Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣípayá 18:1-24

18  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, mo rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, pẹ̀lú ọlá àṣẹ ńlá;+ a sì mú ilẹ̀ ayé mọ́lẹ̀ kedere láti inú ògo rẹ̀.+  Ó sì ké jáde pẹ̀lú ohùn líle,+ pé: “Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá ti ṣubú,+ ó sì ti di ibi gbígbé àwọn ẹ̀mí èṣù àti ibi ìlúgọpamọ́ sí fún gbogbo èémí àmíjáde+ àìmọ́ àti ibi ìlúgọpamọ́ sí fún gbogbo ẹyẹ àìmọ́ àti èyí tí a kórìíra!+  Nítorí pé tìtorí wáìnì ìbínú àgbèrè rẹ̀, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ti di ẹran-ìjẹ,+ àwọn ọba ilẹ̀ ayé sì bá a ṣe àgbèrè,+ àwọn olówò arìnrìn-àjò+ ilẹ̀ ayé sì di ọlọ́rọ̀ nítorí agbára fàájì aláìnítìjú rẹ̀.”+  Mo sì gbọ́ tí ohùn mìíràn láti ọ̀run wá wí pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi,+ bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,+ bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.  Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti wọ́ jọpọ̀ títí dé ọ̀run,+ Ọlọ́run sì ti mú àwọn ìṣe àìṣèdájọ́ òdodo rẹ̀ wá sí ìrántí.+  Ẹ ṣe sí i, àní gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀ ti ṣe síni,+ ẹ sì ṣe sí i ní ìlọ́po méjì, bẹ́ẹ̀ ni, ìlọ́po méjì iye ohun tí ó ṣe;+ nínú ife+ tí ó fi àdàlù kan sí, ẹ fi ìlọ́po méjì+ àdàlù náà sí i fún un.+  Dé àyè tí ó ṣe ara rẹ̀ lógo, tí ó sì gbé nínú fàájì aláìnítìjú, dé àyè yẹn ni kí ẹ fún un ní ìjoró àti ọ̀fọ̀.+ Nítorí pé nínú ọkàn-àyà rẹ̀, ó ń wí ṣáá pé, ‘Mo jókòó bí ọbabìnrin,+ èmi kì í sì í ṣe opó,+ èmi kì yóò sì rí ọ̀fọ̀ láé.’+  Ìdí nìyẹn tí àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀,+ ikú àti ọ̀fọ̀ àti ìyàn, yóò fi dé ní ọjọ́ kan ṣoṣo, a ó sì fi iná sun ún pátápátá,+ nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣèdájọ́ rẹ̀, jẹ́ alágbára.+  “Àwọn ọba+ ilẹ̀ ayé tí wọ́n bá a ṣe àgbèrè, tí wọ́n sì gbé nínú fàájì aláìnítìjú yóò sunkún, wọn yóò sì lu ara wọn nínú ẹ̀dùn-ọkàn lórí rẹ̀,+ nígbà tí wọ́n bá wo èéfín+ ìjóná rẹ̀, 10  bí wọ́n ti dúró ní òkèèrè nítorí ìbẹ̀rù wọn fún ìjoró rẹ̀, tí wọ́n sì wí pé,+ ‘Ó mà ṣe o, ó mà ṣe o, ìwọ ìlú ńlá títóbi,+ Bábílónì ìwọ ìlú ńlá alágbára, nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’+ 11  “Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn olówò arìnrìn-àjò+ ilẹ̀ ayé ń sunkún, wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀,+ nítorí pé kò sí ẹnì kankan láti ra ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹrù ọjà wọn mọ́, 12  ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹrù ọjà+ wúrà àti fàdákà àti òkúta ṣíṣeyebíye àti àwọn péálì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà àti aláwọ̀ àlùkò àti aṣọ ṣẹ́dà àti rírẹ̀dòdò; àti ohun gbogbo tí ó wá láti inú igi olóòórùn dídùn àti gbogbo onírúurú ohun tí a fi eyín erin ṣe àti gbogbo onírúurú ohun tí a fi igi tí ó ṣeyebíye jù lọ ṣe àti ti bàbà àti ti irin àti ti òkúta mábìlì;+ 13  pẹ̀lúpẹ̀lù, igi sínámónì àti èròjà atasánsán ti Íńdíà àti tùràrí àti òróró onílọ́fínńdà àti oje igi tùràrí àti wáìnì àti òróró ólífì àti ìyẹ̀fun kíkúnná àti àlìkámà àti àwọn màlúù àti àgùntàn, àti àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ àwọ́rìn àti ẹrú àti ọkàn ẹ̀dá ènìyàn.+ 14  Bẹ́ẹ̀ ni, èso àtàtà tí ọkàn rẹ fẹ́+ ti lọ kúrò lọ́wọ́ rẹ, àti gbogbo ohun ẹlẹ́wà oge àti àwọn ohun mèremère ti ṣègbé kúrò lọ́wọ́ rẹ, àwọn ènìyàn kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé.+ 15  “Àwọn olówò arìnrìn-àjò+ nǹkan wọ̀nyí, tí wọ́n di ọlọ́rọ̀ láti ara rẹ̀, yóò dúró ní òkèèrè nítorí ìbẹ̀rù wọn fún ìjoró rẹ̀, wọn yóò sì sunkún, wọn yóò sì ṣọ̀fọ̀,+ 16  ní sísọ pé, ‘Ó mà ṣe o, ó mà ṣe o—ìlú ńlá títóbi náà,+ tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà àti aláwọ̀ àlùkò àti rírẹ̀dòdò, tí a sì fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà àti òkúta ṣíṣeyebíye àti péálì ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ jìngbìnnì,+ 17  nítorí pé ní wákàtí kan irúfẹ́ ọrọ̀ ńláǹlà bẹ́ẹ̀ ni a ti pa run di ahoro!’+ “Àti olúkúlùkù ọ̀gákọ̀ àti olúkúlùkù ènìyàn tí ń rìnrìn àjò lójú omi lọ sí ibikíbi,+ àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ àti gbogbo àwọn tí ń rí oúnjẹ òòjọ́ wọn nípasẹ̀ òkun, dúró ní òkèèrè,+ 18  wọ́n sì ké jáde bí wọ́n ti wo èéfín láti inú ìjóná rẹ̀, wọ́n sì wí pé, ‘Ìlú ńlá wo ni ó dà bí ìlú ńlá títóbi náà?’+ 19  Wọ́n sì da ekuru sí orí ara wọn,+ wọ́n sì ké jáde, wọ́n ń sunkún, wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀,+ wọ́n sì wí pé, ‘Ó mà ṣe o, ó mà ṣe o—ìlú ńlá títóbi náà, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó ní ọkọ̀ ojú omi lójú òkun+ ti di ọlọ́rọ̀+ nítorí ìgbówólórí rẹ̀, nítorí pé ní wákàtí kan, a ti pa á run di ahoro!’+ 20  “Máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run,+ pẹ̀lúpẹ̀lù ẹ̀yin ẹni mímọ́+ àti ẹ̀yin àpọ́sítélì+ àti ẹ̀yin wòlíì, nítorí pé Ọlọ́run ti fi ìyà jẹ ẹ́ fún yín lọ́nà tí ó bá ìdájọ́ mu!”+ 21  Áńgẹ́lì alágbára kan sì gbé òkúta kan tí ó dà bí ọlọ+ ńlá sókè, ó sì fi í sọ̀kò sínú òkun,+ ó wí pé: “Lọ́nà kan náà, pẹ̀lú ìgbésọnù yíyára ni a ó fi Bábílónì ìlú ńlá títóbi náà sọ̀kò sísàlẹ̀, a kì yóò sì tún rí i mọ́ láé.+ 22  Àti ìró àwọn akọrin tí ń lo háàpù sí orin wọn àti ti àwọn olórin àti ti àwọn onífèrè àti ti àwọn afunkàkàkí ni a kì yóò tún gbọ́ nínú rẹ mọ́ láé,+ àti oníṣẹ́ ọnà iṣẹ́ ọwọ́ èyíkéyìí ni a kì yóò tún rí nínú rẹ mọ́ láé, àti ìró ọlọ kankan ni a kì yóò tún gbọ́ nínú rẹ mọ́ láé, 23  àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà kankan kì yóò tún tàn nínú rẹ mọ́ láé, àti ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó ni a kì yóò tún gbọ́ nínú rẹ mọ́ láé;+ nítorí pé àwọn ọkùnrin onípò gíga+ jù lọ ilẹ̀ ayé ni àwọn olówò arìnrìn-àjò rẹ,+ nítorí pé a ti ṣi gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà nípasẹ̀ iṣẹ́ ìbẹ́mìílò rẹ.+ 24  Bẹ́ẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀+ àwọn wòlíì+ àti ti àwọn ẹni mímọ́+ àti ti gbogbo àwọn tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé