Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣípayá 15:1-8

15  Mo sì rí àmì+ mìíràn ní ọ̀run, títóbi àti àgbàyanu, áńgẹ́lì méje+ tí wọ́n ní ìyọnu àjàkálẹ̀ méje.+ Àwọn wọ̀nyí ni ó kẹ́yìn, nítorí pé nípasẹ̀ wọn ni a mú ìbínú+ Ọlọ́run wá sí ìparí.+  Mo sì rí ohun tí ó jọ òkun bí gíláàsì+ tí ó dà pọ̀ mọ́ iná, àti àwọn tí ó jagunmólú+ lọ́wọ́ ẹranko ẹhànnà náà àti lọ́wọ́ ère+ rẹ̀ àti lọ́wọ́ nọ́ńbà+ orúkọ rẹ̀ tí wọ́n dúró níbi òkun bí gíláàsì náà,+ wọ́n ní háàpù+ Ọlọ́run lọ́wọ́.  Wọ́n sì ń kọ orin Mósè+ ẹrú Ọlọ́run àti orin Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà, pé: “Títóbi àti àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ,+ Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè.+ Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ,+ Ọba ayérayé.+  Ta ni kì yóò bẹ̀rù rẹ+ ní ti gidi, Jèhófà,+ tí kì yóò sì yin orúkọ rẹ lógo,+ nítorí pé ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin?+ Nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì jọ́sìn níwájú rẹ,+ nítorí a ti fi àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ rẹ tí ó jẹ́ òdodo hàn kedere.”+  Àti lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo rí, a sì ṣí ibùjọsìn àgọ́+ ẹ̀rí+ sílẹ̀ ní ọ̀run,+  àwọn áńgẹ́lì méje+ tí wọ́n ní ìyọnu àjàkálẹ̀ méje+ náà sì yọ láti inú ibùjọsìn náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ ọ̀gbọ̀+ tí ó mọ́, tí ń tàn yòyò, a sì fi àmùrè wúrà di igẹ̀ wọn yí ká.  Ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà+ sì fún àwọn áńgẹ́lì méje náà ní àwokòtò méje oníwúrà tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run,+ ẹni tí ó wà láàyè títí láé àti láéláé.+  Ibùjọsìn náà sì wá kún fún èéfín nítorí ògo Ọlọ́run+ àti nítorí agbára rẹ̀, kò sì sí ẹnì kankan tí ó lè wọnú ibùjọsìn náà títí di ìgbà tí ìyọnu àjàkálẹ̀ méje+ ti àwọn áńgẹ́lì méje náà fi parí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé