Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣípayá 22:1-21

22  Ó sì fi odò omi ìyè+ kan hàn mí, tí ó mọ́ kedere bí kírísítálì, tí ń ṣàn jáde láti ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà+  wá sí ìsàlẹ̀ gba àárín ọ̀nà fífẹ̀ rẹ̀. Àwọn igi+ ìyè tí ń mú irè oko méjìlá ti èso jáde sì wà níhà ìhín odò náà àti níhà ọ̀hún, tí ń so àwọn èso wọn ní oṣooṣù.+ Ewé àwọn igi náà sì wà fún wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn.+  Kì yóò sì sí ègún kankan mọ́.+ Ṣùgbọ́n ìtẹ́ Ọlọ́run+ àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà yóò wà nínú ìlú ńlá náà, àwọn ẹrú rẹ̀ yóò sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un;+  wọn yóò sì rí ojú rẹ̀,+ orúkọ rẹ̀ yóò sì wà ní iwájú orí wọn.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, òru kì yóò sí mọ́,+ wọn kò sì nílò ìmọ́lẹ̀ fìtílà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò nílò ìmọ́lẹ̀ oòrùn, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run yóò tan ìmọ́lẹ̀+ sórí wọn, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé àti láéláé.+  Ó sì wí fún mi pé: “Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́;+ bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run àwọn àgbéjáde onímìísí+ àwọn wòlíì+ rán áńgẹ́lì rẹ̀ jáde láti fi àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́+ han àwọn ẹrú rẹ̀.  Sì wò ó! mo ń bọ̀ kíákíá.+ Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé+ yìí mọ́.”  Tóò, èmi Jòhánù ni ẹni tí ń gbọ́, tí ó sì ń rí nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo gbọ́, tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti jọ́sìn+ níwájú ẹsẹ̀ áńgẹ́lì tí ó ti ń fi nǹkan wọ̀nyí hàn mí.  Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Gbogbo ohun tí mo jẹ́ ni ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ àti ti àwọn arákùnrin rẹ tí wọ́n jẹ́ wòlíì+ àti ti àwọn tí ń pa àwọn ọ̀rọ̀ àkájọ ìwé yìí mọ́. Jọ́sìn Ọlọ́run.”+ 10  Ó tún sọ fún mi pé: “Má ṣe fi èdìdì di àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí, nítorí àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti sún mọ́lé.+ 11  Ẹni tí ń ṣe àìṣòdodo, kí ó máa ṣe àìṣòdodo síbẹ̀;+ kí a sì sọ ẹni tí ó jẹ́ eléèérí di eléèérí síbẹ̀;+ ṣùgbọ́n kí olódodo+ máa ṣe òdodo síbẹ̀, kí a sì sọ ẹni mímọ́ di mímọ́ síbẹ̀.+ 12  “‘Wò ó! Mo ń bọ̀ kíákíá,+ èrè+ tí mo sì ń fi fúnni wà pẹ̀lú mi, láti san fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ ti rí.+ 13  Èmi ni Ááfà àti Ómégà,+ ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn,+ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti òpin. 14  Aláyọ̀ ni àwọn tí ó fọ aṣọ wọn,+ kí ọlá àṣẹ láti lọ síbi àwọn igi ìyè+ lè jẹ́ tiwọn, kí wọ́n sì lè gba ẹnubodè wọlé sínú ìlú ńlá náà.+ 15  Lẹ́yìn òde ni àwọn ajá+ wà àti àwọn tí ń bá ẹ̀mí lò+ àti àwọn àgbèrè+ àti àwọn òṣìkàpànìyàn àti àwọn abọ̀rìṣà àti gbogbo ẹni tí ó fẹ́ràn irọ́, tí ó sì ń bá a lọ ní pípurọ́.’+ 16  “‘Èmi, Jésù, rán áńgẹ́lì mi láti jẹ́rìí fún yín nípa nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò+ àti ọmọ+ Dáfídì, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ títànyòyò.’”+ 17  Àti ẹ̀mí+ àti ìyàwó+ ń bá a nìṣó ní sísọ pé: “Máa bọ̀!” Kí ẹnikẹ́ni tí ń gbọ́ sì wí pé: “Máa bọ̀!”+ Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀;+ kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.+ 18  “Mo ń jẹ́rìí fún olúkúlùkù ẹni tí ó gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí pé: Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe àfikún+ kan sí nǹkan wọ̀nyí, Ọlọ́run yóò fi àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀+ tí a kọ sínú àkájọ ìwé yìí kún ẹni náà; 19  bí ẹnikẹ́ni bá sì mú ohunkóhun kúrò nínú àwọn ọ̀rọ̀ àkájọ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run yóò mú ìpín rẹ̀ kúrò nínú àwọn igi ìyè+ àti kúrò nínú ìlú ńlá mímọ́ náà,+ àwọn nǹkan tí a kọ̀wé nípa wọn nínú àkájọ ìwé yìí. 20  “Ẹni tí ó jẹ́rìí nípa nǹkan wọ̀nyí wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni; mo ń bọ̀ kíákíá.’”+ “Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.” 21  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé