Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣípayá 9:1-21

9  Áńgẹ́lì karùn-ún sì fun kàkàkí rẹ̀.+ Mo sì rí ìràwọ̀+ kan tí ó ti jábọ́ láti ọ̀run sí ilẹ̀ ayé, a sì fún un ní kọ́kọ́rọ́+ kòtò ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.+  Ó sì ṣí kòtò ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, èéfín+ sì gòkè wá láti inú kòtò náà bí èéfín ìléru ńlá,+ oòrùn sì ṣókùnkùn,+ àti afẹ́fẹ́ pẹ̀lú, nípasẹ̀ èéfín kòtò náà.  Àwọn eéṣú+ sì jáde wá sórí ilẹ̀ ayé láti inú èéfín náà; a sì fún wọn ní ọlá àṣẹ, irú ọlá àṣẹ kan náà tí àwọn àkekèé+ ilẹ̀ ayé ní.  A sì sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe pa ewéko ilẹ̀ ayé kankan lára tàbí ohun títutùyọ̀yọ̀ èyíkéyìí tàbí igi èyíkéyìí, bí kò ṣe kìkì àwọn ènìyàn tí kò ní èdìdì Ọlọ́run ní iwájú orí wọn.+  A sì yọ̀ǹda fún àwọn eéṣú náà, láti má ṣe pa wọ́n, ṣùgbọ́n pé kí a mú àwọn wọ̀nyí joró+ fún oṣù márùn-ún, oró náà lára wọn sì dà bí oró àkekèé+ nígbà tí ó bá ta ènìyàn.  Ní ọjọ́ wọnnì, àwọn ènìyàn náà yóò wá ikú,+ ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i lọ́nàkọnà, wọn yóò sì fẹ́ láti kú, ṣùgbọ́n ikú yóò máa sá fún wọn.  Ìrí àwọn eéṣú náà sì jọ àwọn ẹṣin+ tí a múra sílẹ̀ fún ìjà ogun; àti ní orí wọn ni ohun tí ó rí bí adé tí ó dà bí wúrà wà, ojú wọ́n sì dà bí ojú ènìyàn,+  ṣùgbọ́n wọ́n ní irun bí irun obìnrin.+ Eyín wọ́n sì dà bí ti kìnnìún;+  wọ́n sì ní àwo ìgbàyà+ bí àwo ìgbàyà irin. Ìró ìyẹ́ apá wọ́n sì dà bí ìró àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ ti ọ̀pọ̀ ẹṣin tí ń sáré lọ sínú ìjà ogun.+ 10  Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n ní ìrù, wọ́n sì ń tani bí àkekèé;+ àti ní ìrù wọn ni ọlá àṣẹ wọ́n wà láti ṣe àwọn ènìyàn náà lọ́ṣẹ́ fún oṣù márùn-ún. 11  Wọ́n ní ọba kan lórí wọn, áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà.+ Lédè Hébérù, orúkọ rẹ̀ ni Ábádónì, ṣùgbọ́n lédè Gíríìkì, ó ní orúkọ náà Ápólíónì.+ 12  Ègbé kan ti kọjá. Wò ó! Ègbé+ méjì sí i ń bọ̀ lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí. 13  Áńgẹ́lì kẹfà+ sì fun kàkàkí rẹ̀.+ Mo sì gbọ́ tí ohùn+ kan láti inú àwọn ìwo orí pẹpẹ wúrà+ tí ó wà níwájú Ọlọ́run 14  wí fún áńgẹ́lì kẹfà, tí ó ní kàkàkí lọ́wọ́ pé: “Tú àwọn áńgẹ́lì+ mẹ́rin tí a dè+ síbi odò ńlá Yúfírétì+ sílẹ̀.” 15  A sì tú àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin náà sílẹ̀, àwọn tí a ti múra sílẹ̀ fún wákàtí àti ọjọ́ àti oṣù àti ọdún náà, láti pa ìdá mẹ́ta àwọn ènìyàn náà. 16  Iye àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti agbo agẹṣinjagun náà sì jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún: mo gbọ́ iye wọn. 17  Báyìí sì ni mo ṣe rí àwọn ẹṣin náà nínú ìran náà, àti àwọn tí wọ́n jókòó lórí wọn: wọ́n ní àwo ìgbàyà pupa bí iná àti búlúù bí háyásíǹtì àti yẹ́lò bí imí ọjọ́; orí àwọn ẹṣin náà sì dà bí orí kìnnìún,+ iná àti èéfín àti imí ọjọ́+ sì jáde wá láti ẹnu wọn. 18  Ìyọnu àjàkálẹ̀ mẹ́ta wọ̀nyí ni a fi pa ìdá mẹ́ta àwọn ènìyàn náà, láti inú iná àti èéfín àti imí ọjọ́ tí ó jáde wá láti ẹnu wọn. 19  Nítorí ọlá àṣẹ àwọn ẹṣin náà wà ní ẹnu wọn àti ní ìrù wọn; nítorí ìrù wọ́n dà bí ejò,+ wọ́n sì ní orí, ìwọ̀nyí ni wọ́n sì fi ń ṣe ìpalára. 20  Ṣùgbọ́n ìyókù àwọn ènìyàn tí ìyọnu àjàkálẹ̀ wọ̀nyí kò pa kò ronú pìwà dà iṣẹ́ ọwọ́ wọn,+ kí wọ́n má ṣe jọ́sìn àwọn ẹ̀mí èṣù+ àti àwọn òrìṣà wúrà àti fàdákà+ àti bàbà àti òkúta àti igi, tí kò lè ríran tàbí gbọ́ràn tàbí rìn;+ 21  wọn kò sì ronú pìwà dà àwọn ìṣìkàpànìyàn+ wọn tàbí iṣẹ́ ìbẹ́mìílò+ wọn tàbí àgbèrè wọn tàbí olè jíjà wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé