Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣípayá 17:1-18

17  Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì méje tí wọ́n ní àwokòtò méje+ lọ́wọ́ sì wá, ó sì bá mi sọ̀rọ̀, pé: “Wá, èmi yóò fi ìdájọ́ lórí aṣẹ́wó ńlá+ tí ó jókòó lórí omi+ púpọ̀ hàn ọ́,  ẹni tí àwọn ọba ilẹ̀ ayé bá ṣe àgbèrè,+ nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn tí ń gbé ilẹ̀ ayé ni a ti mú kí wọ́n mu wáìnì àgbèrè+ rẹ̀ ní àmupara.”  Ó sì gbé mi nínú agbára ẹ̀mí+ lọ sínú aginjù kan. Mo sì tajú kán rí obìnrin kan tí ó jókòó lórí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò+ tí ó kún fún àwọn orúkọ ọ̀rọ̀ òdì,+ tí ó sì ní orí méje+ àti ìwo mẹ́wàá.  A sì fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò+ àti rírẹ̀dòdò+ ṣe obìnrin náà ní ọ̀ṣọ́, a sì fi wúrà àti òkúta ṣíṣeyebíye àti àwọn péálì+ ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, ó sì ní ife wúrà+ kan lọ́wọ́ rẹ̀ tí ó kún fún àwọn ohun ìríra+ àti àwọn ohun àìmọ́ àgbèrè+ rẹ̀.  Àti sí iwájú orí rẹ̀ a kọ orúkọ kan, ohun ìjìnlẹ̀+ kan: “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó+ àti ti àwọn ohun ìríra ilẹ̀ ayé.”+  Mo sì rí i pé obìnrin náà ti mu ẹ̀jẹ̀+ àwọn ẹni mímọ́ àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹlẹ́rìí Jésù+ ní àmupara. Tóò, ní títajúkán rí i, kàyéfì ńlá ṣe mí.+  Nítorí náà, áńgẹ́lì náà wí fún mi pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi ṣe kàyéfì? Ó dájú pé èmi yóò sọ ohun ìjìnlẹ̀ obìnrin+ náà fún ọ àti ti ẹranko ẹhànnà tí ń gbé e, tí ó sì ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá:+  Ẹranko ẹhànnà tí ìwọ rí ti wà tẹ́lẹ̀,+ ṣùgbọ́n kò sí, síbẹ̀ ó máa tó gòkè wá láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,+ yóò sì kọjá lọ sínú ìparun. Nígbà tí wọ́n bá sì rí bí ẹranko ẹhànnà náà ti wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò sí, síbẹ̀ tí yóò tún wà, àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yóò ṣe kàyéfì lọ́nà ìkansáárá, ṣùgbọ́n a kò kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé ìyè+ láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.+  “Níhìn-ín ni ibi tí làákàyè tí ó ní ọgbọ́n ti wọlé:+ Orí méje+ náà túmọ̀ sí òkè ńlá méje,+ níbi tí obìnrin náà jókòó lé. 10  Ọba méje ni ó sì ń bẹ: márùn-ún ti ṣubú,+ ọ̀kan wà,+ ọ̀kan tí ó kù kò tíì dé,+ ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dé, yóò dúró fún ìgbà kúkúrú.+ 11  Ẹranko ẹhànnà tí ó sì ti wà tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò sí,+ òun fúnra rẹ̀ pẹ̀lú ni ọba kẹjọ, ṣùgbọ́n ó jáde wá láti inú àwọn méje náà, ó sì kọjá lọ sínú ìparun. 12  “Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí túmọ̀ sí ọba mẹ́wàá,+ tí kò tíì gba ìjọba, ṣùgbọ́n wọ́n gba ọlá àṣẹ bí ọba fún wákàtí kan pẹ̀lú ẹranko ẹhànnà náà. 13  Àwọn wọ̀nyí ní ìrònú kan ṣoṣo, nítorí náà, wọ́n fún ẹranko ẹhànnà+ náà ní agbára àti ọlá àṣẹ wọn. 14  Àwọn wọ̀nyí yóò bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà jagun, ṣùgbọ́n, nítorí pé òun ni Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba,+ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò ṣẹ́gun wọn.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́ pẹ̀lú rẹ̀ yóò ṣe bẹ́ẹ̀.”+ 15  Ó sì wí fún mi pé: “Àwọn omi tí ìwọ rí, níbi tí aṣẹ́wó náà jókòó, túmọ̀ sí àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n.+ 16  Ìwo mẹ́wàá+ tí ìwọ sì rí, àti ẹranko ẹhànnà náà,+ àwọn wọ̀nyí yóò kórìíra aṣẹ́wó náà,+ wọn yóò sì sọ ọ́ di ìparundahoro àti ìhòòhò, wọn yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán, wọn yóò sì fi iná sun ún pátápátá.+ 17  Nítorí Ọlọ́run fi í sínú ọkàn-àyà wọn láti mú ìrònú òun ṣẹ,+ àní láti mú ìrònú kan ṣoṣo tiwọn ṣẹ nípa fífún ẹranko ẹhànnà náà+ ní ìjọba wọn, títí di ìgbà tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi di èyí tí a ṣe ní àṣeparí.+ 18  Obìnrin+ tí ìwọ sì rí túmọ̀ sí ìlú ńlá títóbi tí ó ní ìjọba kan lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé