Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣípayá 19:1-21

19  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, mo gbọ́ ohun tí ó dà bí ohùn rara ti ogunlọ́gọ̀ ńlá ní ọ̀run.+ Wọ́n wí pé: “Ẹ yin Jáà!+ Ìgbàlà+ àti ògo àti agbára jẹ́ ti Ọlọ́run wa,+  nítorí òótọ́ àti òdodo ni àwọn ìdájọ́ rẹ̀.+ Nítorí pé ó ti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sórí aṣẹ́wó ńlá tí ó fi àgbèrè rẹ̀ sọ ilẹ̀ ayé di ìbàjẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹrú rẹ̀ lára rẹ̀.”+  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n sọ ní ìgbà kejì pé: “Ẹ yin Jáà!+ Èéfín láti ara rẹ̀ sì ń bá a lọ ní gígòkè títí láé àti láéláé.”+  Àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún+ àti ẹ̀dá alààyè mẹ́rìn+ náà sì wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run tí ó jókòó+ lórí ìtẹ́, wọ́n sì wí pé: “Àmín! Ẹ yin Jáà!”+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohùn kan jáde wá láti orí ìtẹ́ náà, ó sì wí pé: “Ẹ máa yin Ọlọ́run wa, gbogbo ẹ̀yin ẹrú rẹ̀,+ tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ẹ̀yin ẹni kékeré àti ẹni ńlá.”+  Mo sì gbọ́ ohun tí ó dà bí ohùn ogunlọ́gọ̀ ńlá àti bí ìró omi púpọ̀ àti bí ìró àwọn ààrá pípabanbarì. Wọ́n wí pé: “Ẹ yin Jáà,+ nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run wa, Olódùmarè,+ ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.+  Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí a sì láyọ̀ púpọ̀, ẹ sì jẹ́ kí a fi ògo+ fún un, nítorí ìgbéyàwó+ Ọ̀dọ́ Àgùntàn ti dé,+ aya rẹ̀ sì ti múra sílẹ̀.+  Bẹ́ẹ̀ ni, a ti yọ̀ǹda fún un kí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, títànyòyò, tí ó mọ́ ṣe é ní ọ̀ṣọ́, nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà náà dúró fún àwọn ìṣe òdodo àwọn ẹni mímọ́.”+  Ó sì sọ fún mi pé: “Kọ̀wé pé: Aláyọ̀ ni àwọn tí a ké sí+ wá síbi oúnjẹ alẹ́ ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.”+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó sọ fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni àsọjáde tòótọ́ ti Ọlọ́run.”+ 10  Látàrí ìyẹn, mo wólẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ rẹ̀ láti jọ́sìn rẹ̀.+ Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀!+ Gbogbo ohun tí mo jẹ́ ni ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ àti ti àwọn arákùnrin rẹ tí wọ́n ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.+ Jọ́sìn Ọlọ́run;+ nítorí jíjẹ́rìí Jésù ni ohun tí ń mí sí ìsọtẹ́lẹ̀.”+ 11  Mo sì rí tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó! ẹṣin funfun kan.+ Ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni a ń pè ní Aṣeégbíyèlé+ àti Olóòótọ́,+ ó ń ṣèdájọ́, ó sì ń bá ogun lọ nínú òdodo.+ 12  Ojú rẹ̀ jẹ́ ọwọ́ iná ajófòfò,+ adé dáyádémà+ púpọ̀ sì wà ní orí rẹ̀. Ó ní orúkọ+ kan tí a kọ, tí ẹnì kankan kò mọ̀ bí kò ṣe òun fúnra rẹ̀, 13  a sì fi ẹ̀wù àwọ̀lékè tí a fi ẹ̀jẹ̀+ wọ́n ṣe é ní ọ̀ṣọ́, orúkọ tí a sì ń pè é ni Ọ̀rọ̀+ Ọlọ́run. 14  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń bẹ ní ọ̀run ń tẹ̀ lé e lórí àwọn ẹṣin funfun, wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, funfun, tí ó mọ́. 15  Idà+ gígùn mímú sì yọ jáde láti ẹnu rẹ̀, kí ó lè fi í ṣá àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì fi ọ̀pá irin+ ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn. Bákan náà, ó ń tẹ ìfúntí wáìnì+ ìbínú ìrunú Ọlọ́run+ Olódùmarè. 16  Àti pé lórí ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀, àní lórí itan rẹ̀, ó ní orúkọ kan tí a kọ, Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa.+ 17  Mo tún rí áńgẹ́lì kan tí ó dúró nínú oòrùn, ó sì ké jáde pẹ̀lú ohùn rara, ó sì wí fún gbogbo ẹyẹ+ tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run pé: “Ẹ wá níhìn-ín, ẹ kóra jọpọ̀ síbi oúnjẹ alẹ́ ńlá ti Ọlọ́run, 18  kí ẹ lè jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara+ àwọn ọba àti àwọn ibi kìkìdá ẹran ara àwọn ọ̀gágun àti àwọn ibi kìkìdá ẹran ara àwọn ọkùnrin alágbára+ àti àwọn ibi kìkìdá ẹran ara àwọn ẹṣin+ àti ti àwọn tí ó jókòó sórí wọn, àti àwọn ibi kìkìdá ẹran ara gbogbo ènìyàn, ti òmìnira àti ti ẹrú àti ti àwọn ẹni kékeré àti ńlá.” 19  Mo sì rí ẹranko ẹhànnà+ náà àti àwọn ọba+ ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn tí wọ́n kóra jọpọ̀ láti bá ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin+ àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ja ogun.+ 20  A sì mú ẹranko ẹhànnà náà,+ àti pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wòlíì èké+ tí ó ṣe àwọn iṣẹ́ àmì+ níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ṣi àwọn tí ó gba àmì+ ẹranko ẹhànnà náà lọ́nà àti àwọn tí ó ṣe ìjọsìn fún ère rẹ̀.+ Nígbà tí wọ́n ṣì wà láàyè, àwọn méjèèjì ni a fi sọ̀kò sínú adágún iná tí ń fi imí ọjọ́ jó.+ 21  Ṣùgbọ́n àwọn ìyókù ni a fi idà gígùn ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin+ pa tán, idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde.+ Gbogbo àwọn ẹyẹ+ sì jẹ+ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara wọn+ ní àjẹyó.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé