Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣípayá 21:1-27

21  Mo sì rí ọ̀run tuntun+ kan àti ilẹ̀ ayé tuntun+ kan; nítorí ọ̀run ti ìṣáájú+ àti ilẹ̀ ayé ti ìṣáájú+ ti kọjá lọ, òkun+ kò sì sí mọ́.  Mo rí ìlú ńlá mímọ́+ náà pẹ̀lú, Jerúsálẹ́mù Tuntun, tí ń ti ọ̀run+ sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, a sì múra rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó+ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀.+  Pẹ̀lú ìyẹn, mo gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: “Wò ó! Àgọ́+ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé,+ wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀.+ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn.+  Yóò sì nu omijé+ gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́,+ bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.+ Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”+  Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́+ sì wí pé: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.”+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wí pé: “Kọ̀wé, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.”  Ó sì wí fún mi pé: “Wọ́n ti ṣẹlẹ̀! Èmi ni Ááfà àti Ómégà, ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti òpin.+ Ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ ni èmi yóò fi fún láti inú ìsun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.+  Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹ́gun yóò jogún nǹkan wọ̀nyí, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀,+ yóò sì jẹ́ ọmọ mi.+  Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ojo àti àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́+ àti àwọn tí ń ríni lára nínú èérí+ wọn àti àwọn òṣìkàpànìyàn+ àti àwọn àgbèrè+ àti àwọn tí ń bá ẹ̀mí lò àti àwọn abọ̀rìṣà+ àti gbogbo òpùrọ́,+ ìpín tiwọn yóò wà nínú adágún tí ń fi iná+ àti imí ọjọ́+ jó. Èyí túmọ̀ sí ikú kejì.”+  Ọ̀kan nínú àwọn áńgẹ́lì méje tí wọ́n ní àwokòtò méje lọ́wọ́ tí ó kún fún ìyọnu àjàkálẹ̀+ méje ìkẹyìn sì wá, ó sì bá mi sọ̀rọ̀, ó sì wí pé: “Wá níhìn-ín, dájúdájú, èmi yóò fi ìyàwó hàn ọ́, aya Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.”+ 10  Nítorí náà, ó gbé mi nínú agbára ẹ̀mí lọ sí òkè ńlá títóbi tí ó ga fíofío,+ ó sì fi ìlú ńlá mímọ́+ náà Jerúsálẹ́mù hàn mí tí ń ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ 11  ó sì ní ògo Ọlọ́run.+ Ìtànyinrin rẹ̀ dà bí òkúta ṣíṣeyebíye jù lọ, bí òkúta jásípérì tí ń dán bí kírísítálì tí ó mọ́ kedere.+ 12  Ó ní ògiri ńlá gíga fíofío,+ ó sì ní ẹnubodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnubodè náà, áńgẹ́lì méjìlá, a sì kọ àkọlé àwọn orúkọ tí ó jẹ́ àwọn ti ẹ̀yà méjìlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 13  Ẹnubodè mẹ́ta wà ní ìlà-oòrùn, àti ní àríwá, ẹnubodè mẹ́ta, àti ní gúúsù, ẹnubodè mẹ́ta, àti ní ìwọ̀-oòrùn, ẹnubodè mẹ́ta.+ 14  Ògiri ìlú ńlá náà tún ní òkúta ìpìlẹ̀+ méjìlá, àti lára wọn, orúkọ méjìlá ti àwọn àpọ́sítélì+ méjìlá ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. 15  Wàyí o, ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀ mú ọ̀pá esùsú oníwúrà+ kan lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n, kí ó lè wọn ìlú ńlá náà àti àwọn ẹnubodè rẹ̀ àti ògiri rẹ̀.+ 16  Ìlú ńlá náà sì gbalẹ̀ ní igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, òró rẹ̀ sì tóbi gẹ́lẹ́ bí ìbú rẹ̀. Ó sì fi ọ̀pá esùsú náà wọn ìlú ńlá náà,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá ìwọ̀n fọ́lọ́ǹgì; òró àti ìbú àti gíga rẹ̀ jẹ́ ọgbọọgba. 17  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wọn ògiri rẹ̀, ogóje ó lé mẹ́rin ìgbọ̀nwọ́, ní ìbámu pẹ̀lú òṣùwọ̀n ènìyàn, tí ó tún jẹ́ ti áńgẹ́lì lẹ́sẹ̀ kan náà. 18  Wàyí o, ìgbékalẹ̀ ògiri rẹ̀ jẹ́ òkúta jásípérì,+ ìlú ńlá náà sì jẹ́ ògidì wúrà bí gíláàsì tí ó mọ́ kedere. 19  Àwọn ìpìlẹ̀+ ògiri ìlú ńlá náà ni a fi gbogbo onírúurú òkúta ṣíṣeyebíye+ ṣe lọ́ṣọ̀ọ́: ìpìlẹ̀ kìíní jẹ́ jásípérì,+ ìkejì sàfáyà,+ ìkẹta kásídónì, ìkẹrin ẹ́mírádì,+ 20  ìkarùn-ún sádónísì, ìkẹfà sádíọ́sì, ìkeje kírísóláítì,+ ìkẹjọ bérílì, ìkẹsàn-án tópásì,+ ìkẹwàá kírísópírásì, ìkọkànlá háyásíǹtì, ìkejìlá ámétísì.+ 21  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹnubodè méjìlá náà jẹ́ péálì méjìlá; ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹnubodè náà ni a fi péálì+ kan ṣe. Ọ̀nà fífẹ̀ ìlú ńlá náà sì jẹ́ ògidì wúrà, bí gíláàsì tí ń fi òdì-kejì hàn kedere. 22  Èmi kò sì rí tẹ́ńpìlì kan nínú rẹ̀,+ nítorí Jèhófà+ Ọlọ́run Olódùmarè+ ni tẹ́ńpìlì rẹ̀,+ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.+ 23  Ìlú ńlá náà kò sì nílò oòrùn tàbí òṣùpá láti ràn sórí rẹ̀, nítorí ògo Ọlọ́run mú un mọ́lẹ̀ kedere,+ Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà sì ni fìtílà rẹ̀. 24  Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀,+ àwọn ọba ilẹ̀ ayé yóò sì mú ògo wọn wá sínú rẹ̀.+ 25  A kì yóò sì sé ẹnubodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán,+ nítorí òru kì yóò sí níbẹ̀.+ 26  Wọn yóò sì mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀.+ 27  Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí kì í ṣe ọlọ́wọ̀ àti ẹnikẹ́ni tí ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun ìríra+ àti ní pípurọ́+ kì yóò wọnú rẹ̀ lọ́nàkọnà;+ àyàfi àwọn tí a kọ sínú àkájọ ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni yóò wọnú rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé