Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣípayá 7:1-17

7  Lẹ́yìn èyí, mo rí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin+ tí wọ́n dúró lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé, wọ́n di ẹ̀fúùfù mẹ́rin+ ilẹ̀ ayé mú pinpin, kí ẹ̀fúùfù kankan má bàa fẹ́ sórí ilẹ̀ ayé tàbí sórí òkun tàbí sórí igi èyíkéyìí.+  Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń gòkè láti ibi yíyọ oòrùn,+ ó ní èdìdì Ọlọ́run alààyè;+ ó sì ké pẹ̀lú ohùn rara sí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí a yọ̀ǹda fún láti pa ilẹ̀ ayé àti òkun lára,  pé: “Ẹ má ṣe pa ilẹ̀ ayé tàbí òkun tàbí àwọn igi lára, títí di ẹ̀yìn ìgbà tí a bá fi èdìdì+ di àwọn ẹrú Ọlọ́run wa ní iwájú orí wọn.”+  Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì dì, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì,+ tí a fi èdìdì dì láti inú gbogbo ẹ̀yà+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì:+  Láti inú ẹ̀yà Júdà,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá ni a fi èdìdì dì;láti inú ẹ̀yà Rúbẹ́nì,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá;láti inú ẹ̀yà Gádì,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá;  láti inú ẹ̀yà Áṣérì,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá;láti inú ẹ̀yà Náfútálì,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá;láti inú ẹ̀yà Mánásè,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá;  láti inú ẹ̀yà Síméónì,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá;láti inú ẹ̀yà Léfì,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá;láti inú ẹ̀yà Ísákárì,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá;  láti inú ẹ̀yà Sébúlúnì,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá;láti inú ẹ̀yà Jósẹ́fù,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá;láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá ni a fi èdìdì dì.+  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo rí, sì wò ó! ogunlọ́gọ̀ ńlá,+ tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè+ àti ẹ̀yà àti ènìyàn+ àti ahọ́n,+ wọ́n dúró níwájú ìtẹ́+ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, wọ́n wọ aṣọ funfun;+ imọ̀ ọ̀pẹ+ sì ń bẹ ní ọwọ́ wọn. 10  Wọ́n sì ń bá a nìṣó ní kíké pẹ̀lú ohùn rara, pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa,+ ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́,+ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà ni ìgbàlà wa ti wá.” 11  Gbogbo áńgẹ́lì+ sì dúró yí ká ìtẹ́ náà àti àwọn alàgbà+ àti ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà,+ wọ́n sì dojú bolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run,+ 12  wí pé: “Àmín! Ìbùkún àti ògo àti ọgbọ́n àti ìdúpẹ́ àti ọlá àti agbára+ àti okun ni fún Ọlọ́run wa títí láé àti láéláé. Àmín.”+ 13  Ní ìdáhùnpadà, ọ̀kan nínú àwọn alàgbà+ náà wí fún mi pé: “Àwọn wọ̀nyí tí wọ́n wọ aṣọ funfun,+ ta ni wọ́n, ibo ni wọ́n sì ti wá?” 14  Nítorí náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ mo wí fún un pé: “Olúwa mi, ìwọ ni ẹni tí ó mọ̀.” Ó sì wí fún mi pé: “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ó jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà,+ wọ́n sì ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun+ nínú ẹ̀jẹ̀+ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. 15  Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi wà níwájú+ ìtẹ́ Ọlọ́run; wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀+ fún un tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀; Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́+ yóò sì na àgọ́+ rẹ̀ bò wọ́n. 16  Ebi kì yóò pa wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọ́n tàbí ooru èyíkéyìí tí ń jóni gbẹ,+ 17  nítorí Ọ̀dọ́ Àgùntàn,+ tí ó wà ní àárín ìtẹ́ náà, yóò máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn+ wọn, yóò sì máa ṣamọ̀nà wọn lọ sí àwọn ìsun omi+ ìyè. Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé