Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣípayá 13:1-18

13  Ó sì dúró jẹ́ẹ́ lórí iyanrìn+ òkun. Mo sì rí ẹranko ẹhànnà+ kan tí ń gòkè bọ̀ láti inú òkun,+ ó ní ìwo mẹ́wàá+ àti orí méje,+ adé dáyádémà mẹ́wàá sì wà lórí àwọn ìwo rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn orúkọ tí ó kún fún ọ̀rọ̀ òdì+ wà ní àwọn orí rẹ̀.  Wàyí o, ẹranko ẹhànnà tí mo rí dà bí àmọ̀tẹ́kùn,+ ṣùgbọ́n ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bí ti béárì,+ ẹnu rẹ̀ sì dà bí ẹnu kìnnìún.+ Dírágónì+ náà sì fún ẹranko náà ní agbára rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀ àti ọlá àṣẹ ńlá.+  Mo sì rí ọ̀kan lára àwọn orí rẹ̀ bí ẹni pé a ṣá a pa, ṣùgbọ́n ọgbẹ́ ikú+ rẹ̀ sàn, gbogbo ilẹ̀ ayé sì tẹ̀ lé ẹranko ẹhànnà náà pẹ̀lú ìkansáárá.  Wọ́n sì jọ́sìn dírágónì náà nítorí pé ó fún ẹranko ẹhànnà náà ní ọlá àṣẹ, wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà: “Ta ni ó dà bí ẹranko ẹhànnà náà, ta sì ni ó lè bá a jagun?”  A sì fún un+ ní ẹnu tí ń sọ àwọn ohun ńlá+ àti ọ̀rọ̀ òdì, a sì fún un ní ọlá àṣẹ láti gbéṣẹ́ṣe fún oṣù méjìlélógójì.+  Ó sì la ẹnu rẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ òdì+ sí Ọlọ́run, láti sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ rẹ̀ àti ibùgbé rẹ̀, àní àwọn tí ń gbé ní ọ̀run+ pàápàá.  A sì yọ̀ǹda+ fún un láti bá àwọn ẹni mímọ́ ja ogun àti láti ṣẹ́gun wọn,+ a sì fún un ní ọlá àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n àti orílẹ̀-èdè.  Gbogbo àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yóò sì jọ́sìn rẹ̀; a kò kọ orúkọ ẹnì kankan nínú wọn sínú àkájọ ìwé+ ìyè ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí a fikú pa,+ láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.+  Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí, kí ó gbọ́.+ 10  Bí a bá pinnu ẹnikẹ́ni fún oko òǹdè, òun a lọ sí oko òǹdè.+ Bí ẹnikẹ́ni yóò bá fi idà pani, a gbọ́dọ̀ fi idà pa á.+ Níhìn-ín ni ibi tí ó ti túmọ̀ sí ìfaradà+ àti ìgbàgbọ́+ àwọn ẹni mímọ́.+ 11  Mo sì rí ẹranko ẹhànnà mìíràn+ tí ń gòkè bọ̀ láti inú ilẹ̀ ayé,+ ó sì ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́ àgùntàn, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ bí dírágónì.+ 12  Ó sì ń lo gbogbo ọlá àṣẹ ẹranko ẹhànnà àkọ́kọ́+ lójú rẹ̀. Ó sì ń mú kí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ jọ́sìn ẹranko ẹhànnà àkọ́kọ́ náà, èyí tí ọgbẹ́ ikú rẹ̀ sàn.+ 13  Ó sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì ńláǹlà,+ tó bẹ́ẹ̀ tí yóò tilẹ̀ mú kí iná sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run sí ilẹ̀ ayé lójú aráyé. 14  Ó sì ń ṣi àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé lọ́nà, nítorí àwọn iṣẹ́ àmì tí a yọ̀ǹda fún un láti ṣe lójú ẹranko ẹhànnà náà, bí ó ti ń sọ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé láti yá ère+ ẹranko ẹhànnà tí ó ní ọgbẹ́ idà,+ síbẹ̀ tí ó sọjí. 15  A sì yọ̀ǹda fún un láti fi èémí fún ère ẹranko ẹhànnà náà, kí ère+ ẹranko ẹhànnà náà lè sọ̀rọ̀, kí ó sì mú kí a pa gbogbo àwọn tí kì yóò jọ́sìn ère ẹranko ẹhànnà náà lọ́nà èyíkéyìí. 16  Ó sì ṣe é ní ọ̀ranyàn fún gbogbo ènìyàn,+ ẹni kékeré àti ẹni ńlá, àti ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, àti òmìnira àti ẹrú, pé kí wọ́n fún àwọn wọ̀nyí ní àmì kan ní ọwọ́ ọ̀tún wọn tàbí ní iwájú orí wọn,+ 17  àti pé kí ẹnì kankan má lè rà tàbí tà àyàfi ẹni tí ó bá ní àmì náà, orúkọ+ ẹranko ẹhànnà náà tàbí nọ́ńbà orúkọ rẹ̀.+ 18  Níhìn-ín ni ibi tí ọgbọ́n ti wọlé: Kí ẹni tí ó ní làákàyè gbéṣirò lé nọ́ńbà ẹranko ẹhànnà náà, nítorí pé nọ́ńbà ènìyàn+ ni; nọ́ńbà rẹ̀ sì ni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà, ẹẹ́wàá mẹ́fà, àti ẹyọ mẹ́fà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé