Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣípayá 16:1-21

16  Mo sì gbọ́ tí ohùn rara+ kan láti inú ibùjọsìn náà wí fún àwọn áńgẹ́lì méje náà pé: “Ẹ lọ da àwokòtò méje ìbínú Ọlọ́run+ jáde sí ilẹ̀ ayé.”  Èkínní+ sì lọ, ó sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sínú ilẹ̀ ayé.+ Egbò+ adunniwọra àti afòòró ẹ̀mí sì wá wà lára àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àmì ẹranko ẹhànnà náà,+ tí wọ́n sì ń jọ́sìn ère rẹ̀.+  Èkejì+ sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sínú òkun.+ Ó sì di ẹ̀jẹ̀+ bí ti òkú ènìyàn, gbogbo alààyè ọkàn sì kú, bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ohun tí ó wà nínú òkun.+  Ẹkẹta+ sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sínú àwọn odò+ àti àwọn ìsun omi. Wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀.+  Mo sì gbọ́ tí áńgẹ́lì ti orí àwọn omi wí pé: “Ìwọ, Ẹni tí ń bẹ, tí ó sì ti wà,+ Ẹni ìdúróṣinṣin,+ jẹ́ olódodo, nítorí pé ìwọ ti ṣe ìpinnu wọ̀nyí,+  nítorí pé wọ́n tú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti ti àwọn wòlíì+ jáde, ìwọ sì ti fún wọn ní ẹ̀jẹ̀+ mu. Ó tọ́ sí wọn.”+  Mo sì gbọ́ tí pẹpẹ náà wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè,+ òótọ́ àti òdodo ni àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ.”+  Ẹ̀kẹ́rin+ sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sórí oòrùn; a sì yọ̀ǹda fún oòrùn láti fi iná jó àwọn ènìyàn náà gbẹ.+  A sì fi ooru ńlá jó àwọn ènìyàn náà gbẹ, ṣùgbọ́n wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ+ Ọlọ́run, ẹni tí ó ní ọlá àṣẹ+ lórí ìyọnu àjàkálẹ̀ wọ̀nyí, wọn kò sì ronú pìwà dà láti lè fi ògo+ fún un. 10  Ìkarùn-ún sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sórí ìtẹ́ ẹranko ẹhànnà náà.+ Ìjọba rẹ̀ sì ṣókùnkùn,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gé ahọ́n wọn jẹ nítorí ìrora wọn, 11  ṣùgbọ́n wọ́n sọ̀rọ̀ òdì+ sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọn kò sì ronú pìwà dà àwọn iṣẹ́ wọn. 12  Ìkẹfà+ sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sórí odò ńlá Yúfírétì,+ àwọn omi rẹ̀ sì gbẹ ráúráú,+ kí a lè palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún àwọn ọba+ láti ibi yíyọ oòrùn. 13  Mo sì rí tí àwọn àgbéjáde onímìísí+ àìmọ́ mẹ́ta tí wọ́n rí bí àkèré+ jáde wá láti ẹnu dírágónì+ náà àti láti ẹnu ẹranko ẹhànnà+ náà àti láti ẹnu wòlíì èké náà.+ 14  Ní ti tòótọ́, wọ́n jẹ́ àwọn àgbéjáde tí àwọn ẹ̀mí èṣù mí sí,+ wọ́n sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì,+ wọ́n sì jáde lọ bá àwọn ọba+ gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá,+ láti kó wọn jọpọ̀ sí ogun+ ọjọ́ ńlá+ Ọlọ́run Olódùmarè.+ 15  “Wò ó! Mo ń bọ̀ bí olè.+ Aláyọ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò,+ tí ó sì pa ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ mọ́, kí ó má bàa rìn ní ìhòòhò, kí àwọn ènìyàn sì wo ipò ìtìjú rẹ̀.”+ 16  Wọ́n sì kó wọn jọpọ̀ sí ibi tí a ń pè ní Ha–Mágẹ́dọ́nì+ lédè Hébérù. 17  Ìkeje sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sínú afẹ́fẹ́.+ Látàrí èyí, ohùn rara+ jáde wá láti inú ibùjọsìn níbi ìtẹ́ náà, tí ó wí pé: “Ó ti ṣẹlẹ̀!” 18  Mànàmáná sì kọ, ohùn sì dún, ààrá sì sán, ìsẹ̀lẹ̀+ ńlá sì sẹ̀ irú èyí tí kò tíì sẹ̀ láti ìgbà tí ènìyàn ti wá wà lórí ilẹ̀ ayé,+ ìsẹ̀lẹ̀+ kan tí ó lọ jìnnà, tí ó pọ̀ jọjọ. 19  Ìlú ńlá+ títóbi náà sì pín sí apá mẹ́ta, àwọn ìlú ńlá àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú; a sì rántí Bábílónì Ńlá+ níwájú Ọlọ́run, láti fún un ní ife wáìnì ìbínú ìrunú rẹ̀.+ 20  Pẹ̀lúpẹ̀lù, gbogbo erékùṣù sá lọ, a kò sì rí àwọn òkè ńláńlá.+ 21  Yìnyín ńláǹlà,+ tí òkúta rẹ̀ kọ̀ọ̀kan fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìwọ̀n tálẹ́ńtì kan sì bọ́ láti ọ̀run sórí àwọn ènìyàn náà, àwọn ènìyàn náà sì sọ̀rọ̀ òdì+ sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu àjàkálẹ̀ yìnyín náà,+ nítorí ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀ pọ̀ lọ́nà kíkàmàmà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé