Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣe 11:1-30

11  Wàyí o, àwọn àpọ́sítélì àti àwọn ará tí wọ́n wà ní Jùdíà gbọ́ pé àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè+ pẹ̀lú ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.  Nítorí náà, nígbà tí Pétérù gòkè wá sí Jerúsálẹ́mù, àwọn alátìlẹyìn ìdádọ̀dọ́+ bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣàríyànjiyàn,  wọ́n wí pé ó ti wọ ilé àwọn ọkùnrin tí kò dádọ̀dọ́, ó sì ti bá wọn jẹun.  Látàrí èyí, Pétérù bẹ̀rẹ̀, ó sì ń bá a lọ láti ṣàlàyé kókó kọ̀ọ̀kan fún wọn, pé:  “Mo wà ní ìlú ńlá Jópà, mo ń gbàdúrà, mo sì rí ìran kan nínú ojúran, irú ohun èlò kan tí ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ bí aṣọ ọ̀gbọ̀ ńlá tí a ń fi àwọn igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ rọ̀ ọ́ wálẹ̀ láti ọ̀run, ó sì wá títí dé ọ̀dọ̀ mi.  Ní títẹjú mọ́ inú rẹ̀, mo ṣe àkíyèsí, mo sì rí àwọn ẹ̀dá ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹranko ìgbẹ́ àti àwọn ohun tí ń rákò àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, mo gbọ́ tí ohùn kan sọ fún mi pé, ‘Dìde, Pétérù, máa pa, kí o sì máa jẹ!’+  Ṣùgbọ́n mo wí pé, ‘Rárá o, Olúwa, nítorí ohun tí ó jẹ́ ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́ kò wọ ẹnu mi rí.’+  Ní ìgbà kejì, ohùn náà láti ọ̀run dáhùn pé, ‘Ìwọ dẹ́kun pípe àwọn ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.’+ 10  Èyí ṣẹlẹ̀ ní ìgbà kẹta, a sì tún fa gbogbo rẹ̀ sókè sí ọ̀run.+ 11  Pẹ̀lúpẹ̀lù, wò ó! ní ìṣẹ́jú yẹn àwọn ọkùnrin mẹ́ta dúró síbi ilé tí a wà, a rán wọn sí mi láti Kesaréà.+ 12  Nítorí náà, ẹ̀mí+ sọ fún mi pé kí n bá wọn lọ, láìṣiyèméjì rárá. Ṣùgbọ́n arákùnrin mẹ́fà wọ̀nyí bá mi lọ pẹ̀lú, a sì wọ ilé ọkùnrin náà.+ 13  “Ó ròyìn fún wa bí òun ṣe rí áńgẹ́lì tí ó dúró ní ilé òun tí ó sì wí pé, ‘Rán àwọn ènìyàn lọ sí Jópà, kí o sì ránṣẹ́ pe Símónì tí a fún ní orúkọ àpèlé náà Pétérù,+ 14  òun yóò sì sọ nǹkan wọnnì fún ọ nípasẹ̀ èyí tí ìwọ àti gbogbo agbo ilé rẹ fi lè rí ìgbàlà.’+ 15  Ṣùgbọ́n nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ẹ̀mí mímọ́ bà lé wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti bà lé wa ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.+ 16  Látàrí èyí, mo rántí àsọjáde Olúwa, bí ó ti máa ń wí pé, ‘Jòhánù, ní tirẹ̀, fi omi batisí,+ ṣùgbọ́n a ó batisí yín nínú ẹ̀mí mímọ́.’+ 17  Nítorí náà, bí Ọlọ́run bá fi ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti fi fún wa pẹ̀lú, àwa tí a ti gba Jésù Kristi Olúwa gbọ́,+ ta ni èmi tí èmi yóò fi lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́?”+ 18  Wàyí o, nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n gbà láìjanpata,+ wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo,+ pé: “Tóò, nígbà náà, Ọlọ́run ti yọ̀ǹda ìrònúpìwàdà fún ète ìyè fún àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú.”+ 19  Nítorí náà, àwọn tí a ti tú ká+ nípasẹ̀ ìpọ́njú tí ó dìde nítorí Sítéfánù ré kọjá lọ títí dé Foníṣíà+ àti Kípírù+ àti Áńtíókù, ṣùgbọ́n wọn kò sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹnì kankan àyàfi àwọn Júù nìkan.+ 20  Àmọ́ ṣá o, lára wọn, àwọn ará Kípírù àti ará Kírénè kan wà, tí wọ́n wá sí Áńtíókù, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè Gíríìkì+ sọ̀rọ̀, tí wọ́n ń polongo ìhìn rere Jésù Olúwa.+ 21  Síwájú sí i, ọwọ́ Jèhófà+ wà pẹ̀lú wọn, iye púpọ̀ tí ó di onígbàgbọ́ sì yí padà sọ́dọ̀ Olúwa.+ 22  Ìròyìn nípa wọ́n dé etí-ìgbọ́ ìjọ tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì rán Bánábà+ lọ títí dé Áńtíókù. 23  Nígbà tí ó dé, tí ó sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ Ọlọ́run, ó yọ̀,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fún gbogbo wọn ní ìṣírí láti máa bá a lọ nínú Olúwa pẹ̀lú ète àtọkànwá;+ 24  nítorí ó jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún ẹ̀mí mímọ́ àti ìgbàgbọ́. Ogunlọ́gọ̀ tí ó pọ̀ ni a sì fi kún Olúwa.+ 25  Nítorí náà, ó lọ sí Tásù+ láti wá Sọ́ọ̀lù+ kiri dáadáa, 26  lẹ́yìn tí ó sì rí i, ó mú un wá sí Áńtíókù. Ó wá tipa bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé, fún odindi ọdún kan, wọ́n kóra jọpọ̀ pẹ̀lú wọn nínú ìjọ, wọ́n sì kọ́ ogunlọ́gọ̀ tí ó jọjú, Áńtíókù sì ni a ti kọ́kọ́ tipasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Kristẹni.+ 27  Wàyí o, ní ọjọ́ wọ̀nyí, àwọn wòlíì+ sọ̀ kalẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù wá sí Áńtíókù. 28  Ọ̀kan lára wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ágábù+ dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi hàn nípasẹ̀ ẹ̀mí pé ìyàn ńlá máa tó mú gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá;+ èyí tí ó ṣẹlẹ̀, ní ti tòótọ́, ní àkókò Kíláúdíù. 29  Nítorí náà, àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn pinnu, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí agbára olúkúlùkù ti lè gbé e,+ láti fi ìpèsè a-dín-ìṣòro-kù+ ránṣẹ́ sí àwọn ará tí ń gbé ní Jùdíà; 30  èyí ni wọ́n sì ṣe, wọ́n fi í ránṣẹ́ sí àwọn àgbà ọkùnrin láti ọwọ́ Bánábà àti Sọ́ọ̀lù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé