Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣípayá 11:1-19

11  A sì fún mi ní esùsú kan tí ó dà bí ọ̀pá+ bí ó ti wí pé: “Dìde, kí o sì wọn ibùjọsìn tẹ́ńpìlì+ Ọlọ́run àti pẹpẹ àti àwọn tí ń jọ́sìn nínú rẹ̀.  Ṣùgbọ́n ní ti àgbàlá tí ó wà ní ẹ̀yìn òde+ ibùjọsìn tẹ́ńpìlì, fi í sílẹ̀ pátápátá, má sì wọ̀n ọ́n, nítorí a ti fi í fún àwọn orílẹ̀-èdè,+ wọn yóò sì tẹ ìlú ńlá+ mímọ́ náà mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ fún oṣù méjìlélógójì.+  Ṣe ni èmi yóò mú kí àwọn ẹlẹ́rìí mi méjì+ sọ tẹ́lẹ̀+ fún ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà ọjọ́ ní wíwọ aṣọ àpò ìdọhọ.”+  Àwọn wọ̀nyí ni a fi igi ólífì méjì+ àti ọ̀pá fìtílà méjì+ ṣàpẹẹrẹ, wọ́n sì dúró níwájú Olúwa ilẹ̀ ayé.+  Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọ́n lára, iná a jáde wá láti ẹnu wọn, a sì jẹ àwọn ọ̀tá+ wọn run; bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọ́n lára pẹ́nrẹ́n, lọ́nà yìí ni a ó pa á.  Àwọn wọ̀nyí ní ọlá àṣẹ láti sé ọ̀run+ pa kí òjò kankan má bàa rọ̀+ ní àwọn ọjọ́ ìsọtẹ́lẹ̀ wọn, wọ́n sì ní ọlá àṣẹ lórí àwọn omi láti sọ wọ́n di ẹ̀jẹ̀+ àti láti fi gbogbo onírúurú ìyọnu àjàkálẹ̀ kọlù ilẹ̀ ayé nígbàkúùgbà tí wọ́n bá fẹ́.  Nígbà tí wọ́n bá sì ti parí ìjẹ́rìí wọn, ẹranko ẹhànnà tí ó gòkè wá láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀+ yóò bá wọn jagun, yóò sì ṣẹ́gun wọn, yóò sì pa wọ́n.+  Òkú wọn yóò sì wà ní ọ̀nà fífẹ̀ ìlú ńlá títóbi náà, èyí tí a ń pè lọ́nà ìtúmọ̀ ti ẹ̀mí ní Sódómù+ àti Íjíbíbtì, níbi tí a ti kan Olúwa wọn mọ́gi+ pẹ̀lú.  Àwọn tí ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti orílẹ̀-èdè+ yóò sì wo òkú wọn fún ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀,+ wọn kò sì jẹ́ kí a tẹ́ òkú wọn sínú ibojì. 10  Àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé sì yọ̀+ lórí wọn, wọ́n sì gbádùn ara wọn, wọn yóò sì fi àwọn ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì,+ nítorí pé wòlíì méjì wọ̀nyí mú àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé joró. 11  Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà,+ ẹ̀mí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sì wọnú wọn,+ wọ́n sì dúró lórí ẹsẹ̀ wọn, ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí ń wò wọ́n. 12  Wọ́n sì gbọ́ tí ohùn rara+ kan láti ọ̀run wí fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀ lókè níhìn-ín.”+ Wọ́n sì gòkè lọ sínú ọ̀run nínú àwọsánmà, àwọn ọ̀tá wọ́n sì rí wọn. 13  Ní wákàtí yẹn, ìsẹ̀lẹ̀ ńlá sì sẹ̀, ìdá mẹ́wàá+ ìlú ńlá náà sì ṣubú; ìsẹ̀lẹ̀ náà sì pa ẹgbẹ̀rún méje ènìyàn, jìnnìjìnnì sì bo àwọn yòókù, wọ́n sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run.+ 14  Ègbé+ kejì ti kọjá. Wò ó! Ègbé kẹta ń bọ̀ kíákíá. 15  Áńgẹ́lì keje sì fun kàkàkí rẹ̀.+ Ohùn rara sì dún ní ọ̀run, pé: “Ìjọba ayé di ìjọba Olúwa+ wa àti ti Kristi+ rẹ̀, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé àti láéláé.”+ 16  Àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún+ tí wọ́n jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn sì dojú bolẹ̀,+ wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run,+ 17  wí pé: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ,+ Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè,+ Ẹni tí ń bẹ,+ tí ó sì ti wà, nítorí o ti gba agbára ńlá+ rẹ, o sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.+ 18  Ṣùgbọ́n àwọn orílẹ̀-èdè kún fún ìrunú, ìrunú tìrẹ sì dé, àti àkókò tí a yàn kalẹ̀ láti ṣèdájọ́ àwọn òkú, àti láti fi èrè+ wọn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ wòlíì+ àti fún àwọn ẹni mímọ́ àti fún àwọn tí ń bẹ̀rù orúkọ rẹ, ẹni kékeré àti ẹni ńlá,+ àti láti run+ àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”+ 19  A sì ṣí ibùjọsìn tẹ́ńpìlì Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run,+ a sì rí àpótí+ májẹ̀mú rẹ̀ nínú ibùjọsìn+ tẹ́ńpìlì rẹ̀. Mànàmáná àti ohùn àti ààrá àti ìsẹ̀lẹ̀ àti yìnyín ńlá sì ṣẹlẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé