Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣípayá 4:1-11

4  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo rí, sì wò ó! ilẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run, ohùn àkọ́kọ́ tí mo sì gbọ́ dà bí ti kàkàkí,+ ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé: “Máa bọ̀ lókè níhìn-ín,+ èmi yóò sì fi àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ hàn ọ́.”+  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, mo wá wà nínú agbára ẹ̀mí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀: sì wò ó! ìtẹ́+ kan wà ní ipò rẹ̀ ní ọ̀run,+ ẹnì kan sì wà tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà.+  Ẹni tí ó jókòó, ní ìrísí,+ sì dà bí òkúta jásípérì+ àti òkúta aláwọ̀ pupa tí ó ṣeyebíye, àti yí ká ìtẹ́ náà òṣùmàrè+ kan wà tí ó dà bí òkúta émírádì+ ní ìrísí.  Àti yí ká ìtẹ́ náà ni ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún wà, mo sì rí àwọn alàgbà+ mẹ́rìnlélógún+ tí wọ́n wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun,+ tí wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọ̀nyí,+ adé wúrà+ sì ń bẹ ní orí wọn.  Mànàmáná+ àti ohùn àti ààrá+ sì ń jáde wá láti inú ìtẹ́ náà; fìtílà+ iná méje sì wà tí ń jó níwájú ìtẹ́ náà, ìwọ̀nyí sì túmọ̀ sí ẹ̀mí méje+ ti Ọlọ́run.  Àti níwájú ìtẹ́ náà ni ohun tí a lè pè ní òkun bí gíláàsì,+ tí ó dà bí kírísítálì wà. Àti ní àárín ìtẹ́ náà àti yí ká ìtẹ́ náà ni àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin+ wà tí wọ́n kún fún ojú níwájú àti lẹ́yìn.  Ẹ̀dá alààyè kìíní sì dà bí kìnnìún,+ ẹ̀dá alààyè kejì sì dà bí ẹgbọrọ akọ màlúù,+ ẹ̀dá alààyè kẹta+ sì ní ojú bí ti ènìyàn, ẹ̀dá alààyè kẹrin+ sì dà bí idì+ tí ń fò.  Àti ní ti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà,+ olúkúlùkù wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìyẹ́ apá mẹ́fà;+ yí ká àti lábẹ́, wọ́n kún fún ojú.+ Wọn kò sì ní ìsinmi rárá lọ́sàn-án àti lóru bí wọ́n ti ń wí pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà+ Ọlọ́run, Olódùmarè,+ tí ó ti wà,+ tí ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀.”  Àti nígbàkigbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá fi ògo àti ọlá àti ìdúpẹ́+ fún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́,+ Ẹni tí ó wà láàyè títí láé àti láéláé,+ 10  àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún+ náà a wólẹ̀ níwájú Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wọn a jọ́sìn+ Ẹni tí ó wà láàyè títí láé àti láéláé, wọn a sì ju adé wọn síwájú ìtẹ́ náà, wọn a sọ pé: 11  “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo+ àti ọlá+ àti agbára,+ nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo,+ àti nítorí ìfẹ́+ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé