Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣípayá 8:1-13

8  Nígbà tí ó+ sì ṣí èdìdì keje,+ kẹ́kẹ́ pa ní ọ̀run fún nǹkan bí ààbọ̀ wákàtí.  Mo sì rí àwọn áńgẹ́lì méje+ tí wọ́n dúró níwájú Ọlọ́run, a sì fún wọn ní kàkàkí méje.  Áńgẹ́lì mìíràn sì dé, ó sì dúró nídìí pẹpẹ,+ ó ní ajere tùràrí oníwúrà lọ́wọ́; a sì fún un ní ìwọ̀n tùràrí+ púpọ̀ gan-an láti sun ún pẹ̀lú àdúrà gbogbo ẹni mímọ́ lórí pẹpẹ wúrà tí ó wà níwájú ìtẹ́ náà.  Èéfín tùràrí náà sì gòkè láti ọwọ́ áńgẹ́lì náà pẹ̀lú àdúrà+ àwọn ẹni mímọ́ síwájú Ọlọ́run.  Ṣùgbọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ áńgẹ́lì náà mú ajere tùràrí náà, ó sì fi díẹ̀ nínú iná+ pẹpẹ kún inú rẹ̀, ó sì fi í sọ̀kò sí ilẹ̀ ayé.+ Ààrá+ àti ohùn àti mànàmáná+ àti ìsẹ̀lẹ̀ sì sẹ̀.+  Àwọn áńgẹ́lì méje tí wọ́n ní kàkàkí+ méje+ lọ́wọ́ sì múra sílẹ̀ láti fun wọ́n.  Èyí èkíní sì fun kàkàkí rẹ̀. Yìnyín àti iná+ tí ó dà pọ̀ mọ́ ẹ̀jẹ̀ sì ṣẹlẹ̀, a sì fi í sọ̀kò sí ilẹ̀ ayé; ìdá mẹ́ta ilẹ̀ ayé sì jóná,+ ìdá mẹ́ta àwọn igi sì jóná, gbogbo ewéko+ tútù sì jóná.  Áńgẹ́lì kejì sì fun kàkàkí rẹ̀. Ohun kan bí òkè ńlá+ títóbi tí iná ń jó ni a sì fi sọ̀kò sínú òkun.+ Ìdá mẹ́ta òkun sì di ẹ̀jẹ̀;+  ìdá mẹ́ta àwọn ẹ̀dá tí ń bẹ nínú òkun tí wọ́n ní ọkàn sì kú,+ ìdá mẹ́ta àwọn ọkọ̀ ojú omi sì fọ́ bàjẹ́. 10  Áńgẹ́lì kẹta sì fun kàkàkí rẹ̀. Ìràwọ̀ ńlá tí ń jó bí fìtílà sì jábọ́ láti ọ̀run,+ ó sì jábọ́ sórí ìdá mẹ́ta àwọn odò àti sórí àwọn ìsun omi.+ 11  A sì ń pe orúkọ ìràwọ̀ náà ní Iwọ. Ìdá mẹ́ta àwọn omi sì di iwọ, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ènìyàn sì kú láti ọwọ́ àwọn omi náà, nítorí a ti sọ ìwọ̀nyí di kíkorò.+ 12  Áńgẹ́lì kẹrin sì fun kàkàkí rẹ̀. A sì fi agbára lu ìdá mẹ́ta oòrùn àti ìdá mẹ́ta òṣùpá àti ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀, kí ìdá mẹ́ta wọ́n bàa lè ṣókùnkùn,+ kí ọ̀sán má sì ní ìmọ́lẹ̀ títàn fún ìdá mẹ́ta rẹ̀,+ àti òru bákan náà. 13  Mo sì rí, mo sì gbọ́ tí idì+ kan tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run+ wí pẹ̀lú ohùn rara pé: “Ègbé, ègbé, ègbé+ ni fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé nítorí ìyókù ìró ìpè kàkàkí àwọn áńgẹ́lì mẹ́ta tí wọ́n máa tó fun kàkàkí wọn!”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé