Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣípayá 5:1-14

5  Mo sì rí ní ọwọ́ ọ̀tún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́,+ àkájọ ìwé kan tí a kọ̀wé sí tinú-tẹ̀yìn,+ tí a fi èdìdì+ méje dì pinpin.  Mo sì rí áńgẹ́lì alágbára kan tí ń pòkìkí pẹ̀lú ohùn rara pé: “Ta ni ó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà, kí ó sì tú àwọn èdìdì rẹ̀?”  Ṣùgbọ́n kò sí ẹyọ ẹnì kan ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé tàbí nísàlẹ̀ ilẹ̀ ayé tí ó lè ṣí àkájọ ìwé náà tàbí láti wo inú rẹ̀.  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí pé a kò rí ẹnì kan tí ó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà tàbí láti wo inú rẹ̀.+  Ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn alàgbà náà wí fún mi pé: “Dẹ́kun ẹkún sísun. Wò ó! Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà,+ gbòǹgbò+ Dáfídì,+ ti ṣẹ́gun+ láti lè ṣí àkájọ ìwé náà àti èdìdì méje rẹ̀.”  Mo sì rí ní ìdúró ní àárín ìtẹ́+ náà àti ti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà àti ní àárín àwọn alàgbà náà,+ ọ̀dọ́ àgùntàn+ kan bí ẹni pé a ti fikú pa á,+ tí ó ní ìwo méje àti ojú méje, àwọn ojú tí wọ́n túmọ̀ sí ẹ̀mí méje+ ti Ọlọ́run tí a ti rán jáde sí gbogbo ilẹ̀ ayé.  Ó sì lọ, ó sì gbà á lójú ẹsẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́.+  Nígbà tí ó sì gba àkájọ ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin àti àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún+ náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, olúkúlùkù wọ́n ní háàpù+ kan lọ́wọ́ àti àwokòtò wúrà tí ó kún fún tùràrí, tùràrí+ náà sì túmọ̀ sí àdúrà+ àwọn ẹni mímọ́.  Wọ́n sì ń kọ orin tuntun+ kan, pé: “Ìwọ ni ó yẹ láti gba àkájọ ìwé náà, kí o sì ṣí àwọn èdìdì rẹ̀, nítorí pé a fikú pa ọ́, o sì fi ẹ̀jẹ̀+ rẹ ra+ àwọn ènìyàn fún Ọlọ́run+ láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè, 10  o sì mú kí wọ́n jẹ́ ìjọba+ kan àti àlùfáà+ fún Ọlọ́run wa,+ wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba+ lé ilẹ̀ ayé lórí.” 11  Mo sì rí, mo sì gbọ́ ohùn ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì ní àyíká ìtẹ́ àti àwọn ẹ̀dá alààyè àti àwọn alàgbà náà, iye wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún+ àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún,+ 12  tí wọ́n ń wí ní ohùn rara pé: “Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí a fikú pa+ ni ó yẹ láti gba agbára àti ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti okun àti ọlá àti ògo àti ìbùkún.”+ 13  Àti gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ ayé+ àti lórí òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé: “Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́+ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà ni kí ìbùkún àti ọlá+ àti ògo+ àti agbára ńlá wà fún títí láé àti láéláé.” 14  Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà sì ń wí pé: “Àmín!” àwọn alàgbà+ náà sì wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé