Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣípayá 3:1-22

3  “Sì kọ̀wé sí áńgẹ́lì+ ìjọ ní Sádísì pé: Ìwọ̀nyí ni ohun tí òun wí ẹni tí ó ní ẹ̀mí méje+ ti Ọlọ́run àti ìràwọ̀ méje náà,+ ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ ní orúkọ pé o wà láàyè, ṣùgbọ́n o ti kú.+  Máa kíyè sára,+ kí o sì fún àwọn ohun tí ó ṣẹ́ kù tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú lókun,+ nítorí èmi kò rí i pé ìwọ ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ ní kíkún níwájú Ọlọ́run mi.+  Nítorí náà, máa bá a lọ ní fífi bí o ṣe gbà+ àti bí o ṣe gbọ́ sọ́kàn, sì máa bá a lọ ní pípa á mọ́,+ kí o sì ronú pìwà dà.+ Dájúdájú, láìjẹ́ pé o jí,+ èmi yóò wá gẹ́gẹ́ bí olè,+ ìwọ kì yóò sì mọ̀ rárá wákàtí tí èmi yóò dé bá ọ.+  “‘Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lóòótọ́ ìwọ ní àwọn orúkọ+ díẹ̀ ní Sádísì tí wọn kò sọ ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn di ẹlẹ́gbin,+ dájúdájú, wọn yóò bá mi rìn nínú èyí tí ó funfun,+ nítorí wọ́n yẹ.+  Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun+ ni a ó fi ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun ṣe ní ọ̀ṣọ́ báyìí;+ dájúdájú, èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ lọ́nàkọnà kúrò nínú ìwé ìyè,+ ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ mímọ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba+ mi àti níwájú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.+  Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí+ ń sọ fún àwọn ìjọ.’  “Sì kọ̀wé sí áńgẹ́lì+ ìjọ ní Filadéfíà pé: Ìwọ̀nyí ni ohun tí òun wí ẹni tí ó jẹ́ mímọ́,+ tí ó jẹ́ òótọ́,+ tí ó ní kọ́kọ́rọ́ Dáfídì,+ ẹni tí ń ṣí tí kò sí ẹni tí yóò tì, tí ó sì ń tì, tí kò sí ẹni tí yóò ṣí,  ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́+ rẹ—wò ó! mo ti gbé ilẹ̀kùn ṣíṣísílẹ̀+ kalẹ̀ níwájú rẹ, èyí tí ẹnì kankan kò lè tì—pé agbára díẹ̀ ni ìwọ ní, ìwọ sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, ìwọ kò sì já sí èké sí orúkọ mi.+  Wò ó! Ṣe ni èmi yóò fi àwọn wọnnì láti inú sínágọ́gù Sátánì fúnni, àwọn tí ń wí pé Júù ni àwọn,+ síbẹ̀ tí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n irọ́ ni wọ́n ń pa+—wò ó! ṣe ni èmi yóò mú kí wọ́n wá, kí wọ́n sì wárí+ níwájú ẹsẹ̀ rẹ, èmi yóò sì mú kí wọ́n mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ. 10  Nítorí pé ìwọ pa ọ̀rọ̀ nípa ìfaradà+ mi mọ́, ṣe ni èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́+ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, èyí tí yóò dé bá gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé+ wò. 11  Mo ń bọ̀ kíákíá.+ Máa bá a nìṣó ní dídi ohun tí ìwọ ní mú ṣinṣin,+ kí ẹnì kankan má bàa gba adé rẹ.+ 12  “‘Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun—ṣe ni èmi yóò fi í ṣe ọwọ̀n+ nínú tẹ́ńpìlì+ Ọlọ́run mi,+ lọ́nàkọnà, kì yóò jáde kúrò nínú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi àti orúkọ ìlú ńlá Ọlọ́run mi, Jerúsálẹ́mù tuntun+ tí ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi, àti orúkọ mi tuntun+ yẹn sára rẹ̀. 13  Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí+ ń sọ fún àwọn ìjọ.’ 14  “Sì kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Laodíkíà+ pé: Ìwọ̀nyí ni ohun tí Àmín+ wí, ẹlẹ́rìí+ aṣeégbíyèlé+ àti olóòótọ́,+ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run,+ 15  ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, pé o kò tutù bẹ́ẹ̀ ni o kò gbóná. Èmi ì bá fẹ́ kí o tutù tàbí kẹ̀ kí o gbóná. 16  Nípa báyìí, nítorí pé o lọ́wọ́ọ́wọ́, tí o kò sì gbóná+ tàbí tutù,+ èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ní ẹnu mi. 17  Nítorí ìwọ wí pé: “Ọlọ́rọ̀ ni mí,+ mo sì ti kó ọrọ̀ jọ, èmi kò sì nílò ohunkóhun rárá,” ṣùgbọ́n o kò mọ̀ pé akúùṣẹ́ ni ọ́ àti ẹni ìkáàánú fún àti òtòṣì àti afọ́jú+ àti ẹni ìhòòhò, 18  mo gbà ọ́ nímọ̀ràn láti ra wúrà+ tí a fi iná yọ́ mọ́ lọ́dọ̀ mi kí o lè di ọlọ́rọ̀, àti ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun kí o lè di ẹni tí ó wọṣọ, kí ìtìjú ìhòòhò rẹ má bàa sì di èyí tí ó fara hàn kedere,+ àti oògùn ojú láti fi pa ojú rẹ,+ kí o bàa lè ríran. 19  “‘Gbogbo àwọn tí mo ní ìfẹ́ni fún ni mo ń sọ́nà, tí mo sì ń bá wí.+ Nítorí náà, jẹ́ onítara, kí o sì ronú pìwà dà.+ 20  Wò ó! Mo dúró lẹ́nu ilẹ̀kùn,+ mo sì ń kànkùn. Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohùn mi tí ó sì ṣí ilẹ̀kùn,+ dájúdájú, èmi yóò wọ ilé rẹ̀, èmi yóò sì jẹ oúnjẹ alẹ́ pẹ̀lú rẹ̀ àti òun pẹ̀lú mi. 21  Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun+ ni èmi yóò yọ̀ǹda fún láti jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi,+ àní gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó+ pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀.+ 22  Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí+ ń sọ fún àwọn ìjọ.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé