Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣípayá 12:1-17

12  Àmì ńlá+ kan sì di rírí ní ọ̀run, obìnrin+ kan tí a fi oòrùn ṣe ní ọ̀ṣọ́, òṣùpá sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, adé oníràwọ̀ méjìlá sì ń bẹ ní orí rẹ̀,  ó sì lóyún. Ó sì ké jáde nínú ìrọbí+ rẹ̀ àti nínú ìroragógó rẹ̀ láti bímọ.  Àmì mìíràn sì di rírí ní ọ̀run, sì wò ó! dírágónì+ ńlá aláwọ̀ iná, tí ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá àti adé dáyádémà méje ní àwọn orí rẹ̀;  ìrù+ rẹ̀ sì wọ́ ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀+ ojú ọ̀run, ó sì fi wọ́n sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé.+ Dírágónì náà sì dúró pa síwájú obìnrin+ tí ó máa tó bímọ,+ pé, nígbà tí ó bá bímọ, kí ó lè pa ọmọ rẹ̀ jẹ.+  Ó sì bí ọmọkùnrin kan,+ akọ, ẹni tí yóò fi ọ̀pá irin+ ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn orílẹ̀-èdè. A sì gba ọmọ rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run àti síbi ìtẹ́ rẹ̀.+  Obìnrin náà sì sá lọ sí aginjù,+ níbi tí Ọlọ́run pèsè àyè sílẹ̀ sí fún un, pé kí wọ́n máa bọ́+ ọ níbẹ̀ fún ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà ọjọ́.+  Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì+ àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jagun  ṣùgbọ́n kò borí, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run.  Bẹ́ẹ̀ ni a fi dírágónì+ ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀+ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù+ àti Sátánì,+ ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà;+ a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé,+ a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. 10  Mo sì gbọ́ tí ohùn rara kan ní ọ̀run wí pé: “Nísinsìnyí ni ìgbàlà+ dé àti agbára+ àti ìjọba Ọlọ́run+ wa àti ọlá àṣẹ Kristi+ rẹ̀, nítorí pé olùfisùn àwọn arákùnrin wa ni a ti fi sọ̀kò sísàlẹ̀, ẹni tí ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tọ̀sán-tòru níwájú Ọlọ́run wa!+ 11  Wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀+ nítorí ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà àti nítorí ọ̀rọ̀ ìjẹ́rìí wọn,+ wọn kò sì nífẹ̀ẹ́ ọkàn wọn+ lójú ikú pàápàá. 12  Ní tìtorí èyí, ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn!+ Ègbé+ ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun,+ nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú+ ni òun ní.” 13  Wàyí o, nígbà tí dírágónì náà rí i pé a ti fi òun sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé,+ ó ṣe inúnibíni sí obìnrin+ tí ó bí ọmọ náà tí ó jẹ́ akọ. 14  Ṣùgbọ́n a fún obìnrin náà ní ìyẹ́ apá méjì ti idì ńlá,+ kí ó lè fò lọ sínú aginjù+ sí àyè rẹ̀; níbẹ̀ ni a ti bọ́+ ọ fún àkókò kan àti àwọn àkókò+ àti ààbọ̀ àkókò kúrò ní ojú ejò náà.+ 15  Ejò náà sì pọ omi+ jáde bí odò láti ẹnu rẹ̀ tẹ̀ lé obìnrin náà, láti mú kí odò+ náà gbé e lọ. 16  Ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé wá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún obìnrin náà,+ ilẹ̀ ayé sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé odò náà mì, èyí tí dírágónì náà pọ̀ jáde láti ẹnu rẹ̀. 17  Dírágónì náà sì kún fún ìrunú sí obìnrin náà,+ ó sì lọ láti bá àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ rẹ̀ ja ogun, àwọn ẹni tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí+ Jésù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé