Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣípayá 6:1-17

6  Mo sì rí nígbà tí Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà ṣí ọ̀kan nínú àwọn èdìdì méje+ náà, mo sì gbọ́ tí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin+ náà wí pẹ̀lú ohùn bí ti ààrá pé: “Máa bọ̀!”+  Mo sì rí, sì wò ó! ẹṣin funfun kan;+ ẹni tí ó jókòó+ lórí rẹ̀ sì ní ọrun kan;+ a sì fún un ní adé,+ ó sì jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun+ àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.+  Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kejì, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kejì+ wí pé: “Máa bọ̀!”  Òmíràn sì jáde wá, ẹṣin aláwọ̀ iná; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni a sì yọ̀ǹda fún láti mú àlàáfíà kúrò ní ilẹ̀ ayé kí wọ́n lè máa fikú pa ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì; a sì fún un ní idà ńlá kan.+  Nígbà tí ó+ sì ṣí èdìdì kẹta, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹta+ wí pé: “Máa bọ̀!” Mo sì rí, sì wò ó! ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì+ ní ọwọ́ rẹ̀.  Mo sì gbọ́ tí ohùn kan bí ẹni pé ní àárín+ àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin+ náà wí pé: “Ìlàrin òṣùwọ̀n àlìkámà fún owó dínárì kan,+ àti ìlàrin òṣùwọ̀n mẹ́ta ọkà báálì fún owó dínárì kan; má sì pa òróró ólífì àti wáìnì lára.”+  Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹrin, mo gbọ́ tí ohùn ẹ̀dá alààyè kẹrin+ wí pé: “Máa bọ̀!”  Mo sì rí, sì wò ó! ẹṣin ràndánràndán kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní orúkọ náà Ikú. Hédíìsì+ sì ń tẹ̀ lé e pẹ́kípẹ́kí. A sì fún wọn ní ọlá àṣẹ lórí ìdá mẹ́rin ilẹ̀ ayé, láti máa fi idà+ gígùn pani àti àìtó oúnjẹ+ àti ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani àti àwọn ẹranko ẹhànnà+ ilẹ̀ ayé.  Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ,+ ọkàn+ àwọn tí a fikú pa+ nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nítorí iṣẹ́ ìjẹ́rìí+ tí wọ́n ti máa ń ṣe. 10  Wọ́n sì ké pẹ̀lú ohùn rara, pé: “Títí di ìgbà wo, Olúwa Ọba Aláṣẹ+ mímọ́ àti olóòótọ́,+ ni ìwọ ń fà sẹ́yìn kúrò nínú ṣíṣèdájọ́+ àti gbígbẹ̀san ẹ̀jẹ̀+ wa lára àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé?” 11  A sì fi aṣọ funfun+ kan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; a sì sọ fún wọn pé kí wọ́n sinmi fún ìgbà díẹ̀ sí i, títí iye àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ wọn àti àwọn arákùnrin wọn pẹ̀lú tí a máa tó pa+ bí a ti pa àwọn náà yóò fi pé. 12  Mo sì rí nígbà tí ó ṣí èdìdì kẹfà, ìsẹ̀lẹ̀ ńlá sì sẹ̀; oòrùn sì di dúdú bí aṣọ àpò ìdọhọ+ tí a fi irun ṣe, òṣùpá sì dà bí ẹ̀jẹ̀+ látòkè délẹ̀, 13  àwọn ìràwọ̀ ọ̀run sì jábọ́ sí ilẹ̀ ayé, bí ìgbà tí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ẹ̀fúùfù líle mì bá gbọn àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ tí kò pọ́n dànù. 14  Ọ̀run sì lọ kúrò bí àkájọ ìwé tí a ń ká,+ gbogbo òkè ńlá àti gbogbo erékùṣù ni a sì ṣí kúrò ní àyè wọn.+ 15  Àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ènìyàn onípò gíga jù lọ àti àwọn ọ̀gágun àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára àti olúkúlùkù ẹrú àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní òmìnira fi ara wọn pa mọ́ sínú àwọn hòrò àti sínú àwọn àpáta ràbàtà+ àwọn òkè ńlá. 16  Wọ́n sì ń sọ fún àwọn òkè ńlá àti fún àwọn àpáta ràbàtà pé: “Ẹ wó bò wá,+ kí ẹ sì fi wá pa mọ́ kúrò ní ojú Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́+ àti kúrò nínú ìrunú Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà, 17  nítorí ọjọ́ ńlá+ ìrunú+ wọ́n ti dé, ta ni ó sì lè dúró?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé