Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣe 1:1-26

1  Tìófílọ́sì,+ ìròyìn àkọ́kọ́, ni mo kó jọ nípa gbogbo ohun tí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe, tí ó sì ń kọ́ni,+  títí di ọjọ́ tí a gbé e lọ sókè,+ lẹ́yìn tí ó ti pa àṣẹ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn àpọ́sítélì tí ó yàn.+  Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ni ó fi ara rẹ̀ hàn fún láàyè nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ ẹ̀rí dídánilójú hán-ún hán-ún lẹ́yìn tí ó ti jìyà,+ tí wọ́n ń rí i jálẹ̀jálẹ̀ ogójì ọjọ́, tí ó sì ń sọ àwọn nǹkan nípa ìjọba Ọlọ́run.+  Nígbà tí ó sì ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú wọn, ó pa àṣẹ ìtọ́ni náà fún wọn pé: “Ẹ má ṣe fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹ máa dúró de ohun tí Baba ti ṣèlérí,+ tí ẹ gbọ́ nípa rẹ̀ lẹ́nu mi;  nítorí Jòhánù, ní tòótọ́, fi omi batisí, ṣùgbọ́n a ó batisí yín nínú ẹ̀mí mímọ́+ ní ọjọ́ tí kò ní pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn èyí.”  Wàyí o, nígbà tí wọ́n ti péjọ, wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Olúwa, ìwọ ha ń mú ìjọba+ padà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì ní àkókò yìí bí?”  Ó wí fún wọn pé: “Kì í ṣe tiyín láti mọ àwọn ìgbà tàbí àsìkò+ tí Baba ti fi sí abẹ́ àṣẹ+ òun fúnra rẹ̀;  ṣùgbọ́n ẹ ó gba agbára+ nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí+ mi ní Jerúsálẹ́mù+ àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà+ àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”+  Lẹ́yìn tí ó sì sọ nǹkan wọ̀nyí, bí wọ́n ti ń wòran, a gbé e sókè,+ àwọsánmà sì gbà á lọ kúrò ní ojúran wọn.+ 10  Bí wọ́n sì ti tẹjú mọ́ sánmà bí ó ti ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ,+ pẹ̀lúpẹ̀lù, wò ó! ọkùnrin méjì tí ó wọ ẹ̀wù funfun+ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, 11  wọ́n sì wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn Gálílì, èé ṣe tí ẹ fi dúró, tí ẹ ń wo inú sánmà? Jésù yìí tí a gbà sókè kúrò lọ́dọ̀ yín sínú sánmà yóò wá bẹ́ẹ̀ ní irú ọ̀nà kan náà+ bí ẹ ti rí i tí ó ń lọ sínú sánmà.” 12  Nígbà náà ni wọ́n padà+ sí Jerúsálẹ́mù láti òkè ńlá tí a ń pè ní Òkè Ńlá Ólífì, tí ó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù, tí ó jẹ́ ìrìn ọjọ́ sábáàtì kan.+ 13  Nítorí náà, nígbà tí wọ́n wọlé tán, wọ́n gòkè lọ sínú ìyẹ̀wù òkè,+ níbi tí wọ́n ń gbé, Pétérù àti Jòhánù àti Jákọ́bù àti Áńdérù, Fílípì àti Tọ́másì, Batolómíù àti Mátíù, Jákọ́bù ọmọkùnrin Áfíọ́sì àti Símónì onítara, àti Júdásì ọmọkùnrin Jákọ́bù.+ 14  Pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, gbogbo àwọn wọ̀nyí tẹpẹlẹ mọ́ àdúrà,+ papọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin kan+ àti Màríà ìyá Jésù àti pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀.+ 15  Wàyí o, ní ọjọ́ wọ̀nyí, Pétérù dìde ní àárín àwọn ará, ó sì wí pé (ogunlọ́gọ̀ ènìyàn náà jẹ́ nǹkan bí ọgọ́fà lápapọ̀): 16  “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, ó pọn dandan kí ìwé mímọ́ náà ní ìmúṣẹ,+ èyí tí ẹ̀mí mímọ́+ sọ ṣáájú láti ẹnu Dáfídì nípa Júdásì,+ ẹni tí ó di afinimọ̀nà fún àwọn tí wọ́n fi àṣẹ ọba mú Jésù,+ 17  nítorí a ti kà á mọ́ wa tẹ́lẹ̀,+ ó sì gba ìpín kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí.+ 18  ([Ọkùnrin] yìí gan-an, nítorí náà, fi owó ọ̀yà àìṣòdodo+ ra+ pápá kan, bí ó sì ti já ṣòòròṣò pẹ̀lú orí nísàlẹ̀ pátápátá,+ ó bẹ́ pẹ̀lú ariwo ní agbedeméjì rẹ̀, gbogbo ìfun rẹ̀ sì tú jáde. 19  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó di mímọ̀ fún gbogbo olùgbé Jerúsálẹ́mù, tí a fi pe pápá yẹn ní Ákélídámà ní èdè wọn, èyíinì ni, Pápá Ẹ̀jẹ̀.) 20  Nítorí a kọ ọ́ nínú ìwé Sáàmù pé, ‘Kí ibùwọ̀ rẹ̀ di ahoro, kí olùgbé kankan má sì sí nínú rẹ̀,’+ àti pé, ‘Kí ẹlòmíràn gba ipò iṣẹ́ àbójútó rẹ̀.’+ 21  Nítorí náà, ó pọn dandan pé lára àwọn ọkùnrin tí ó pé jọ pẹ̀lú wa ní gbogbo àkókò tí Jésù Olúwa fi wọlé wọ̀de láàárín wa,+ 22  bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbatisí rẹ̀ láti ọwọ́ Jòhánù+ àti títí di ọjọ́ tí a gbà á sókè kúrò lọ́dọ̀ wa,+ ọ̀kan lára ọkùnrin wọ̀nyí yẹ kí ó di ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa.”+ 23  Nítorí náà, wọ́n dábàá àwọn méjì, Jósẹ́fù tí a ń pè ní Básábà, ẹni tí a fún ní orúkọ àpèlé náà Jọ́sítù, àti Mátíásì. 24  Wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n sì wí pé: “Jèhófà, ìwọ ẹni tí ó mọ ọkàn-àyà gbogbo ènìyàn,+ fi ẹni tí o yàn lára ọkùnrin méjì wọ̀nyí hàn, 25  láti gba ipò iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti iṣẹ́ àpọ́sítélì yìí,+ láti inú èyí tí Júdásì ti yapa láti lọ sí ipò tirẹ̀.” 26  Nítorí náà, wọ́n ṣẹ́ kèké+ lé wọn, kèké sì mú Mátíásì; a sì kà á kún àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé