ́rin àwọn oníṣẹ́ àṣegbà tí ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan ní ọmọ ogun mẹ́rin-mẹ́rin nínú láti máa ṣọ́ ọ, níwọ̀n bí ó ti pète-pèrò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn náà lẹ́yìn ìrékọjá.+  Nítorí náà, Pétérù ni a pa mọ́ sínú ẹ̀wọ̀n; ṣùgbọ́n ìjọ ń gbàdúrà+ lọ́nà gbígbónájanjan sí Ọlọ́run nítorí rẹ̀.  Wàyí o, nígbà tí Hẹ́rọ́dù fẹ́ mú un jáde, ní òru yẹn Pétérù ń sùn ní dídè pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n méjì láàárín ọmọ ogun méjì, àwọn ẹ̀ṣọ́ lẹ́nu ilẹ̀kùn sì ń ṣọ́ ẹ̀wọ̀n náà.  Ṣùgbọ́n, wò ó! áńgẹ́lì Jèhófà dúró+ nítòsí, ìmọ́lẹ̀ kan sì tàn nínú kòlòmákò ẹ̀wọ̀n náà. Ní gbígbá Pétérù pẹ́pẹ́ ní ẹ̀gbẹ́, ó ta á jí,+ ó wí pé: “Dìde kíákíá!” Àwọn ẹ̀wọ̀n rẹ̀ sì bọ́+ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.  Áńgẹ́lì+ náà wí fún un pé: “Di ara rẹ lámùrè, sì de sálúbàtà rẹ.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀. Níkẹyìn, ó wí fún un pé: “Gbé ẹ̀wù àwọ̀lékè+ rẹ wọ̀, kí o sì máa tẹ̀ lé mi.”  Ó sì jáde, ó sì ń tẹ̀ lé e, ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ áńgẹ́lì náà jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ gidi. Ní tòótọ́, ó rò pé ìran ni òun ń rí.+ 10  Ní kíkọjá ẹ̀ṣọ́ ológun kìíní àti èkejì, wọ́n dé ibi ẹnubodè onírin tí ó lọ sí ìlú ńlá náà, èyí sì fúnra rẹ̀ ṣí sílẹ̀ fún wọn.+ Lẹ́yìn tí wọ́n sì jáde, wọ́n tẹ̀ síwájú lọ sísàlẹ̀ ojú pópó kan, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, áńgẹ́lì náà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 11  Bí ojú Pétérù sì ti ń wálẹ̀, ó wí pé: “Nísinsìnyí, mo mọ̀ ní ti gidi pé Jèhófà rán áńgẹ́lì rẹ̀ jáde,+ ó sì dá mi nídè+ kúrò lọ́wọ́ Hẹ́rọ́dù àti kúrò nínú gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń fojú sọ́nà fún.” 12  Lẹ́yìn tí ó sì ti ronú nípa rẹ̀, ó lọ sí ilé Màríà ìyá Jòhánù tí a fún ní orúkọ àpèlé náà Máàkù,+ níbi tí àwọn púpọ̀ díẹ̀ kóra jọpọ̀ sí, tí wọ́n sì ń gbàdúrà. 13  Nígbà tí ó kan ilẹ̀kùn ojú ọ̀nà àbáwọlé, ìránṣẹ́bìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ródà wá jẹ́ ìpè náà, 14  nígbà tí ó sì mọ̀ dájú pé ohùn Pétérù ni, kò ṣí ilẹ̀kùn àbáwọlé nítorí ìdùnnú, ṣùgbọ́n ó sáré wọlé, ó sì ròyìn pé Pétérù dúró ní ojú ọ̀nà àbáwọlé. 15  Wọ́n wí fún un pé: “Orí rẹ dà rú.” Ṣùgbọ́n ó ń tẹnu mọ́ ọn kíkankíkan pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Áńgẹ́lì rẹ̀ ni.”+ 16  Ṣùgbọ́n Pétérù dúró níbẹ̀ ó ń kànkùn. Nígbà tí wọ́n ṣílẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yà wọ́n. 17  Ṣùgbọ́n ó juwọ́+ sí wọn pé kí wọ́n dákẹ́, ó sì sọ fún wọn ní kúlẹ̀kúlẹ̀ bí Jèhófà ṣe mú òun jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n, ó sì wí pé: “Ẹ ròyìn nǹkan wọ̀nyí fún Jákọ́bù+ àti àwọn ará.” Pẹ̀lú èyíinì, ó jáde lọ, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ibòmíràn. 18  Tóò, nígbà tí ilẹ̀ mọ́,+ kì í ṣe ìsásókèsódò kékeré ni ó wà láàárín àwọn ọmọ ogun ní ti ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Pétérù ní ti gidi. 19  Hẹ́rọ́dù+ wá a kiri taápọn-taápọn, nígbà tí kò sì rí i, ó wádìí àwọn ẹ̀ṣọ́ náà wò, ó sì pàṣẹ pé kí a mú wọn lọ fún ìjẹníyà;+ ó sì sọ̀ kalẹ̀ láti Jùdíà lọ sí Kesaréà, ó sì lo àkókò díẹ̀ níbẹ̀. 20  Wàyí o, ẹ̀mí ìjà ń gùn ún lòdì sí àwọn ènìyàn Tírè àti Sídónì. Nítorí náà, pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n sì ti yí Bílásítù lérò padà, ẹni tí ń ṣe àbójútó ìyẹ̀wù ibùsùn ọba, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́wọ́ ẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí láti ilẹ̀ ti ọba ni a ti ń pèsè oúnjẹ+ fún ilẹ̀ tiwọn. 21  Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan tí a dá, Hẹ́rọ́dù gbé aṣọ ìgúnwà wọ̀, ó jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọyé fún wọn ní gbangba. 22  Ẹ̀wẹ̀, àwọn ènìyàn tí ó pé jọ bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé: “Ohùn ọlọ́run kan ni, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!”+ 23  Ní ìṣẹ́jú akàn, áńgẹ́lì Jèhófà kọlù ú,+ nítorí pé kò fi ògo fún Ọlọ́run;+ àwọn kòkòrò mùkúlú sì jẹ ẹ́, ó sì gbẹ́mìí mì. 24  Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀+ Jèhófà ń bá a lọ ní gbígbilẹ̀ àti ní títànkálẹ̀.+ 25  Ní ti Bánábà+ àti Sọ́ọ̀lù, lẹ́yìn tí wọ́n ti parí iṣẹ́ ní kíkún lórí ìpèsè a-dín-ìṣòro-kù+ ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n padà, wọ́n sì mú Jòhánù+ dání pẹ̀lú wọn, ẹni tí a fún ní orúkọ àpèlé náà Máàkù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé