Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣípayá 20:1-15

20  Mo sì rí áńgẹ́lì kan tí ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀+ àti ẹ̀wọ̀n ńlá ní ọwọ́ rẹ̀.  Ó sì gbá dírágónì+ náà mú, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,+ ẹni tí í ṣe Èṣù+ àti Sátánì,+ ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún ọdún.  Ó fi í sọ̀kò sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà,+ ó tì í, ó sì fi èdìdì dí i lórí rẹ̀, kí ó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi dópin. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ tú u fún ìgbà díẹ̀.+  Mo sì rí àwọn ìtẹ́,+ àwọn tí ó jókòó lórí wọn sì ń bẹ, a sì fún wọn ní agbára ṣíṣèdájọ́.+ Bẹ́ẹ̀ ni, mo rí ọkàn àwọn tí a fi àáké pa nítorí ẹ̀rí Jésù tí wọ́n jẹ́ àti nítorí sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, àti àwọn tí kò jọ́sìn ẹranko ẹhànnà+ náà tàbí ère+ rẹ̀ àti àwọn tí kò gba àmì náà sí iwájú orí wọn àti sí ọwọ́ wọn.+ Wọ́n sì wá sí ìyè, wọ́n sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba+ pẹ̀lú Kristi fún ẹgbẹ̀rún ọdún.  (Ìyókù àwọn òkú+ kò wá sí ìyè títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà fi dópin.)+ Èyí ni àjíǹde èkíní.+  Aláyọ̀+ àti mímọ́+ ni ẹnikẹ́ni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkíní; ikú kejì+ kò ní àṣẹ+ kankan lórí àwọn wọ̀nyí, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ àlùfáà+ Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.+  Wàyí o, gbàrà tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá ti dópin, a óò tú Sátánì sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n rẹ̀,  yóò sì jáde lọ láti ṣi orílẹ̀-èdè wọnnì ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé lọ́nà, Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù, láti kó wọn jọpọ̀ fún ogun. Iye àwọn wọ̀nyí rí bí iyanrìn òkun.+  Wọ́n sì rìn jìnnà kárí ìbú ilẹ̀ ayé, wọ́n sì pagbo yí ká ibùdó àwọn ẹni mímọ́+ àti ìlú ńlá olùfẹ́ ọ̀wọ́n.+ Ṣùgbọ́n iná sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá, ó sì jẹ wọ́n run.+ 10  A sì fi Èṣù+ tí ń ṣì wọ́n lọ́nà sọ̀kò sínú adágún iná àti imí ọjọ́, níbi tí ẹranko ẹhànnà+ náà àti wòlíì èké náà ti wà nísinsìnyí;+ a ó sì máa mú wọn joró tọ̀sán-tòru títí láé àti láéláé. 11  Mo sì rí ìtẹ́ ńlá funfun kan àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀.+ Ilẹ̀ ayé àti ọ̀run sá lọ kúrò níwájú rẹ̀,+ a kò sì rí àyè kankan fún wọn. 12  Mo sì rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré,+ tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. Ṣùgbọ́n a ṣí àkájọ ìwé mìíràn sílẹ̀; àkájọ ìwé ìyè ni.+ A sì ṣèdájọ́ àwọn òkú láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn.+ 13  Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú+ tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́, a sì ṣèdájọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn.+ 14  A sì fi ikú+ àti Hédíìsì sọ̀kò sínú adágún iná. Èyí túmọ̀ sí ikú kejì,+ adágún iná náà.+ 15  Síwájú sí i, ẹnì yòówù tí a kò rí pé a kọ sínú ìwé ìyè+ ni a fi sọ̀kò sínú adágún iná náà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé