Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìṣípayá 10:1-11

10  Mo sì rí áńgẹ́lì+ alágbára mìíràn tí ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, tí a fi àwọsánmà+ ṣe ní ọ̀ṣọ́, òṣùmàrè sì wà ní orí rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dà bí oòrùn,+ ẹsẹ̀+ rẹ̀ sì dà bí ọwọ̀n iná,  ó sì ní àkájọ ìwé kékeré tí a ṣí sílẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún sórí òkun, ṣùgbọ́n ti òsì rẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé,+  ó sì ké jáde pẹ̀lú ohùn rara, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí kìnnìún+ bá ké ramúramù. Nígbà tí ó sì ké jáde, ààrá+ méje fọ ohùn tiwọn.  Wàyí o, nígbà tí ààrá méje náà sọ̀rọ̀, mo ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé; ṣùgbọ́n mo gbọ́ tí ohùn kan láti ọ̀run+ wí pé: “Fi èdìdì di àwọn ohun+ tí ààrá méje náà sọ, má sì kọ wọ́n sílẹ̀.”  Áńgẹ́lì tí mo rí tí ó dúró lórí òkun àti lórí ilẹ̀ ayé sì gbé ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún sókè ọ̀run,+  ó sì fi Ẹni tí ó wà láàyè+ títí láé àti láéláé,+ tí ó dá ọ̀run àti àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ̀ àti ilẹ̀ ayé+ àti àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ̀ àti òkun àti àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ̀,+ búra pé: “Kì yóò sí ìjáfara+ kankan mọ́;  ṣùgbọ́n ní àwọn ọjọ́ ìró ti áńgẹ́lì keje,+ nígbà tí ó máa tó fun kàkàkí rẹ̀,+ àṣírí ọlọ́wọ̀+ ti Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ìhìn rere tí ó polongo fún àwọn ẹrú tirẹ̀, àwọn wòlíì+ ni a mú wá sí ìparí ní tòótọ́.”  Ohùn+ tí mo sì gbọ́ láti ọ̀run tún ń bá mi sọ̀rọ̀, ó sì wí pé: “Lọ, gba àkájọ ìwé ṣíṣísílẹ̀ tí ó wà ní ọwọ́ áńgẹ́lì tí ó dúró lórí òkun àti lórí ilẹ̀ ayé.”+  Mo sì lọ bá áńgẹ́lì náà, mo sì sọ fún un pé kí ó fún mi ní àkájọ ìwé kékeré náà. Ó sì wí fún mi pé: “Gbà á, kí o sì jẹ ẹ́ tán,+ yóò sì mú ikùn rẹ korò, ṣùgbọ́n ní ẹnu rẹ yóò dùn bí oyin.” 10  Mo sì gba àkájọ ìwé kékeré náà ní ọwọ́ áńgẹ́lì náà, mo sì jẹ ẹ́ tán,+ ó sì dùn ní ẹnu mi bí oyin;+ ṣùgbọ́n nígbà tí mo jẹ ẹ́ tán, ó mú ikùn mi korò. 11  Wọ́n sì wí fún mi pé: “Ìwọ gbọ́dọ̀ tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n àti ọba púpọ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé