Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣe 10:1-48

10  Wàyí o, ní Kesaréà, ọkùnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kọ̀nílíù, ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun+ ti àwùjọ ọmọ ogun Ítálì,+ gẹ́gẹ́ bí a ti ń pè é,  olùfọkànsìn+ àti ẹnì kan tí ó bẹ̀rù+ Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbo ilé rẹ̀, ó sì ń fi ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn àánú fún àwọn ènìyàn,+ ó sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run nígbà gbogbo.+  Ní nǹkan bí wákàtí kẹsàn-án+ ọjọ́ gẹ́lẹ́, ó rí áńgẹ́lì+ Ọlọ́run kedere nínú ìran,+ tí ó wọlé wá bá a, tí ó sì wí fún un pé: “Kọ̀nílíù!”  Ọkùnrin náà tẹjú mọ́ ọn, bí jìnnìjìnnì sì ti bá a, ó wí pé: “Kí ni, Olúwa?” Ó wí fún un pé: “Àwọn àdúrà+ àti àwọn ẹ̀bùn àánú rẹ ti gòkè gẹ́gẹ́ bí ìrántí lọ síwájú Ọlọ́run.+  Nítorí náà, nísinsìnyí rán àwọn ènìyàn sí Jópà, kí o sì fi ọlá àṣẹ pe Símónì kan tí a fún ní orúkọ àpèlé náà Pétérù.  A ń ṣe [ọkùnrin] yìí lálejò láti ọwọ́ Símónì kan, oníṣẹ́ awọ, tí ó ní ilé kan lẹ́bàá òkun.”+  Gbàrà tí áńgẹ́lì tí ó bá a sọ̀rọ̀ ti lọ tán, ó pe méjì lára àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀ àti ọmọ ogun kan tí ó jẹ́ olùfọkànsìn láàárín àwọn tí wọ́n wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà gbogbo láti ṣèránṣẹ́ fún un,+  ó sì ṣèròyìn ohun gbogbo fún wọn, ó sì rán wọn lọ sí Jópà.+  Ní ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń lépa ìrìn àjò wọn, tí wọ́n sì ń sún mọ́ ìlú ńlá náà, Pétérù lọ sí orí ilé+ ní nǹkan bí wákàtí kẹfà láti gbàdúrà.+ 10  Ṣùgbọ́n ebi wá ń pa á gan-an, ó sì fẹ́ jẹun. Bí wọ́n ti ń pèsè oúnjẹ lọ́wọ́, ó bọ́ sínú ojúran,+ 11  ó sì rí tí ọ̀run ṣí sílẹ̀,+ tí irú ohun èlò kan ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ bí aṣọ ọ̀gbọ̀ ńlá tí a ń fi àwọn igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ rọ̀ ọ́ wálẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé; 12  gbogbo onírúurú ẹ̀dá ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti àwọn ohun tí ń rákò lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń bẹ nínú rẹ̀.+ 13  Ohùn kan sì tọ̀ ọ́ wá pé: “Dìde, Pétérù, máa pa, kí o sì máa jẹ!”+ 14  Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé: “Rárá o, Olúwa, nítorí èmi kò jẹ ohunkóhun tí ó jẹ́ ẹlẹ́gbin àti aláìmọ́ rí.”+ 15  Ohùn náà sì tún bá a sọ̀rọ̀, ní ìgbà kejì pé: “Ìwọ dẹ́kun pípe ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.”+ 16  Èyí ṣẹlẹ̀ ní ìgbà kẹta, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, a sì gbé ohun èlò náà lọ sókè ọ̀run.+ 17  Wàyí o, bí Pétérù ti wà nínú ìdàrú-ọkàn ńláǹlà ní inú lọ́hùn-ún ní ti ohun tí ìran tí òun rí lè túmọ̀ sí, wò ó! àwọn ọkùnrin tí Kọ̀nílíù rán wá ti ṣe ìwádìí nípa ilé Símónì, wọ́n sì dúró níbẹ̀ ní ẹnubodè.+ 18  Wọ́n sì pè, wọ́n sì ṣe ìwádìí bóyá a ń ṣe Símónì tí a fún ní orúkọ àpèlé náà Pétérù lálejò níbẹ̀. 19  Bí Pétérù ti ń da ìran náà rò nínú èrò inú rẹ̀, ẹ̀mí+ wí pé: “Wò ó! Àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ. 20  Bí ó ti wù kí ó rí, dìde, lọ sísàlẹ̀, kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n láti bá wọn lọ, láìṣiyèméjì rárá, nítorí èmi ni mo rán wọn wá.”+ 21  Nítorí náà, Pétérù lọ sísàlẹ̀ lọ bá àwọn ọkùnrin náà, ó sì wí pé: “Wò ó! Èmi ni ẹni tí ẹ ń wá. Kí ni ohun tí ẹ bá wá o?” 22  Wọ́n wí pé: “Kọ̀nílíù, ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ọkùnrin kan tí ó jẹ́ olódodo, tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,+ tí gbogbo orílẹ̀-èdè Júù sì ròyìn rẹ̀ dáadáa,+ ni áńgẹ́lì mímọ́ kan fún ní àwọn ìtọ́ni àtọ̀runwá pé kí ó ránṣẹ́ pè ọ́ láti wá sí ilé òun, kí òun sì gbọ́ àwọn ohun tí o ní láti sọ.” 23  Nítorí náà, ó ké sí wọn wọlé, ó sì ṣe wọ́n lálejò. Ní ọjọ́ kejì, ó dìde, ó sì bá wọn lọ, àwọn kan lára àwọn arákùnrin tí wọ́n wá láti Jópà sì bá a lọ. 24  Ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, ó wọ Kesaréà. Dájúdájú, Kọ̀nílíù ti ń fojú sọ́nà fún wọn, ó sì ti pe àwọn ìbátan rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ jọ. 25  Bí Pétérù ti wọlé, Kọ̀nílíù pàdé rẹ̀, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì wárí fún un. 26  Ṣùgbọ́n Pétérù gbé e sókè, ó wí pé: “Dìde; ènìyàn ni èmi náà.”+ 27  Bí ó sì ti ń bá a sọ̀rọ̀, ó wọlé lọ, ó sì bá ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n péjọ, 28  ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin mọ̀ dáadáa bí ó ti jẹ́ aláìbófinmu tó fún Júù kan láti dara pọ̀ mọ́ tàbí sún mọ́ ènìyàn ẹ̀yà mìíràn;+ síbẹ̀, Ọlọ́run ti fi hàn mí pé èmi kò ní láti pe ènìyàn kankan ní ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́.+ 29  Nítorí bẹ́ẹ̀ mo wá, ní ti gidi láìsí ìlòdìsí, nígbà tí a ránṣẹ́ pè mí. Nítorí náà ni mo ṣe ń wádìí ohun tí ó fà á tí ẹ fi ránṣẹ́ pè mí.” 30  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, Kọ̀nílíù wí pé: “Ọjọ́ mẹ́rin sẹ́yìn ní kíkà á láti wákàtí yìí, mo ń gbàdúrà nínú ilé mi ní wákàtí kẹsàn-án,+ nígbà tí, wò ó! ọkùnrin kan tí ó wọ aṣọ àgbéwọ̀ títànyòyò+ dúró níwájú mi, 31  ó sì wí pé, ‘Kọ̀nílíù, a ti fi ojú rere gbọ́ àdúrà rẹ, àwọn ẹ̀bùn àánú rẹ ni a sì ti rántí níwájú Ọlọ́run.+ 32  Nítorí náà, ránṣẹ́ sí Jópà, kí o sì pe Símónì wá, ẹni tí a fún ní orúkọ àpèlé náà Pétérù.+ [Ọkùnrin] yìí ni a ń ṣe lálejò ní ilé Símónì, oníṣẹ́ awọ, lẹ́bàá òkun.’+ 33  Nítorí náà, mo ránṣẹ́ sí ọ ní kíákíá, ìwọ sì ṣe dáadáa ní wíwá síhìn-ín. Nítorí náà, lọ́tẹ̀ yìí, gbogbo wa wà níwájú Ọlọ́run láti gbọ́ gbogbo ohun tí Jèhófà ti pàṣẹ pé kí o sọ.”+ 34  Látàrí èyí, Pétérù la ẹnu rẹ̀, ó sì wí pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú,+ 35  ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.+ 36  Ó fi ọ̀rọ̀+ náà ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti polongo ìhìn rere àlàáfíà+ fún wọn nípasẹ̀ Jésù Kristi: Ẹni yìí ni Olúwa gbogbo àwọn yòókù.+ 37  Ẹ mọ kókó ọ̀rọ̀ tí a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jákèjádò Jùdíà, bẹ̀rẹ̀ láti Gálílì lẹ́yìn ìbatisí tí Jòhánù wàásù,+ 38  èyíinì ni, Jésù tí ó wá láti Násárétì, bí Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí mímọ́+ àti agbára yàn án, ó sì la ilẹ̀ náà kọjá, ó ń ṣe rere, ó sì ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí Èṣù ni lára;+ nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 39  Àwa sì ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe ní ilẹ̀ àwọn Júù àti ní Jerúsálẹ́mù; ṣùgbọ́n wọ́n pa á pẹ̀lú nípa gbígbé e kọ́ sórí òpó igi.+ 40  Ọlọ́run gbé Ẹni yìí dìde ní ọjọ́ kẹta, ó sì yọ̀ǹda fún un láti fara hàn kedere,+ 41  kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn, bí kò ṣe fún àwọn ẹlẹ́rìí tí Ọlọ́run ti yàn ṣáájú,+ fún àwa, tí a bá a jẹ, tí a sì bá a mu+ lẹ́yìn tí ó dìde kúrò nínú òkú. 42  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó pa àṣẹ ìtọ́ni fún wa láti wàásù+ fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná pé Ẹni tí Ọlọ́run ti fàṣẹ gbé kalẹ̀ nìyí pé kí ó jẹ́ onídàájọ́ alààyè àti òkú.+ 43  Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sí,+ pé gbogbo ẹni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ yóò rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ní orúkọ rẹ̀.”+ 44  Nígbà tí Pétérù ṣì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ nípa ọ̀ràn wọ̀nyí, ẹ̀mí mímọ́ bà lé gbogbo àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.+ 45  Àwọn olùṣòtítọ́ tí wọ́n bá Pétérù wá, tí wọ́n jẹ́ àwọn tí ó dádọ̀dọ́, sì ṣe kàyéfì, nítorí pé ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́ ni a ń tú jáde sórí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè+ pẹ̀lú. 46  Nítorí wọ́n gbọ́ tí wọ́n ń fi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń gbé Ọlọ́run ga lọ́lá.+ Nígbà náà ni Pétérù dáhùn padà pé: 47  “Ẹnikẹ́ni ha lè ka omi léèwọ̀ tí ó fi jẹ́ pé a kò ní batisí+ àwọn wọ̀nyí tí wọ́n ti rí ẹ̀mí mímọ́ gbà, àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí i gbà?” 48  Pẹ̀lú èyíinì, ó pàṣẹ pé kí a batisí wọn ní orúkọ Jésù Kristi.+ Nígbà náà ni wọ́n béèrè pé kí ó dúró fún ọjọ́ díẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé