Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣípayá 14:1-20

14  Mo sì rí, sì wò ó! Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà dúró lórí Òkè Ńlá Síónì,+ àti pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì+ tí wọ́n ní orúkọ rẹ̀ àti orúkọ Baba+ rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn.  Mo sì gbọ́ ìró kan láti ọ̀run wá bí ìró omi púpọ̀+ àti bí ìró ààrá adúnròkè lálá; ìró tí mo sì gbọ́ dà bí ti àwọn akọrin tí ń lo háàpù+ sí orin wọn bí wọ́n ti ń ta háàpù wọn.  Wọ́n sì ń kọrin+ bí ẹni pé orin tuntun+ níwájú ìtẹ́ àti níwájú ẹ̀dá alààyè mẹ́rin+ àti àwọn alàgbà náà;+ kò sì sí ẹnì kankan tí ó lè dọ̀gá nínú orin yẹn bí kò ṣe ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà,+ tí a ti rà+ láti ilẹ̀ ayé wá.  Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí kò fi obìnrin+ sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin; ní ti tòótọ́, wúńdíá+ ni wọ́n. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ.+ Àwọn wọ̀nyí ni a rà+ lára aráyé gẹ́gẹ́ bí àkọ́so+ fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,  a kò sì rí èké kankan lẹ́nu wọn;+ wọ́n wà láìní àbààwọ́n.+  Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run,+ ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun+ láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn,+  ó ń sọ ní ohùn rara pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run,+ kí ẹ sì fi ògo+ fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé,+ nítorí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá+ ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.”+  Àti òmíràn, áńgẹ́lì kejì, tẹ̀ lé e, ó ń wí pé: “Ó ti ṣubú! Bábílónì+ Ńlá ti ṣubú,+ ẹni tí ó mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mu nínú wáìnì+ ìbínú àgbèrè rẹ̀!”+  Áńgẹ́lì mìíràn, ẹkẹta, sì tẹ̀ lé wọn, ó ń sọ ní ohùn rara pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá jọ́sìn ẹranko ẹhànnà+ náà àti ère+ rẹ̀, tí ó sì gba àmì kan sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀,+ 10  òun yóò mu pẹ̀lú nínú wáìnì ìbínú Ọlọ́run tí a tú jáde láìní àbùlà sínú ife ìrunú rẹ̀,+ ṣe ni a ó sì fi iná àti imí ọjọ́+ mú un joró+ níwájú àwọn áńgẹ́lì mímọ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. 11  Èéfín ìjoró wọn yóò sì máa gòkè lọ títí láé àti láéláé,+ wọn kì yóò sì ní ìsinmi rárá tọ̀sán-tòru, àwọn tí ń jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà àti ère rẹ̀, àti ẹnì yòówù tí ó bá gba àmì+ orúkọ rẹ̀. 12  Níhìn-ín ni ibi tí ó ti túmọ̀ sí ìfaradà fún àwọn ẹni mímọ́,+ àwọn tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run+ àti ìgbàgbọ́+ Jésù mọ́.” 13  Mo sì gbọ́ tí ohùn kan láti ọ̀run wá wí pé: “Kọ̀wé pé: Aláyọ̀ ni àwọn òkú+ tí ó kú ní ìrẹ̀pọ́ pẹ̀lú Olúwa+ láti àkókò yìí lọ.+ Bẹ́ẹ̀ ni, ni ẹ̀mí wí, kí wọ́n sinmi kúrò nínú àwọn òpò wọn, nítorí àwọn ohun tí wọ́n ṣe ń bá wọn lọ ní tààràtà.” 14  Mo sì rí, sì wò ó! àwọsánmà funfun kan, àti lórí àwọsánmà náà ẹnì kan jókòó bí ọmọ ènìyàn,+ pẹ̀lú adé wúrà+ ní orí rẹ̀ àti dòjé mímú ní ọwọ́ rẹ̀. 15  Áńgẹ́lì mìíràn sì yọ láti inú ibùjọsìn tẹ́ńpìlì, ó ń ké pẹ̀lú ohùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí àwọsánmà pé: “Ti dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí o sì kárúgbìn,+ nítorí wákàtí láti kárúgbìn ti tó, nítorí ìkórè+ ilẹ̀ ayé tí gbó kárakára.”+ 16  Ẹni tí ó jókòó lórí àwọsánmà sì ti dòjé rẹ̀ bọ orí ilẹ̀ ayé, a sì kárúgbìn ilẹ̀ ayé. 17  Síbẹ̀, áńgẹ́lì mìíràn yọ láti inú ibùjọsìn tẹ́ńpìlì tí ó wà ní ọ̀run,+ òun, pẹ̀lú, ní dòjé mímú lọ́wọ́. 18  Síbẹ̀, áńgẹ́lì mìíràn yọ láti ibi pẹpẹ, ó sì ní ọlá àṣẹ lórí iná.+ Ó sì ké jáde pẹ̀lú ohùn rara sí ẹni tí ó ní dòjé mímú lọ́wọ́, ó wí pé: “Ti dòjé mímú rẹ bọ̀ ọ́, kí o sì kó àwọn òṣùṣù àjàrà ilẹ̀ ayé jọ,+ nítorí èso àjàrà rẹ̀ ti pọ́n.” 19  Áńgẹ́lì+ náà sì ti dòjé rẹ̀ bọ ilẹ̀ ayé, ó sì kó àjàrà+ ilẹ̀ ayé jọ, ó sì fi í sọ̀kò sínú ìfúntí wáìnì ńlá ti ìbínú Ọlọ́run.+ 20  A sì tẹ ìfúntí wáìnì náà lẹ́yìn òde ìlú ńlá náà,+ ẹ̀jẹ̀ sì tú jáde láti inú ìfúntí wáìnì náà ní gíga sókè dé ìjánu ẹṣin,+ ó lọ jìnnà tó ẹgbẹ̀jọ ìwọ̀n fọ́lọ́ǹgì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé