Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣípayá 2:1-29

2  “Kọ̀wé sí áńgẹ́lì+ ìjọ ní Éfésù+ pé: Ìwọ̀nyí ni ohun tí ẹni tí ó di ìràwọ̀ méje+ mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ wí, ẹni tí ń rìn ní àárín ọ̀pá fìtílà méje oníwúrà,+  ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ,+ àti òpò àti ìfaradà rẹ, àti pé ìwọ kò lè gba àwọn ènìyàn búburú mọ́ra, àti pé ìwọ ti dán+ àwọn tí wọ́n sọ pé àpọ́sítélì+ ni àwọn wò, ṣùgbọ́n tí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀, o sì rí wọn ní òpùrọ́.  Ìwọ ń fi ìfaradà+ hàn pẹ̀lú, o sì ti rọ́jú nítorí orúkọ mi,+ àárẹ̀ kò sì mú ọ.+  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ní èyí lòdì sí ọ, pé ìwọ ti fi ìfẹ́ tí ìwọ ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.+  “‘Nítorí náà, rántí inú ohun tí o ti ṣubú, kí o sì ronú pìwà dà,+ kí o sì ṣe àwọn iṣẹ́ ti ìṣáájú. Bí ìwọ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ,+ ṣe ni èmi yóò sì gbé ọ̀pá fìtílà+ rẹ kúrò ní àyè rẹ̀, àyàfi bí o bá ronú pìwà dà.  Síbẹ̀, ìwọ ní èyí, pé o kórìíra+ àwọn iṣẹ́ ẹ̀ya ìsìn Níkóláọ́sì,+ èyí tí èmi pẹ̀lú kórìíra.  Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí+ ń sọ fún àwọn ìjọ: Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun+ ni èmi yóò yọ̀ǹda fún láti jẹ nínú igi ìyè,+ èyí tí ń bẹ nínú párádísè Ọlọ́run.’  “Sì kọ̀wé sí áńgẹ́lì+ ìjọ ní Símínà pé: Ìwọ̀nyí ni ohun tí òun wí, ‘Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn,’+ ẹni tí ó di òkú tẹ́lẹ̀, tí ó sì tún wá sí ìyè,+  ‘Mo mọ ìpọ́njú àti ipò òṣì rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀+ ni ọ́—àti ọ̀rọ̀ òdì láti ẹnu àwọn tí ń sọ pé àwọn jẹ́ Júù,+ síbẹ̀ tí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ sínágọ́gù Sátánì.+ 10  Má fòyà àwọn ohun tí ìwọ máa tó jìyà rẹ̀.+ Wò ó! Èṣù+ yóò máa bá a nìṣó ní sísọ àwọn kan nínú yín sí ẹ̀wọ̀n kí a lè dán yín wò+ ní kíkún, kí ẹ sì lè ní ìpọ́njú+ fún ọjọ́ mẹ́wàá. Jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú,+ dájúdájú, èmi yóò sì fún ọ ní adé ìyè.+ 11  Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́+ ohun tí ẹ̀mí+ ń sọ fún àwọn ìjọ: Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun+ ni ikú kejì+ kì yóò pa lára lọ́nàkọnà.’ 12  “Sì kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Págámù pé: Ìwọ̀nyí ni ohun tí òun wí ẹni tí ó ní idà+ gígùn olójú méjì mímú, 13  ‘Mo mọ ibi tí ìwọ ń gbé, èyíinì ni, ibi tí ìtẹ́ Sátánì wà; síbẹ̀ ìwọ ń bá a nìṣó ní dídi orúkọ mi mú ṣinṣin,+ ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ nínú mi,+ àní ní àwọn ọjọ́ Áńtípà, ẹlẹ́rìí+ mi, olùṣòtítọ́, ẹni tí a pa+ ní ẹ̀gbẹ́ yín, níbi tí Sátánì ń gbé. 14  “‘Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ní àwọn nǹkan díẹ̀ lòdì sí ọ, pé ìwọ ní níbẹ̀, àwọn tí wọ́n di ẹ̀kọ́ Báláámù+ mú ṣinṣin, ẹni tí ó lọ ń kọ́ Bálákì+ láti fi ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti jẹ àwọn ohun tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà àti láti ṣe àgbèrè.+ 15  Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ, pẹ̀lú, ní àwọn tí ó di ẹ̀kọ́ ẹ̀ya ìsìn Níkoláọ́sì+ mú ṣinṣin bákan náà. 16  Nítorí náà, ronú pìwà dà.+ Bí ìwọ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, mo ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ ní kíákíá, ṣe ni èmi yóò sì fi idà gígùn ẹnu+ mi bá wọn jagun.+ 17  “‘Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ:+ Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun+ ni èmi yóò fún ní díẹ̀ nínú mánà+ tí a fi pa mọ́, èmi yóò sì fún un ní òkúta róbótó funfun kan, àti lára òkúta róbótó náà orúkọ+ tuntun tí a kọ, èyí tí ẹnì kankan kò mọ̀ àyàfi ẹni tí ó rí i gbà.’+ 18  “Sì kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Tíátírà+ pé: Ìwọ̀nyí ni ohun tí Ọmọ+ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú tí ó ní dà bí ọwọ́ iná ajófòfò,+ ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dà bí bàbà àtàtà,+ 19  ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, àti ìfẹ́+ àti ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìfaradà rẹ, àti pé àwọn iṣẹ́+ rẹ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ pọ̀ ju àwọn ti ìṣáájú.+ 20  “‘Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ní èyí lòdì sí ọ, pé ìwọ fi àyè gba obìnrin yẹn Jésíbẹ́lì,+ ẹni tí ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì obìnrin, ó sì ń kọ́,+ ó sì ń ṣi àwọn ẹrú+ mi lọ́nà láti ṣe àgbèrè+ àti láti jẹ àwọn ohun tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà.+ 21  Mo sì fún un ní àkókò láti ronú pìwà dà,+ ṣùgbọ́n kò fẹ́ láti ronú pìwà dà àgbèrè rẹ̀.+ 22  Wò ó! Mo máa tó sọ ọ́ sórí ibùsùn àìsàn, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà sínú ìpọ́njú ńlá, àyàfi bí wọ́n bá ronú pìwà dà àwọn iṣẹ́ rẹ̀. 23  Ṣe ni èmi yóò sì fi ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani pa àwọn ọmọ rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ìjọ yóò mọ̀ pé èmi ni ẹni tí ń wá inú kíndìnrín àti ọkàn-àyà, èmi yóò sì fi fún yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ yín.+ 24  “‘Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ̀yin yòókù tí ó wà ní Tíátírà, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kò gba ẹ̀kọ́ yìí, ẹ̀yin tí kò mọ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì,”+ bí wọ́n ti ń wí, ni mo wí fún pé: Èmi kò ní gbé ẹrù ìnira èyíkéyìí mìíràn rù yín.+ 25  Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin+ títí èmi yóò fi dé. 26  Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, tí ó sì pa àwọn iṣẹ́ mi mọ́ títí dé òpin+ ni èmi yóò fún ní ọlá àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè,+ 27  yóò sì fi ọ̀pá irin+ ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn ènìyàn tó bẹ́ẹ̀ tí a óò fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ bí àwọn ohun èlò amọ̀,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti gbà láti ọwọ́ Baba mi, 28  ṣe ni èmi yóò sì fún un ní ìràwọ̀ òwúrọ̀.+ 29  Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí+ ń sọ fún àwọn ìjọ.’+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé